Seyi Makinde: Ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ ní December ni màá sìnkú ìyá mí

Seyi Makinde ati iya rẹ

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinse

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti ṣapejuwe iya rẹ gẹgẹ bi obinrin to ni akinkanju, to ṣe gbẹkẹle, to ṣiṣẹ karakara nigba aye rẹ.

Seyi Makinde lo sọ eyi lasiko to gbalejo Deji ti ilu Akure, to ṣe abẹwo si lati ba kẹdun lori iku iya rẹ to papoda ni ẹni ọdun mọkanlelọgọrin.

Makinde ninu ọrọ rẹ sọ wi pe, iya oun to jẹ ọmọ ilu Akure fihan gbangba pe, awọn ara ilu Akure jẹ eniyan ọtọ to ṣe e fi ọkan tan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Ti o ba ri ọmọ ilu Akure, ohun ti wa ri ni awọn eniyan to jẹ akinkanju, ti ọrọ wọn si ṣee gbẹkẹle.

Seyi Makinde ati iya rẹ

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinse

Bakan naa ni gomina Makinde kede pe, o di ọsẹ kini, Oṣu Kejila, ọdun 2020 ki oun to ṣe oku iya oun to papoda.

Gomina wa dupẹ lọwọ Deji ti Akure fun abẹwo rẹ, to si fi da wọn loju pe, awọn ara ilu Akure yoo ko ipa ribiribi ninu eto isinku iya oun.

Bẹẹ si ni gomina ipinlẹ Oyo lo asiko naa, lati fi ki awọn eniyan ipinlẹ Ondo, fun atilẹyin ti wọn ṣe fun ẹgbẹ oṣelu PDP, lasiko idibo sipo gomina to waye ni Osu Kẹwaa, ọdun 2020.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ọ̀nà tí o lè gbà láti di ọjọ́ ogbó pẹ̀lú olólùfẹ́ rẹ

''Paapaa ilu Akure, wọn fihan pe awọn ṣetan lati jẹ ki ọmọ wọn di gomina ipinlẹ naa pẹlu bii wọn ṣe dibo wọn fun ẹgbẹ oṣelu PDP''

''Amọ, a o tẹsiwaju lati ma a rọ awọn ẹkun to ku nipinlẹ Ondo, lati fi ọwọ sọwọpọ fun gomina to wa lati ilu Akure, nipinlẹ Ondo.''

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa: Mọ̀ si nípa àwọn ọ̀nà tí Yorùbá ń gbà ran ara wọn lọ́wọ́

Ninu ọrọ tirẹ, Deji ti ilu Akure ni iya Gomina naa, Abigail Omojolagbe Makinde to wa lati idile Omoregie, jẹ idile ti awọn eniyan mọ fun iwa ọtọ ati awọn eniyan to ṣe e gbẹkẹle.

Deji naa si gbadura ki Olorun fi ọrun kẹ mama to doloogbe.

Ìyá gómìnà Seyi Makinde dágbére fáyé lẹ́ni ọdún 81

Makinde ati Iya rẹ

Oríṣun àwòrán, @Makinde

Iya to ṣe ọlọkọ to wa gomina ipinlẹ Oyo wa saye, Arabinrin Abigail Omojolagbe Makinde ti faye silẹ.

Bo tilẹ jẹ pe gomina Makinde funrarẹ ko tii fi ọrọ sita, iroyin taa gbọ ni pe Mama Abigail dakẹ lowurọ ọjọbọ ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹwa ọdun 2020.

Makinde ati Iya rẹ

Oríṣun àwòrán, @Makinde

Ni ibẹrẹ ọdun yii ni wọn ṣe ayẹyẹ ọgọrin ọdun ti mama naa pe lorilẹ aye.

Iya Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, @Makinde

Lẹyin aisan ranpẹ toripe ọjọ ogbo ni mama wa lọ sinmi.

Ṣaaju asiko yii gomina Makinde ti ṣapejuwe iya rẹ ri gẹgẹ bii ẹni ti wi bẹ ki wọn ba a bẹẹ to si ni oun fi iru eyi jọ iya to bi oun lọmọ.

Ọpọlọpọ ọrọ ni gomina Seyi Makinde sọ nibi ayẹyẹ ọjọ ibi ti iya rẹ ṣe gbẹyin eyi to fihan pe o mọ riri iya yii ko si ko iyan rẹ kere.

A o mu ẹkunrẹrẹ iroyin wa fun yin bo ba ṣe n lọ.

Àkọlé fídíò, Eegunjobi Omotanbaje Ajobiewe- Èébú ní wọ́n kọ́kọ́ ń bù mí nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣà pípé ní