ENDSARS, End SWAT: Ààrẹ Buhari ló pa àṣẹ tó mú kí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ó dá ikọ̀ SARS sílẹ̀, Fulani Kwajafa tó dá SARS sílẹ̀ ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, Aisha yesufu
Kaakiri agbaye, ọrọ ikọ kogberegbe ọlọpaa ti ọpọ mọ si SARS lo gbaye kan bayii.
Eleyii ti ko ṣẹyin iwọde to n waye kaakiri orilẹ-ede Naijiria bayii nibi ti awọn eeyan ti n gbe ohun soke lati tako idasilẹ ikọ naa.
Njẹ ẹ mọ pe SARS ni baba?
Ikọ SARS bẹrẹ ni ọdun 1984 lati gbogun ti gulegule awọn adigunjale lorilẹ-ede Naijiria.
Ikọ BBC lọ ṣawari Baba SARS, Alagba Fulani Kwajafa to da ikọ naa silẹ.
- Kanye West, Ozil, Boyega, àti àwọn gbajúmọ̀ ilẹ̀ ilẹ̀ okèèrè tó ṣàtìlẹyìn fún ìpolongo #ENDSARS
- Ẹ̀yin olùwọ́de, ẹ lọ kọwọ́ ọmọ yín bọṣọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́...- iléeṣẹ́ ológun kìlọ̀
- Àjọ FCTA fòfin de ìwọ́de nílùú Abuja
- Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò kó tó jọba
- Ṣé Èdùà dá ààtàn isó ni? Ọkùnrin kan tó yasó nínú ọkọ̀ Uber rí ẹ̀wọn he
Ninu ọrọ rẹ o ni, ọga agba ọlọpaa patapata lorilẹ-ede Naijiria nigba naa, Etim Inyang lo pe ipade kan pẹlu awọn eekan ileeṣẹ ọlọpaa lati dẹkun ọwọja idigunjale lasiko naa.
Nibi ipade naa ni wọn ti fi ẹnu ko pe ki wọn da ikọ pataki kan silẹ ti yoo maa gbena woju awọn adigunjale naa nigba naa.
Fulani Kkwajafa to wa ni ipo kọmiṣọnna ọlọpaa nigba naa ni wọn yan lati ko ikọ naa jọ.
Gẹgẹ bi ọrọ to sọ, ọga ọlọpaa Kwajafa ṣalaye pe iye ọlọpaa to bẹrẹ ikọ naa ko ju marundinlọgọrin nigba naa, oun loun si fi ọwọ ara oun yan wọn.
Baba Sars ni agbegbe Adeniji Adele ni olu ileeṣẹ wọn wa nigba naa.
O ni ojuṣe ọlọpaa SARS nigba naa ko ju mimu awọn adigunjale lọ, bẹẹni iwe ojuṣe ati ihuwasi wa fun gbogbo awọn ọlọpaa ikọ naa nigba naa.
Lara awọn ohun to wa ninu iwe naa ni iṣẹ iwadii, ati mimu awọn afunrasi.
Bakan naa lo ni laarin ọdun 1984 si ọdun 1989 ko si igba kankan ti ọlọpaa ikọ naa kankan lori laya lati yinbọn pa araalu.
- Wo àwọn ojúṣe àti èèwọ̀ fún ikọ̀ ọlọ́pàá SWAT tó gba iṣẹ́ lọ́wọ́ SARS
- Ọlọ́pàá mú afurasí 31 tó ń dúnkokò máwọn ọmọdé lórí ayélujára
- Pásítọ̀ Enoch Adeboye darapọ̀ mọ̀ #ENDSARS, ó fún ìjọba Nàìjíríà ní ìmọ̀ràn ọ̀nà àbáyọ
- Mọ̀ nípa iPhone 12, fóònù ológo 5G tí kìí lo "Charger” tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde
- Àṣé àṣírí wà nínú Hijabu tí Aisha Yesufu ń wọ̀ lọ ìwọ́de
O ni: "Ikọ SARS ti a da silẹ lọdun 1984 yatọ si ikọ SARS to wa nilẹ bayii nitori pe ohun kan ṣoṣo ti o lee mu ki ọlọpaa ikọ SARS o yọ ibọn jade nigba naa ni bi adigunjale ba yọ ibọn lati yin si wọn."
Ọga ọlọpaa Kwajafa ṣalaye pe aṣẹ ti ijọba ologun igba naa labẹ olori ologun, Ọgagun Muhammadu Buhari gbe sita fun ọga ọlọpaa nigba naa, Etim Inyang pe ko lọ wa nnkan ṣe si iṣẹlẹ idigunjale to n fojojumọ pọ si lorilẹede Naijiria, bi bẹẹkọ iṣẹ oun atawọn lọgalọga nileeṣẹ ọlọpaa naa yoo lọ sii.
Nibayii, iwọde ṣi n lọ o lati dẹkun gulegule iwa komẹtọ tawọn ọẹọpaa ikọ naa n hu.
















