iPhone 12 :Mọ̀ nípa iPhone 12, fóònù ológo 5G tí kìí lo "Charger” tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde

Oríṣun àwòrán, APple
lleeṣẹ Apple Corps ti fọwọ sii pe iPhone 12 tuntun to jade ni iru rẹ akọkọ ti yoo lo itakun ayelujara 5G.
Ileeṣẹ naa tun ni wọn yoo ṣe ọmọde rẹ jade pẹlu gilaasi oju ti ko ni ju 5.4 inches lọ.
Awọn onimọ sayẹnsi ti fihan pe Itakun ayelujara tuntun ti ileeṣẹ yii ṣe yoo mu ọja wọn gbooro sii tayọ bo ṣe wa lọdun 2014 lẹyin ti ileeṣẹ na ṣe iPhone 6 jade.
"Itakun 5G yoo faaye gba keeyan maa gba fidio ati fifi fidio sita to fi mọ wiwo fidio to mọ gaara to si ja fafa", Tim Cook, oludari ileeṣẹ naa lo sọ bẹẹ.
- Pásítọ̀ Enoch Adeboye darapọ̀ mọ̀ #ENDSARS, ó fún ìjọba Nàìjíríà ní ìmọ̀ràn ọ̀nà àbáyọ
- Mo ṣèlérí láti ṣe ju ohun tí mo ti ṣe lọ fún ẹbí àwọn tó kú torí EndSARS - Seyi Makinde
- Bàbá ọlọ́mọ méjì fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́rin lò pọ̀; Adájọ́ rán an ní ẹ̀wọ̀n gbére
- Ọlọ́pàá mú afurasí 31 tó ń dúnkokò máwọn ọmọdé lórí ayélujára

Oríṣun àwòrán, APple
Awọn nkan to fi da i phone naa yatọ ree:
Ko nilo ohun amugbagbara "Charger".
iPhone 12 tuntun yii yoo ni oju gilaasi fifẹ ti yoo ju ti tẹlẹ lọ.
Ṣugbọn fun igba akọkọ, wọn ko ni ko ohun amugbagbara "charger" ati ẹrọ igbohun "earpiece" sinu pali rẹ. Ileeṣẹ Apple ni anfani itakun tuntun yii niyẹn.
Oluwoye kan, Dan Ives ni o fẹrẹ to ida ogoji ninu awọn to fẹẹ to ọgọrun miliọnu to n lo iPhone ni ko tii ṣe foonu wọn ko gbera siwaju fun o kere tan ọdun mẹta abọ eyi to si lee fun wọn ni anfani pupọ bi wọn ba ṣe e.
Itakun Ayelujara 5G:
Oṣu keji Ọdun 2019 ni ileeṣẹ Samsung ṣe ifilọọlẹ 5G fu foonu Galaxy S10 lẹyin naa ni Huawei, OnePlus ati Google ṣe tiwọn naa pẹlu foonu oni 5G.
Ṣugbọn awọn akọṣẹmọṣẹ ni ko ṣeeṣe ki Apple kọkọ ṣe itakun agbaye sita afi ki wọn duro ki itakun naa kọkọ farahan ki wọn to fi lọọlẹ.
Ileeṣẹ yii ni pẹlu ayẹwo awọn, eeyan le gba fidio oni 20 gig laarin iṣẹju aaya marundinlaadọta.
Ṣugbọn ikilọ ti Apple fi sita ni pe iyatọ le wa nitori adugbo ti eeyan ba wa ati bi itakun ayelujara ibẹ ba ṣe lagbara to.

Oríṣun àwòrán, APple
Aworan to gidi gan an ni:
Uk ni orilẹede keji nilẹ Yuroopu ti yoo bẹrẹ si ni lo itakun ayelujara 5G.
Ni Amẹrika ti ọja Apple ti n ta ju, itakun 5G ọhun fẹ lọra nibẹ.

Oríṣun àwòrán, @apple
Lawọn orilẹede kan, 5G ko tii di kari ile kari oko.
Ṣugbọn ni China, to jẹ ibudo ọja nla keji fun awọn ọja Apple, ijọba ti ni awọn yoo mu imọ ẹrọ wọn gbooro sii kaakiri orilẹede wọn si kede laipẹ pe itakun ayelujara ti wa daadaa ni Beijing ati Shenzhen.
- Wo àwọn ojúṣe àti èèwọ̀ fún ikọ̀ ọlọ́pàá SWAT tó gba iṣẹ́ lọ́wọ́ SARS
- Ọlọ́pàá mẹ́sàn án tó farapa nínú ìjàmbá ọkọ̀ Akure t'éèyàn méjì ti kú sì wà nílé ìwòsàn
- Ìjàmbá ọkọ̀ akérò àti tírélà pa èèyàn mẹ́rin lọ́nà mọ́rosẹ̀ Ore sí Benin
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó wáyé nibi ìwọ́de ENDSARS Nàìjíríà
- Ẹgbẹ́ Agbẹjọ́rò NBA ti kéde pé àwọn yóò ṣojú awọn Olùwọ́de #EndSARS lọ́fẹ̀ẹ́ nílé ẹjọ́
















