Welder Rape: Adájọ́ rán bàbá ọlọ́mọ méjì tó fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́rin lò pọ̀ lẹ́wọ̀n gbére

Aworan ọmọde ti wọn ba lopọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile ẹjọ giga kan ni ilu Akure ni ipinlẹ̀ Ondo ni guusu Iwọ oorun Naijiria ti dajọ ẹwọn gbere farakunrin oniṣẹ jorin-jorin kan to fipa ba ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹrin lo pọ.

A gbọ pe arakunrin naa, Modupe Oni, ṣe aṣemaṣe yii nilu Ifon ni ijọba ibilẹ Ose.

O sọ fun adajọ pe oun ko jẹbi ẹsun naa.

Gẹgẹ bi ileeẹjọ ti ṣe fidi ọrọ naa mulẹ, wọn ni Oni fipa ba ọmọde naa lopọ nigba ti o wa ra ẹpa lọdọ iyawo rẹ.

Iyawo rẹ ko si nile lo ba tan ọmọ naa wọ inu iyara to si fipa ba a lajọṣepọ.

Àkọlé fídíò, EndSARS protest in Nigeria: Mr Macaroni, Falz, Wizkid, Tiwa Savage àtàwọn míì ṣe ìwọde

Nigba ti ọmọ naa yoo fi pada de ile, o tu kẹkẹ ọrọ fawọn obi rẹ ti wọn si sare gbe e lọ si ile iwosan.

Nibẹ ni ayẹwo ti fihan pe lootọ ni wọn fipa ba a lopọ.

Àkọlé fídíò, Say no to rape: Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá pariwo síta lórí wàhálà ìfipábánilòpọ̀

Lasiko igbẹjọ agbẹjọro ijọba pe ẹlẹri mẹrin wa ti afurasi naa si jẹri niwaju Adajọ fun ara rẹ.

Oni sọ pẹ ọrọ naa ko ribẹ ṣugbọn Adajọ Samuel Bola ni ọrọ to sọ niwaju ile ẹjọ yatọ si eyi to kọsilẹ lọdọ ọlọpaa.

Àkọlé fídíò, Abayọmi Aranmọlatẹ, Dr Laser: Vagino Plasty àti iṣẹ́ abẹ ẹwà Obìnrin ló jẹ mí lógún

Lẹyin naa lo dajọ ẹwọn gbere fun baba ọlọmọ meji naa.

Lẹyin eyi ni Adajọ Oni gboriyin fun ọmọdebinrin naa pe o dara to ni igboya lati sọrọ sita.

Àkọlé fídíò, Rape: Ayé obìnrin tí wọ́n fipábálòpọ̀ kò lè rí bákàn náà mọ́