Nigeria Accident: Ènìyàn 17 kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ mẹ́ta tó ṣẹlẹ̀ ní Osun, òpópónà Ibadan sí Eko àti Delta

Oríṣun àwòrán, Twitter
Eniyan mẹtadinlogun lo ku, ti ọgọọrọ eniyan si farapa ninu ijamba ọkọ to waye ni awọn opopona ni ipinlẹ Osun, Ogun, Delta ati ipinlẹ Eko.
Iroyin ni eniyan mẹsan an ni ẹmi wọn ba ijamba ọkọ laarin ọpọlọpọ ọkọ to waye ni ipinlẹ Osun.
Eniyan mẹrin ku ninu ijamba ọkọ to waye nipinlẹ Ogun, pẹlu eniyan meji si sọ ẹmi wọn nu ninu ijamba ọkọ to waye nipinlẹ Delta ati ilu Eko.
Agbegbe Igbelajawa, Erin Ijesa ni ọkọ nla meji ti kọlu ara wọn nipinlẹ Osun.
- EndSARS protest in Nigeria: Mr Macaroni, Falz, Wizkid, Tiwa Savage àtàwọn míì ṣe ìwọde
- Ìfẹ́hònúhàn 'End SARS' ń tẹ́síwájú láì jẹ́ pé Buhari ṣe.....
- Wo ìdí tí Tẹni, ọ̀dọ́mọdé olórin obìnrin kìí fi ń ṣí ìhòhò rẹ silẹ̀
- Mọ̀ sí i nípa díẹ̀ lára àwọn èèyàn tí ikú wọn 'láti ọwọ́ ọlọ́pàá' milẹ̀ tìtì ní Nàìjíríà
Awọn ọkọ meji to k lu ara wọn ni opopona Ilesha-Akure naa lo gbina ti ọkọ mẹsan an si jona raurau.
Ijamba ọkọ naa fa sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ titi de Ipetu/Eti Oni/ Iperindo/ Ilesha road, eleyii si mu ki ọpọlọpọ ọkọ ha si oju kan naa fun ọpọlọpọ wakati ti Ajọ FRSC, ọlọpaa ati Ajọ panapana fi ṣiṣẹ lati la ọna fun awọn eniyan lati ṣiṣẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Gomina ipinlẹ Osun, Adegboyega Oyetola ba awọn ẹbi ati ara awọn eniyan to sọ ẹmi awọn eniyan wọn daro.
Nipinlẹ Ogun, ijamba ọkọ to waye naa ṣẹlẹ ni ori afara Saapade, to lọ si opopona Ibadan si Eko.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ajo FRSC to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ wi pe aṣiwa ọkọ lo fa a iṣẹlẹ naa ni idaji ọjọ Aje naa, ti ẹmi eniyan mẹfa si lọ si iṣẹlẹ naa.
- Èèyàn 164 ló tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ní àrùn Coronavirus ní Nàìjíríà
- Mọ̀ sí i nípa díẹ̀ lára àwọn èèyàn tí ikú wọn 'láti ọwọ́ ọlọ́pàá' milẹ̀ tìtì ní Nàìjíríà
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kéde ṣíṣí gbogbo kíláàsì iléèwé padà
- Inú mi dùn sí iwọ́de EndSARS tàwọn ọdọ́ Nàìjíríà ń ṣè - Ooni Ogunwusi
- Àìbìkítà yíì gbọ́dọ̀ dópin, ìjọba gbọdọ̀ mú ẹ̀dùn ọkàn àwọn aráàlú lọ́kùnkúndùn- Agbẹjọ́rò Àgbà
- Àwọn aṣòfín ní ìpínlẹ̀ Edo ti yọ Abẹnugan Ilé, Francis Okiye bí jìgá
Ni ilu Eko, ijamba ọkọ to waye lori afara Third Mainland Bridge, ti wọn n lọ si Iyana Oworo naa mu ẹmi eniyan meji lọ.
Bakan naa ni ilu Delta, eniyan meji sọ ẹmi wọn nu ni opopona Ughelli-Warri ni aarọ Ọjọ Aiku, ti awọn mẹfa si farapa.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ilé alájà mẹ́ta wó pa èèyan méje, èèyàn 20 farapa ní Obalende, Eko
Eeyan méje ti jẹ Ọlọrun nipe nibi ile alaja mẹta to wo ni ipinlẹ Eko lọjọ Aiku, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020.
Kii ṣe ajoji mọ bi ile ṣe n wo lọtun losi ni ipinlẹ Eko ti o si maa n mu ẹmi awọn eeyan lọ tabi ki wọn farapa nigba ti wọn yoo fi doola wọn.Ile naa ti wọn n kọ lọwọ lo wa ni adugbo Odo, Obalende, nijba ibilẹ Eti-Osa ni ilu Eko.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
- Lagos Building Collapse: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko gbé ìgbìmọ̀ olùwádìí kalẹ̀
- Ẹni kan ti gbẹ́mìí mì; àwọn mẹ́rin ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn-LASEMA
- Ìdí tí ilé fi wó lu ènìyàn méjì ní Oshodi -LASEMA
- Àwọn ọ̀dọ́ yabo ààfin, Ṣọun Ògbómọ̀ṣọ́ àti mínísítà sá àsálà fẹ́mi wọn
- Ààrẹ Buhari kí Akeredolu kú orííré bí ó ṣe jáwé olúborí nínú ìdìbò sípò gómínà
- Gomina Kano tí ní kí olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ lọ rọ́kún nílé nítori o bu Ààrẹ Buhari lórí #EndSars
- EndSARS: Wo ohun táwọn gbajúgbajà tó n darí ìwọ́de ìfopinsí FSARS n sọ
Pato ohun to fa a to fi wo ko tii ye ẹnikẹni ṣugbọn ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni Eko, LASEMA atawọn ajọ adoola mii ni awọn ti ri ogun eeyan doola laaye wọn si ti gbe wọn lọ si ileewosan kiakia.
Bakan naa ni ajọ naa sọ pe ajọ to n risi ọrọ ile kikọ nipinlẹ Eko, LASBCA, ti titi ile naa pa tẹlẹ ṣaaju iṣẹlẹ buruku yii.

Oríṣun àwòrán, lasema
Amọ ẹni to ni ile naa pada gba ọna alumọkọrọyi bẹrẹ iṣẹ nibẹ ni owurọ ọjọ Aiku.
Ọga Agba ajọ LASEMA, Olufemi Oke-Osanyintolu sọ ninu atẹjade kan pe aigbọran si ofin lo pada yọri si bi ile naa ṣe wo, to si mu ẹmi awọn eeyan kan lọ.

Oríṣun àwòrán, lasema

Oríṣun àwòrán, lasema
Ṣugbọn, ọkunrin mẹfa, obinrin kan lo ba iṣẹlẹ naa rin ti wọn si ti gbe wọn lọ sile igbokusi.

Oríṣun àwòrán, LASEMA/TWITTER

Oríṣun àwòrán, lasema
Ẹwẹ, alukoro ajọ LASEMA, Nosa Okubor ni igbiyanju ṣi n lọ lọwọ lati doola awọn eeyan toripe wọn o mọ iye eeyan ti ile naa wo lu nigba ti a fi n ko iroyin yii jọ.

Oríṣun àwòrán, Google Maps
Ẹni méjì kú, ọ̀pọ̀ dèrò ilé ìwòsàn níbi ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ ní Okokomaiko nípínlẹ̀ Eko
Ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, iyẹn, Lagos State Emergency Management Agency, LASEMA ti fidi iṣẹlẹ ijamba ọkọ naa mulẹ nipinlẹ Eko pe ẹmi meji ba iṣẹlẹ naa rin.
Ogbeni Nosa Okunbor to jẹ agbẹnusọ ajọ LASEMA fi atẹjade naa sita lọjọ Aiku pe agbegbe Okokomaiko si Iyana Isashi ni ijamba ọkọ naa ti ṣẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, @Lasema
O ni ajọ LASEMA ti ko awọn to ṣeṣe ni Oke afa ninu ejigbo naa lọ sile iwosan.
O ni didide kia si amojuto iṣẹlẹ naa lo tun jẹ ki iku to wa nibẹ mọ niwọnba bẹẹ nitori bi wọn se de ibẹ ni wọn doola ẹmi awọn to ha sinu ọkọ naa ati awakọ ti wọn pe ni Olasupo Adedeji to n gbe ni Asenuga ni ibudokọ Ile iwe ni Ikotun.
- Ó sàn fún mi kí n má tíì lọ́kọ báyìí ju kí n lọ́kọ ṣùgbọ́n...- Nkechi Blessing
- Ọ̀rẹ́ wa ni Lawrence jẹ́, àmọ́ ó gbẹ̀yìn dẹ́nu ìfẹ́ kọ abúrò wa - Joshua àti Damilola Bamiloye
- Duro Ladipọ, ìlúmọ̀ọ́ká òṣèré tíátà àti ọmọ àlúfà tí kò gbàgbé àṣà ìbílẹ̀
- APC mókè nínú ìbò gómìnà níjọba ìbílẹ̀ mẹ́sàn-án l‘Ondo, PDP gba mẹ́ta
Ogbeni Nosa ni pe: " bi ajọ LRT se rii pe awakọ bọọsi akero kekere naa ti kọlu ọkọ akero miran to si wọ ọ lọ kọlu okọ ajagbe ti wọn wa soju kan nibẹ.
Lori ere ni ọkọ naa kọlu ọkọ ajagbe naa ti awọn eeyan si ha si abẹ rẹ.
Ati pe awọn meji miran tun farapa ni Okokomaiko loru ọjọ Ẹti.
Wọn ti pese itọju to yẹ fun awọn to farapa niwọnba ti wọn si ko awọn to ku lọ si Trauma Centre".
LASEMA salaye pe loju ẹsẹ ni awakọ kan ati ero kan dagbere faye ni Okokomaiko si Iyana Isashi lopopona Badagry.
Ọkọ ajagbe to ni nọmba AAA 95 XX lo bajẹ loju ọna pẹlu ẹru irin to ko ni eyi to fi jẹ ki sunkéré fakéré o pọ lọna.
Bakan naa ni ọkọ ajagbe akẹru miran to ni nọmba GDD 962 ZT to kọ awọn pali ohun mimu ni awakọ rẹ gbagbe sunlọ ti o si ja le ọkọ bọọsi akero ti nomba rẹ jẹ SMK 343 YA ati LSD 818 XX ti awọn naa wa ninu sunkẹrẹ fakéré ọkọ nibẹ.
LASEMA ni wọn ti palẹmọ oku awọn to doloogbe lọ si Lagos State Environmental Health Monitoring Unit Officials.
- Wo oríṣi inú rírun márùn-ún tí o kò gbọdọ̀ pa mọ́ra
- Kọ́ sí i nípa àwọn oúnjẹ aṣaralóore tó yẹ kí Aláboyún máa jẹ
- Bí èsì ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo se ń jáde rèé..
- Ìdí márùn ún tí agbára Covid 19 ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ kò fi tó tí àwọn ilẹ̀ àgbáyé míràn
- Ẹ gbọ́ òhun tí àwọn olùdíjé sípò gómìnà nípínlẹ̀ Ondo sọ nípa Bàbá ìsàlẹ̀...















