Lagos Building Collapse: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko gbé ìgbìmọ̀ olùwádìí kalẹ̀

Awoku ile to wo leko
Àkọlé àwòrán, Ọpọ obi lo ya bo awọn ileewosan lati mọ ipo ti awọn ọmọ wọn wa ti awọn miran ṣi n wa eeyan wọn

Ijọba ipinlẹ Eko ti yan igbimọ ẹlẹni maarun ti yoo ṣewadii awọn nkan to fa a ti ile alaja mẹta kan fi wo nipinlẹ naa.

Ijọba ipinlẹ Eko lo kede igbesẹ naa loju opo Facebook rẹ.

Ile alaja mẹta naa to wa ni Ita Faaji ni agbegbe Lagos Island lo wo lọjọ kẹtala oṣu Kẹta, to si fa ifarapa ati iku fun diẹ lara awọn to n gbe ninu ile naa.

Àkọlé fídíò, Àlàyé rèé lórí ilé kẹ̀ta tó wó l'Eko

Lasiko to n ṣe ifilọlẹ igbimọ naa, kọmisana fun ile kikọ ati idagbasoke ilu, Prince Rotimi Ogunleye sọ pe awọn nkan pataki ti igbimọ naa yoo mojuto ni wiwa ọna ti opin fi le de ba iṣẹlẹ ile wiwo lọjọ iwaju, to fi mọ iwa aibikita awọn abanikọle tabi ẹni to nile, ati ipa ti ijọba ipinlẹ naa n ko ninu iru iṣẹlẹ bẹ.

Bakan naa ni ireti wa pe igbimọ naa yoo ṣe agbekalẹ ilana ti yoo mu ki awọn to n kọle maa ṣe isẹ to pojuowo.

Alaga igbimọ naa, Onimọ ẹrọ Wasiu Olokunola ninu ọrọ rẹ, sọ pe igbimọ naa yoo ṣe iṣẹ to ni itumọ , nitori pe 'awọn ọmọ igbimọ naa ni iriri to yẹ ninu ile kikọ.'