Lagos building collapse: Àwọn aráàlú, LASEMA tako ara wọn lóríi síso ètò ìdóòlà ẹmí rọ̀

Awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi lati ileeṣẹ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, LASEMA ti ko irinṣẹ wọn kuro ni ibudo iṣẹlẹ ijamba ile to wo ni ilu Eko ni ọjọru.
Awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ṣiṣẹ mọju ni ibudo iṣẹlẹ naa lati ṣawari awọn eeyan to ṣeeṣe ki wọn ṣi wa labẹ awoku ile naa ṣugbsn ni kete ti ilẹ ms ni wọn palẹ irinṣẹ wọn mọ kuro nibẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọga agba ajọ LASEMA ti kọkọ fi to awọn oniroyin leti ni owurọ ọjọbọ pe ni kete ti awọn ba ti fi idi rẹ mulẹ pe ko si eeyan kan mọ labẹ awoku ile naa ni awọn yoo fi opin si eto idoola ẹmi nibẹ.
Titi di owurọ ọjọbọ, nnkan bii aadọta eeyan ni wọn ti yọ labẹ awoku ile yii, ti ko si din ni mọkanla ninu wọn to gbe ẹmi mi.
Amọṣa ọpọ awọn olugbe agbegbe naa ni wọn ṣi n fi apa janu ti pẹlu ibinu si ijọba pe ko tii yẹ ki wọn so eto idoola awọn eeyan rọ nitori pe awọn ṣi lero pe awọn eeyan kan ṣi wa labẹ ile naa.









