Oyo State: Kí ló ṣẹlẹ̀ níbi ìgbẹ́jọ́ Alao-Akala n'Ibadan lónìí?

Ile ẹjọ giga ni ilu Ibadan ti sun igbẹjọ gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ Otunba Christopher Adebayo Alao-Akala lori ẹsun iṣowo ilu bi bililọnu mọkanla aabọ kumọkumọ siwaju.
Ile ẹjọ naa to kalẹ si agbegbe Iyaganku n'Ibadan ni aisi ẹlẹri lo fa sababi ti o fi sun igbẹjọ naa si ọjọ keji oṣu karun un ọdun yii.
Kọmiṣọna tẹlẹ ri fun ọrọ ijọba ibilẹ ati ọrọ oye, Sẹnẹtọ Hosea Agboola ati oniṣowo Ọgbẹni Femi Babalola ni ajọ EFCC jọ fẹsun iṣowo ilu kumọkumọ kan.
Ẹsun onikoko mọkanla lajọ EFCC fi kan awọn mẹtẹẹta to da lori iditẹ, gbigbe iṣẹ fun kọgila lai se eto isuna.
Awọn ẹsun miran ti wọn fi kan wọn ni pe wọn ni ijẹri eke, rira dukia pẹlu owo jibiti ati gbigbe dukia naa pamọ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Alao-Akala
Agbẹjẹro for ajọ EFCC Ọmọwe B. Ubi sọ pe nigba ti Akala wa nipo gomina, o gbeṣẹ iṣẹ ọna ṣisẹ to to bilọnu mẹjọ aabọ fun ilẹ imọ ẹrọ Pentagon laarin ọdun 2007 si ọdun 2009.
Ọmọwe Ubi ni Ọgbẹni Babalọla lo ni ile iṣẹ ọhun, oun lo si ṣagbatẹru ni ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn kaakiri ipinlẹ Oyo lai se eto isuna fun isẹ naa.








