School Reopening: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kéde ṣíṣí gbogbo kíláàsì iléèwé padà

Oríṣun àwòrán, AFP
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede ọjọ ti gbogbo kilaasi awọn ileewe aladani ati ti ijọba ni ipinlẹ naa yoo wọle.
Eyi n waye lẹyin oṣu mẹfa ti wọn ti awọn ileewe pa nitori ajakalẹ aarun Coronavirus lorilẹede Naijiria.
Ijọ̀ba ipinlẹ Eko fi sita loju opo Twitter wọn pe kọmisọna eto ẹkọ nipinlẹ Eko, Folasade Adefisoye kede pe gbogbo awọn kilaasi to ku ti ko tii wọle tẹlẹ lee wọle pada.
Iwọle wọn yoo bẹrẹ lati ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹwa ọdun 2020.
Arabinrin Folasade sọ pe awọn ṣe ipinu yii lẹyin ọpọlọpọ ijiroro ati gbigba imọran pẹlu ati lọdọ tọrọ kan ati awọn akọṣẹmọṣẹ lori aabo to fi mọ awọn oludari awọn ileewe to ni kilaasi fun awọn ọjẹ wẹwẹ.
O fi kun un pe iwọle pada yii jẹ fun saa ikẹkọọ ọdun 2020/2021 o si kan awọn kilaasi jẹleosinmi paapaa naa atawọn nọọsiri alakọbẹrẹ.
Bakan naa ninu atẹjade kan ti adari ẹka ọrọ to kan araalu ni ileeṣẹ naa, Kayode Abayomi fi sita, o rọ awọn adari ileewe girama to jẹ aladani ki wọn tẹle ofin aabo eyi ti ijọba ti ṣaju fi sita lasiko Covid-19.
O tun sọ fun wọn pe ki wọn tẹle ofin imọtoto gẹgẹ bi ijọba ipinlẹ ṣe paṣẹ fun wọn nipasẹ ọfiisi to n ṣamojuto imọ ẹkọ to ye kooro (Office of Education Quality Assurance).
Wọn kilọ pe ọfiisi OEQA yoo maa ṣe amojuto igbaradi awọn ileewe to si jẹ pe awọn ni yoo maa fun awọn ileewe ni iwe aṣẹ lati wọle pada to si ni ki gbogbo awọn oludasilẹ ileewe aladani ri i daju pe wọn gba iwe aṣẹ lati ọfiisi ọhun ki wọn to wọle pada.
- Mọ̀ sí i nípa díẹ̀ lára àwọn èèyàn tí ikú wọn 'láti ọwọ́ ọlọ́pàá' milẹ̀ tìtì ní Nàìjíríà
- Wọ́n kò pa ẹnikẹ́ni sí ààfin Ṣọun Ogbomosọ, òkú tí àwọn ọdọ́ gbé wa ni ọlọ́pàá wọ́ jáde - Agbẹnusọ Ṣọ̀un
- Wo ìgbà mẹ́rin tí ìjọba ti tú ikọ̀ ọlọ́pàá SARS ká sẹ̀yín ṣùgbọ́n....
- A ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò ni pẹ̀lú títú FSARS ká, àtúntò ọlọ́pàá ń bọ̀- Buhari













