A ní ẹ̀rí tó pọ̀ pé Naira Marley àti Sam Larry dúnkookò mọ́ ẹ̀mí Mohbad tó fi kú - Ọlọ́pàá

Mohbad, Naira Marley ati Sam Larry

Oríṣun àwòrán, Collage

Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Eko, Idowu Owohunwa ti sisọ loju rẹ pe awọn ẹri to daju ti wa eyi to so Azeez Fasola, ti ọpọ eeyan mọ si Naira Marley.

Ati gbajumọ alafẹ kan nilu Eko, Balogun Eletu, ti ọpọ eeyan mọ si Sam Larry, mọ iwa idunkookomọni loju aye ati lori ayelujara.

Eyi to se ọsẹ nla fun ẹmi gbajumọ akọrin takansufe nni, Ilerioluwa Aloba, ti ọpọ eeyan mọ si Mohbad.

Owohunwa kede bẹẹ nibi ipade akọroyin to se lọsan oni lati salaye abọ iwadii awọn ọlọpaa lori iku Mohbad.

Amọ o ni Naira Marley ati Sammy Larry ti sẹ lori awọn ẹsun iwa ọdaran eyi to mu ki wọn lọwọ ninu iku Mohbad.

O ni awọn mejeeji ni awọn ni ẹri lati fi gbe ara awọn lẹsẹ pe awọn ko si nile laarin ọjọ Kẹwaaa si Ikejila osu Kẹsan ọdun 2023 lasiko ti isẹlẹ naa sẹlẹ.

"Ọpọ ẹlẹri lo fẹsun kan Naira Marley ati Sam Larry ati ikọ wọn pe wọn mu ọgbẹ lara Mohbad ni aimọye igba"

Amọ Owohunwa ni awọn ẹri pupọ wa pe wọn dunkooko mọ ẹmi Mohbad ati dida ọgbẹ si lara.

Gẹgẹ bi Kọmisana ọlọpaa naa ti wi, Sam Larry gba pe oun na Mohbad lọpọ igba lọna ati gba miliọnu meji Naira ti oun san fun lati wa sere nibi ayẹyẹ kan amọ ti ko yọju sibẹ.

Owohunwa ni “Lasiko iwadi wa, ọpọ awọn ẹlẹri lo fẹsun kan awọn afurasi mejeeji naa ati ikọ wọn yaju si Mohbad ni aimọye igba.

“A fidi rẹ mulẹ pe lọdun 2019 ni oloogbe naa darapọ mọ ileesẹ Naira Marley to n gbe orin jade amọ ti ede aiyede waye laarin awọn mejeeji.

Idi si ree ti Mohbad se ni oun fẹ yọwọ kuro ninu iwe adehun tawọn mejeeji tọwọ bọ, ti oun ko si fẹ ki aburo Naira Marley si maa jẹ Manija oun mọ.

Mohbad

Oríṣun àwòrán, Mohbad

Abẹ́rẹ́ mẹ́ta ọ̀tọ̀tọ̀ tí nọ́ọ̀sì fún Mohbad ló jẹ́ kí ikú rẹ̀ yá – Ọlọ́pàá

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Owohunwa wa fikun pe abajade ileesẹ ọlọpaa lori iku Mohbad ni awọn n kede rẹ lonii.

“Lọwọ yii, awọn afurasi marun un ni a ti mu, ti wọn si ti wa ni ahamọ wa bayii lori iku oloogbe naa.”

Lara awọn to ti wa ni atimọle ni “nọọsi to fun ni abẹrẹ mẹta ọtọtọ, eyii ti o wa lara nnkan to gbẹmi rẹ.”

“Nọoṣi naa gan ni ojulowo afurasi wa.”

“O jẹwọ pe awọn abẹrẹ ti oun fun oloogbe naa lo fa nnkan to pada yọri si iku Mohbad.”

Ọlọpaa ni nọosi ọhun wọ gau latari pe ko koju oṣuwọn, ko si ni iwe ẹri ijọba lati fun alaisan kankan ni abẹrẹ ati pe ibi to ti fun un ni abẹrẹ kii ṣe ile iwosan tabi ibi to yẹ ki wọn ti tọju alaisan.

“Ọgbẹni Ayobami Siduq ti wọn n pe ni ‘Spending,’ oun lo lọ pe nọọsi to fun Mohbad labẹrẹ, a fura si pe o gbimọpọ lọwọ ninu iku rẹ nitori ko pe ojulowo nọọsi.”

“Ibrahim Oluwatosin Owoduni ti apẹle rẹ n jẹ ‘Cryboy’... oun ati Mohbad ja, a ri oun naa gẹgẹ bii afurasi.”

O fi kun pe awọn mu Sam Larry ati Naira Marley nitori pe wọn lọwọ ninu ilu bara ti wọn na oloogbe naa gẹgẹ bii awọn fidio to wa lori ayelujara ti oloogbe ọhun ṣe ṣaaju iku rẹ, wọn si ti wa ni ahamọ.

Bakan naa ni Kọmiṣona ọlopaa ipinlẹ Eko ni eredi iwadii ileeṣẹ naa ko ṣẹyin ati mọ ohun gan to ṣokunfa iku oloogbe naa ati lati mọ awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.

Owohunwa ni lati mọ kulẹkulẹ ọrọ ọhun, awọn ṣe iwadii Azeez Adeshina Fashola ‘Naira Marley’ ati Samson Balogun ‘Sam Larry.’

Yatọ si awọn meji yii, o ni awọn tun ṣe iwadii ipa ti ajọ to n gbogun ti oogun oloro, NDLEA ko ninu iku rẹ.

"Eeyan mẹrindinlọgbọn ni a fọrọ wa lẹnu wo lori iku Mohbad"

Ọwohunwa sọ pe eeyan mẹrindinlọgbọn ni awọn ti gba ọrọ silẹ lẹnu wọn, lara wọn ni baba oloogbe, iya oloogbe, ẹgbọn oloogbe ọkunrin ati obinrin, to fi mọ iyawo rẹ atawọn mii.

Ọlọpaa tun gba ọrọ lẹnu Zlatan, ẹni to ni ọkọ ti wọn fi gbe Mohbad lọ sile iwosan lọjọ to ku, ayaworan oloogbe, oluranlọwọ rẹ, awakọ to gbe lọ si gbade ere to lọ kẹyin, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O fikun pe awọn se ayẹwo iwadii Autopsy nipa iku oloogbe naa, ti awọn si n reti ayẹwo naa bayii lati mọ ohun to pa Mohbad.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

"Ọgbẹ ti Mohbad gba lapa nibi ija oun ati ọrẹ rẹ, eyi to ti n wu, lo gbe lọ sile iwosan, ki Nọọsi to fun ni abẹrẹ to pa a"

Ọlọpaa ṣalaye pe ija kan waye laarin Mohbad ati ọrẹ rẹ kan nibi ode ere to lọ kẹyin, nibi to ti fi ọwọ ṣeṣe lasiko to fẹ fun ọrẹ rẹ naa ni ikuku.

Amọ ikuku naa ba gilasi ọkọ Prado ti wọn gbe lọ sibẹ, eyii to mu ko ṣeṣe.

Gẹgẹ ohun to sọ, awọn ọrẹ oloogbe mii to wa nibẹ sọ fun pe ko lọ sile iwosan nitori ọwọ ọhun ti bẹrẹ si wu.

Amọ Mohbad kọ jalẹ, o si sọ pe oun yoo pe nọosi oun to maa n tọju oun tẹlẹ.

Nọọsi naa ni ọlọpaa ni o fun oloogbe ọhun labẹrẹ mẹta ọtọtọ, eyii to ṣokunfa bi iku rẹ ṣe waye gẹgẹ bi wọn ṣe ni o jẹwọ ni agọ awọn.