Ayédèrú pọ́ńbélé ní ìwé ẹ̀rí tí Bola Tinubu gbé sílẹ̀ fún INEC lásìkò ìbò ààrẹ - Atiku

Tinubu ati Atiku

Oríṣun àwòrán, Atiku and Tinubu

Igbakeji ààrẹ tẹ́lẹ̀ nílẹ̀ wá, tó tún jẹ́ olùdíje fún ipò ààrẹ fẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP, Alhaji Atiku Abubakar tí ṣe ìpàdé àwọn akọ̀ròyìn kan nirọ̀lẹ òní.

Nibi ipade akọ̀ròyìn náà sì ni Atiku tí ṣàlàyé ìdí tó ṣe lọ beere fún iwe ẹri ààrẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ni Fáṣítì Chicago State University (CSU) to fi ìwé ẹri rẹ silẹ.

Tinubu lo fi iwe ẹri Diploma láti fasiti CSU naa silẹ fún àjọ eleto idibo ilẹ̀ wa, gẹgẹ bi ara iwe ẹri rẹ, lásìkò ibo ààrẹ tó wáyé losu kejì ọdún 2023.

Atiku, tí agbẹjọro rẹ àti tẹgbẹ oselu PDP, Kalu Kalu, jókòó tí, ní wón ṣàlàyé ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípa ohun tí wọn ba bọ lẹ́nu iwadi wọn ọ̀hún.

Àlàyé rèé lórí ìdí tí ìwé ẹri Bola Tinubu fi jẹ ayédèrú - Amòfin Atiku

Nigba tó ń sọ̀rọ̀, amofin Kalu Kalu ṣàlàyé pé ayédèrú ìwé ẹrú, tí Tinubu gbelẹ rọ, ló gbé silẹ fún àjọ eleto ìdìbò lásìkò ibo ààrẹ tó kọjá

Àmọ́ iléeṣẹ́ ààrẹ àtàwọn alatilẹyin ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti ṣẹ lori ẹsun naa.

"Àlàyé rèé tí ìwé ẹri Bola Tinubu fi jẹ ayédèrú"

Amofin Kalu tẹsiwaju pe yàtọ̀ sí pé ayédèrú ni ìwé ẹrú tí Tinubu gbé silẹ, orúkọ tó wà nínú ìwé ẹri náà tún jẹ́ ti obìnrin.

O ni èyí túmọ̀ sí pe kii ṣe Bola Tinubu lo ni ìwé ẹri naa.

"Idi kẹta ni pé fọọmu igbaniwọle sílè ẹ̀kọ́ Fáṣítì Chicago State University nínú èyí tí Bola Tinubu tí sọ pe oun lọ síle ẹ̀kọ́ gírámà Government College n'ilu Eko, tí òun sì kẹ́kọ̀ọ́ yege lọ́dún 1970 lo jẹ irọ pọnbele nítorí ọdún 1974 ni wọn ile ẹ̀kọ́ gírámà náà silẹ."

Amofin Kalu tẹsiwaju pe iwe ẹri fasiti CSU tí Tinubu fi silẹ fún àjọ INEC, safihan pe ọmọ ilẹ̀ Amerika to jẹ aláwọ̀ dúdú lo ni iwe ẹri náà.

O fikùn pé níwọ̀n ìgbà tí Tinubu tí ṣẹ ṣáájú pe oun kii ṣe ọmọ orílẹ̀ èdè méjì, a jẹ pe kii ṣe oun lo ni iwe ẹri náà.

"Nínú iwé ẹri naa, A tó wà nibẹ safihan pe Ahmed lo túmọ̀ sí àmọ́ ìwé ẹri ìsìnrú ìlú tí Bola Tinubu fi silẹ safihan pe A inú rẹ pé Adekunle lo n jẹ, òun kò sì mọ ibi tí Adekunle tí wá."

Irọ ni Atiku pa, ayédèrú kọ ní ìwé ẹri Bola Tinubu - Agbenusọ Tinubu

Ọkàn lára àwọn agbẹnusọ fún aare Bola Tinubu, amofin Wole Afolabi, tí kéde pé irọ́ tó jìnnà sootọ ni pé ayédèrú ni ìwé ẹri ààrẹ Bola Tinubu.

Temitope Ajayi, tíí ṣe amugbalẹgbẹ feto ìròyìn fún ààrẹ ṣàlàyé pé kò sí ọgbọ́n kankan nínú ẹ̀sùn pé Tinubu fi ayédèrú ìwé ẹri diploma silẹ fún INEC nítorí pé ó ti gba iwe ẹri rẹ ni fasiti náà.

O wa fi ọwọ́ gbaya pé ojúlówó pọnbele ni ìwé ẹri ti Tinubu gbé kalẹ fún àjọ INEC, tí fasiti CSU náà sì ti fi ontẹ lu pe àwọn kìí tun ìwé ẹri tó ba sọnù ṣe padà.