Cook-A-Thon: Alásè kan ní Ibadan ti ń gbìyànjú láti dáná fún wákàtí 200

Oríṣun àwòrán, bbc
Obinrin ẹni ọdun mọkanlelogun to n ṣe agunbanirọ lọwọlọwọ bayii niluu Ibadan, Idowu Peniel Ẹniọla, ti n gbiyanju lati se oriṣiriṣi ounjẹ fun igba wakati.
Wakati mẹtalelaadọrun ati iṣẹju mọkanla ni gbajugbaja alase niluu Eko, Hilda Baci fi dana, ki ajọ to n ṣe akọsilẹ awọn nnkan aramọnda l'agbaye (Guiness World Records) to fun un ni ami ẹyẹ gẹgẹ bii bii ẹni ti o se oriṣiriṣi ounjẹ fun wakati to pọ julọ l'agbaye.
Ṣugbọn lọwọlọwọ bayii, Ẹniọla ti n gbiyanju lati dana fun igba wakati, ti o si ṣeeṣe ki o ju bẹẹ lọ gẹgẹ bi awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ ṣe ṣalaye fun akọroyin BBC Yoruba.
Bo tilẹ jẹ pe Ẹniọla ko fi orukọ silẹ pẹlu ajọ GWR saaju igbesẹ naa, erongba rẹ ni lati fi awọn fọnran ina ti o da han ajọ naa nigba ti o ba ṣetan.
“Ajọ mẹrin ọtọtọ ni mo forukọ silẹ fun yatọ si GWR”
Peniel Ẹniọla fi idi rẹ mulẹ fun akọroyin wa wi pe kii ṣe ajọ GWR nikan ni afojusun oun.
O ni oun fi orukọ silẹ pẹlu ajọ mẹrin ọtọọtọ mii to n fun awọn to ba ṣe nnkan aramọnda ni iwe ẹri ati ami ẹyẹ l'agbaye.
O fi kun ọrọ rẹ pe igbesẹ lati dana fun igba wakati kii ṣe lati ta kangbọn pẹlu Hilda Baci nitori oju ọrun to ẹyẹ fo.
Lati Ọjọbọ, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan an, ni Ẹniọla ti bẹrẹ si n se oriṣiriṣi ounjẹ.
Gbogbo awọn ololufẹ rẹ to ṣe abẹwo si ile itura Ọmọoke to n bẹ niluu Ibadan nibi ti o ti n dana naa lo si ti n jẹun ọfẹ lati igba naa.
O ṣeeṣe ki o yọri ina to n da lọjọ Ẹti, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa ọdun yii, nigba ti igba wakati ba pe.
A ṣe akiyẹsi wi pe wọn kọ imọlẹ si ara aṣọ ti Ẹniọla ati ẹni to n baa dana wọ.
Alaye ti o ṣe fun akọroyin wa nipa eleyii ni pe oun naa n pe fun idajọ ododo lori iku gbajugbaja olorin takasufee, Ilerioluwa Alọba, ti ọpọ eeyan mọ si Mohbad.
Saaju ki Hilda Baci to gba ami ẹyẹ ni awọn ọmọ Naijiria ti n ṣe nnkan aramọnda ti ajọ GWR si n fun wọn ni iwe ẹri ati ami ẹyẹ.

Oríṣun àwòrán, bbc
Lara awọn to ti gba ami ẹyẹ naa sẹyin ni Fẹla Kuti, akọrin ti wọn pe ni 'Modenine', Yakubu Adeṣokan, Kaffy onijo, Joy Ọnaọlapọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ṣugbọn awọn nnkan aramọnda ti ọmọ Naijiria n gba bi ẹni gba igba ọti lẹyin ti Hilda Baci gba iwe ẹri tirẹ tan tun peleke sii.
Lara igbesẹ naa ni ti Tonye Solomon to gba ami ẹyẹ ninu oṣu Kẹjọ ọdun yii, fun gigun akasọ to pọ julọ l'agbaye pẹlu bọọlu alafẹsẹgba lẹsẹ lori rẹ.
Akẹkọọ fasiti ijọba apapọ, FUTA to n bẹ niluu Akurẹ naa gba ami ẹyẹ ati iwe ẹri gẹgẹ bii ẹni ti o se agbekalẹ ọrọ sisọ fun wakati ti o pọ julọ lagbaye ninu oṣu kẹẹsan ọdun yii bakan naa.
Kodaa, arakunrin kan n'ipinlẹ Ekiti kede wi pe oun yoo ṣe oun ti ẹnikan ko ṣe nipa ṣiṣẹ ifẹnukonu pẹlu obinrin fun wakati ti o pọ julọ l'agbaye, ṣugbọn ijọba ipinlẹ Ekiti koro oju sii.












