Ilé aṣojúṣòfin l'Abuja képe ọ̀gá ọlọ́pàá láti ṣe ìwádìí ikú aláboyún àti awakọ̀ kẹ̀kẹ́ Marwa l'Eko

Oríṣun àwòrán, LASTMA/X
Ile aṣojuṣofin Naijiria, niluu Abuja ti kepe ọga agba ọlọpaa ni Naijiria, Kayode Egbetokun lati ṣe iwadii ijamba ọkọ to ṣekupa alaboyun kan ati awọn awakọ kẹkẹ Marwa lagbegbe Ago Palace niluu Eko lọjọ Iṣẹgun.
Ohun ti a gbọ ni pe ọlọpaa kan to n ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ LASTMA to n ri si lilọ bibọ ọkọ nipinlẹ Eko n lọ ọwọ ọkọ Sienna tawọn LASTMA mu mọ awakọ naa lọwọ ti ọkọ naa si lọ kọlu kẹkẹ Marwa nibi ti alaboyun kan ati awakọ Marwa ti ku tawọn akẹkọọ meji si farapa.
Aṣofin Jesse Onuakalusi to n ṣoju ẹkun Oshodi/Isolo lo da aba fun ile ni Ọjọru lati sẹ agbeyẹwo iṣẹlẹ ọhun.
Onuakalusi ni iru awọn iṣẹlẹ idunkoko awọn oṣiṣẹ LASTMA ati ọlọpaa mọ awọn eeyan ti n pọju.
Aṣofin Onuakalusi sọ fun ile pe o ṣe pataki lati wa ọna ti opin yoo de ba gbogbo irufẹ bayii.
Lẹyin atotonu rẹ ni gbogbo ile bu ẹnu ẹtẹ lu iṣẹlẹ naa ti wọn si kepe ọga ọlọpaa ni Naijiria lati ṣe iwadii iṣẹlẹ naa ki o si fi iya to tọ jẹ ẹnikẹni ti aje iwa ibajẹ ninu iṣẹlẹ naa ba ṣi mọ lori.
Ọrọ ajọ LASTMA lori iṣẹlẹ naa
Gẹgẹ bi atẹjade ti ajọ LASTMA fi soju opo X rẹ lọjọ Iṣẹgun, ajọ naa ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ awọn kan lo mu awakọ Sienna alawọ buluu eyi to n gba ọna to lodi si ofin ti ọpọ mọ si ''one-way.''
Ajọ LASTMA ṣalaye pe nibi to ti n salọ lo ti fi ọkọ rẹ gba kẹkẹ Marwa lagbagbe Okota nibi ti awakọ kẹkẹ naa ti ku lẹsẹkẹsẹ ati alaboyun kan tawọn akẹkọọ meji si farapa.
Oṣiṣẹ LASTMA to dari awọn to mu awakọ naa, Hassan Kehinde ṣalaye pe ọlọpaa to n ṣisẹ pọ pẹlu awọn oṣiṣẹ LASTMA lo pinnu lati tẹle awakọ naa lọ si ọfiisi LASTMA.
Ọgbẹni Kehinde ṣalaye pe loju ọna wọn si ọfiisi LASTMA ni awakọ yii gbiyanju lati salọ ti o si dari ọkọ rẹ si opopona Bayo Oyewale ni Ago nibi ti o ti kọlu kẹkẹ Marwa ti ero wa ninu rẹ.
O fidi rẹ mulẹ pe loju na ni awakọ kẹkẹ naa gbẹmi mi, nigba ti alaboyun to wa nibẹ ku nile iwosan.
Awọn akẹkọọ meji to wa nibẹ ni oṣiṣẹ LASTMA sọ pe wọn si n gba itọju nile iwosan.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko naa sọrọ
Ninu ọrọ tiẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin ṣalaye loju opo X rẹ pe awakọ kan to sa fawọn oṣiṣẹ ajọ LASTMA nigba ti o gba ọna to lodi sofin ni o lọ kọlu kẹkẹ Marwa.
SP Hundeyin o ṣeni laanu pe eeyan meji lo ku ninu iṣẹlẹ naa nigba tawọn ọmọde meji to farapa nibẹ si n gba itọju lọwọ nile iwosan.
Ọgbẹni Hundeyin ni awọn eeyan kan ti o binu lori iṣẹlẹ naa lu ọlọpaa ti o n ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ LASTMA debi wi pe o farapa yanayana.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
SP Hundeyin ni ọlọpaa ọhun ko le sọrọ, amọ o n si n gba itọju nile iwosan bakan naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni alaafia pada jọba ni agbegbe naa lẹyin tawọn ọlọpaa lọ sibẹ.
O ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.















