Kí ni ohun tó kàn báyìí lẹ́yìn tí NLC àti TUC wọ́gilé ìyanṣẹ́lódì wọn tó yẹ kó bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Nkechi Ogbonna
- Role, BBC News, Lagos
Ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria, NLC ati TUC ti wọgile iyanṣelodi wọn alailọjọ ti wọn kede pe yoo bẹrẹ lọjọ Iṣegun ọsẹ yii.
Igbesẹ lati wọgile iyanṣelodi naa lo waye lẹyin ti wọn ṣe ipade pẹlu ijoba apapọ lalẹ ọjọ Aje niluu Abuja.
Ṣaaju ni ẹgbẹ naa ti kọkọ kede iyanṣelodi ọhun lẹyin ti wọn fẹsun kan ijọba apapọ pe o kọti ikun si awọn ohun ti awon n bere fun.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
Ẹgbẹ oṣiṣẹ sọ pe adehun ti wa laarin oun ati ijọba apapọ ṣaaju, ati pe ijọba apapọ ṣeleri lati mu awọn adehun naa ṣe laarin ọgbọn ọjọ pere.
Ẹwẹ, Aarẹ Bola Tinubu ti kede awọn igbesẹ tuntun lati mu aye dẹrun fun awọn oṣiṣẹ ninu ọrọ rẹ to ba awọn araalu sọ lọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023, to jẹ ayajọ ọjọ ominira Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lara awọn igbesẹ tuntun naa ni kiko awọn ọkọ akero tuntun sita, eyii ti yoo maa lo afẹfẹ gaasi.
Tinubu tun kede pe awọn oṣiṣẹ ijọba ti ipo wọn kere yoo gba afikun ₦25,000 lori owo oṣu wọn fun oṣu mẹfa gbako.
Ki ni eredi ti ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣe fẹ yanṣelodi?
Lọjọ ti Tinubu gba iṣakoso ijọba Naijiria lo kede pe oun yoo fopin si owo iranwọ ori epo bẹntiro ni Naijiria, eyii to mu ki iye owo ti wọn n ta epo bẹntiro naa gbowo lori ni nnkan bii ida irinwo lati oṣu mẹrin sẹyin.
Yatọ si epo bẹntiro, ounjẹ atawọn nnkan mii lo tun gbowo lori, eyii to mu ko nira fun ọpọ araalu lati ri ounjẹ oojọ wọn.
Iṣẹlẹ naa tun mu ki owo naira ja wa silẹ nigba ti owo dollar ilẹ Amẹrika ga soke ju bo ṣe yẹ lọ, ti ara si n ni ọpọ araalu.
Ọpọ awọn oniṣowo to n lo epo bẹntiro fun owo wọn lo nira fun lati ṣowo jere.
Bi awọn to ni ọkọ sile ko ṣe le gbe ọkọ wọn jade bii ti tẹlẹ mọ naa ni awọn to n wọ ọkọ igboro n kerora latari owo ọkọ to wọn gogo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki ni ẹgbẹ oṣiṣẹ n fẹ lati ọwọ ijọba?
Pataki lara awọn nnkan ti ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC n bere fun ni afikun owo oṣu gbogbo oṣiṣẹ ni Naijiria.
Wọn ni awọn n fẹ ki oṣiṣẹ ti owo oṣu rẹ kere julọ maa gba ₦200,000 loṣu, ko le rọrun fun wọn lati koju ọwọngogo to wa lode.
Lọwọ yii, ₦30,000 pere ni owo oṣiṣe to kere julọ ni Naijiria, eyii ti ko to nnkan.
Ki ni ohun to kan?
Ijọba ti n wa ọna abayọ si bi yoo ṣe yanju họwuhọwu to n waye laarin rẹ ati ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ.
Aarẹ Tinubu sọ pe oun mọ pe ara n ni awọn araalu amọ awọn atunto eto ọrọ aje to n lọ lọwọ ṣe pataki fun anfani gbogbo mutumuwa lọjọ iwaju.
O ni “A mọ pe awọn atunto wọnyii yoo nira, amọ fun anfani gbogbo wa ni.”
Igbagbọ wa pe ijọba apapọ ati ẹgbẹ oṣiṣẹ yoo le yanju họwuhọwu to wa laarin wọn ki ọgbọn ọjọ ti ẹgbẹ naa da fun ijọba to pe, ki iyanṣelodi ọlọjọ gbọrọ ti wọn ṣeleri rẹ ma si le waye.












