Ohun tí àjọ LASTMA àti ọlọ́pàá sọ lórí ìjàmbá ọkọ̀ tó mú ẹ̀mí lọ ní Ago Palace l'Eko rèé

Oríṣun àwòrán, LASTMA/X
Oniruuru iroyin lo ti jade lori ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lagbegbe Ago Palace niluu Eko lọjọ Iṣẹgun papaa julọ lori iye eeyan to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Bi awọn kan ti n sọ pe eeyan kan lo ku, lawọn mii n sọ pe ko din ni eeyan marun un to ba iṣẹlẹ ọhun lọ.
Amọ, kinni ajọ to n ri si lilọ bibọ ọkọ loju popo nipinlẹ Eko, LASTMA ati ileeṣẹ ọlọpaa sọ lori iṣẹlẹ naa?
Gẹgẹ bi atẹjade ti ajọ LASTMA fi soju opo X rẹ lọjọ Iṣẹgun, ajọ naa ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ awọn kan lo mu awakọ Sienna alawọ buluu eyi to n gba ọna to lodi si ofin ti ọpọ mọ si ''one-way.''
Ajọ LASTMA ṣalaye pe nibi to ti n salọ lo ti fi ọkọ rẹ gba kẹkẹ Marwa lagbagbe Okota nibi ti awakọ kẹkẹ naa ti ku lẹsẹkẹsẹ ati alaboyun kan tawọn akẹkọọ meji si farapa.
Oṣiṣẹ LASTMA to dari awọn to mu awakọ naa, Hassan Kehinde ṣalaye pe ọlọpaa to n ṣisẹ pọ pẹlu awọn oṣiṣẹ LASTMA lo pinnu lati tẹle awakọ naa lọ si ọfiisi LASTMA.
Ọgbẹni Kehinde ṣalaye pe loju ọna wọn si ọfiisi LASTMA ni awakọ yii gbiyanju lati salọ ti o si dari ọkọ rẹ si opopona Bayo Oyewale ni Ago nibi ti o ti kọlu kẹkẹ Marwa ti ero wa ninu rẹ.
O fidi rẹ mulẹ pe loju na ni awakọ kẹkẹ naa gbẹmi mi, nigba ti alaboyun to wa nibẹ ku nile iwosan.
Awọn akẹkọọ meji to wa nibẹ ni oṣiṣẹ LASTMA sọ pe wọn si n gba itọju nile iwosan.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ninu ọrọ tiẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin ṣalaye loju opo X rẹ pe awakọ kan to sa fawọn oṣiṣẹ ajọ LASTMA nigba ti o gba ọna to lodi sofin ni o lọ kọlu kẹkẹ Marwa.
SP Hundeyin o ṣeni laanu pe eeyan meji lo ku ninu iṣẹlẹ naa nigba tawọn ọmọde meji to farapa nibẹ si n gba itọju lọwọ nile iwosan.
Ọgbẹni Hundeyin ni awọn eeyan kan ti o binu lori iṣẹlẹ naa lu ọlọpaa ti o n ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ LASTMA debi wi pe o farapa yanayana.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
SP Hundeyin ni ọlọpaa ọhun ko le sọrọ, amọ o n si n gba itọju nile iwosan bakan naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni alaafia pada jọba ni agbegbe naa lẹyin tawọn ọlọpaa lọ sibẹ.
O ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.
Ènìyàn kan kú, àwọn mẹ́rin farapa bí òṣìṣẹ́ LASTMA àti àwakọ̀ ṣe ń lọ́ ọkọ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́
Ènìyàn kan ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀, tí àwọn mẹ́rin mìíràn sì farapa bí ìfaǹfa ṣe wáyé láàárín awakọ̀ kan, àwọn òṣìṣẹ́ tó ń mójútó ìrìnnà ojú pópó ní ìpínlẹ̀ Eko, LASTMA àti ọlọ́pàá kan ní agbègbè Ago Palace Way, Isolo, ìpínlẹ̀ Eko.
Ìròyìn tó tẹ BBC Yorùbá lọ́wọ́ ní nǹkan bí aago mẹ́sàn-án òwúrọ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni ìjàmbá náà wáyé nígbà tí awakọ̀ náà ń gbìyànjú láti móríbọ̀ lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA tó ń le ló lọ kọlu àwọn èèyǹ náà.
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ní àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA náà lé awakọ̀ náà lẹ́yìn tó rú òfin ojú pópó ṣùgbọ́n tó kọ̀ tí kò dúró.
Wọ́n ní LASTMA náà lọ “steering” mọ́ awakọ̀ náà lọ́wọ́ tó sì pàdánù ìjánu ọkọ̀ rẹ̀.
“Lẹ́yìn tó pàdánù ìjánu ọkọ̀ náà ló lọ kọlu àwọn ènìyàn márùn-ún tó ń kọjá lọ tí ọ̀kan nínú wọn sì pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lójú ẹsẹ̀, tí àwọn yòókù sì farapa.”
Agbẹnusọ LASTMA, Adebayo Taofiq fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn tó sì ní àwọn máa fi bí ìṣẹ̀lẹ̀ ṣe jẹ́ síta láìpẹ́.
Bákan náà ni ọ̀gá àgbà àjọ tó ń mójútó òpópónà ìjọba àpapọ̀, Babatunde Farinloye fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ènìyàn kan ló bá ìjàmbá náà lọ.















