Àwọn onímọ̀ ṣe àwárí ibùdó àkọ́kọ́ t'áwọn òyìnbó amúnisìn ń kó ẹrú pamọ́ sí ní ilẹ̀ adúláwọ̀

Aworan awọn ti wọn wu ilẹ

O ṣeéṣe ki wọn ti rí ọkánkán ninu awọn ibudo akọkọ t'awọn oyinbo ko awọn ẹru alawọdudu si - ababọ BBC ree lori iwadii pataki to laami-laaka yi ni Ghana.

Pẹlẹpẹlẹ ni onimọ iwadii ijinlẹ nípa nnkan Aye atijọ yi, Christopher DeCorse fi n to awọn nkan meremere to rí sori tabili lẹgbẹ ibi ti wọn ti n gbẹ ilẹ.

Ninu awọn nkan to fi ẹlẹ ko kalẹ ni etu ibọn wa, ikoko aye atijọ ti wọn fi n fa taba, afọku ikoko ati egungun ẹnu ewúrẹ.

Awọn nkan ti wọn wu jade ninu ilẹ jẹ atọna si nkan to sẹlẹ nibi laimọye ọdun sẹyin.

Ọjọgbọn yii to wa lati fasiti Syracude lorileede America bu sẹrin to si sọ pe "Ẹni to ba jẹ onimọ iwadii ijinlẹ nipa nnkan Aye atijọ to ba ni inu oun kii dun ti oun ba ti n ri nnkan meremere ko sọ ootọ rara"

O ni "Awọn nkan ti a wu jade yii jẹ itọsọna lati fi ẹsẹ ododo rinlẹ pe aaye yi l'awọn oyinbo amunisin fi kọkọ ko awọn ẹru adulawo si ni gbogbo ilẹ Afrika"

Ìbí aaye awoku ibudo Fort Amsterdam to dojú kọ omi okun ni onimọ yi wa.

Ninu aaye yi l'awọn nkan ti wọn lero pé o jẹ asẹku ibùdó to tobi mii tí wọn pè nì Kormantine wa.

O ti pẹ ti aaye yi ti ba ìgbà lọ tàwọn oṣiṣẹ Ọjọgbọn yi sì n wu jáde síta padà.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹsọ pẹlẹ ni wọn fi n ṣe ìṣe yi.

Gbogbo iyẹpẹ ti wọn ba wu jáde ní wọn n fi ajọ jọ pada sí inu ilẹ.

Wọn tà pẹpẹ kan bo ori ìbí tí wọn wá bí isẹ wọn ṣe n tẹsiwaju.

Ìbí tí aaye yi wa jẹ nkan t'awon èèyàn ko lè sọ pato amọ iwadii yi ti wa mú òpin ba gbogbo tabi ṣugbọn lori ọrọ yi.

Ni nkan bí odun 17th Century lọhun ni Fort Kormantine jẹ ibudo pataki tàwọn alawofunfun ti bẹrẹ sí ní yi ọkàn kuro nidi owo goolu tita sí owo tita ati rira ọmọnìyàn.

Asiko yi jẹ ìgbà pataki nipa ibaṣepọ wọn pẹlu ilẹ adúláwọ̀.

Nkan tàwọn onimọ iwadii yi ba ti ṣeeṣe kò tan imọlẹ si igbe aye awọn oyinbo yí àti tàwọn eeyan ti wọn kò lẹru.

Bẹẹ yoo jẹ kí a mọ nipa ipa ti tita ati rira eeyan yi ni lori awọn eeyan agbegbe to ti waye.

Pupọ awọn agbegbe eti omi okun Ghana ni ọgbẹ owo eeyan tita yi kò tan lọkan wọn.

Kaakiri agbegbe Gold Coast láwọn ibudo ti wọn tí n ta eeyan soke òkun yi wa.

Àìmọye ẹgbẹrun lọnà ẹgbẹrun eeyan lo gba ibudo yi wọ ọkọ ojú omi lọ ìrìnàjò aremabọ.

Fort Kormantine - ti wọn kọ ní ọdún 1631 jẹ ọkan lara ìbí tí owo yi ti kọkọ bẹrẹ.

Nígbà náà aaye ìbí tí wọn yóò ti máa ta Goolu,ati eyin erin ni wọn fi pilẹ rẹ.

Ọdun 1663 ni owo eeyan tita bẹrẹ níbẹ lẹyìn tí Oba Charles II fun ileesẹ Royal Adventurers of England ni iwe aṣẹ lati ṣòwò dé ilé adúláwọ̀.

Ileeṣẹ yi l'orukọ padà yi padà si Royal African Company.

O gbé aṣẹ fawọn nìkan lati maa ṣe owo tita èèyàn kaakiri ilẹ adúláwọ̀.

Ìgbà ọdun gbako láwọn oniṣowo ilẹ Gẹẹsi nikan fi da owo eeyan tita ṣe kí àwọn ẹya Dutch to gba mọ wọn lọwọ ti Fort Kormantine sí wa ní ipo pataki ninu owo eeyan tita yi.

Wọn lò aaye yi gẹgẹ aaye ikẹrupamọ sí.

Àwọn ẹrù yi ni wọn fi n ṣe pasiparọ eeyan ti wọn wa ra.

Lati ibì ni wọn tí wá n ko awọn ti jigbe sinu ọkọ oju ojo lati lọ tàwọn ni ilẹ Carribean fawọn to n fi wọn dako níbẹ.

Eyi ni wọn fí mu idagbasoke ba okoowo Sugar láwọn ilẹ wọnyi.

Aworan Omokolade Omigbule

"A kò ní ìmọ púpọ nípa bi awọn aaye ti wọn tí n ta awọn eeyan yi se ri nígbà náà lọhun ti eyi si jẹ ko dun mọ wa pé a rí ibudo Fort Kormantine yi"

Lẹyìn tí ọwọ awọn eeyan Dutch yi tẹ ibùdó yi ni wọn kọ Fort Amsterdam sí ibẹ bakan naa. Eyi lo mú kí o sọro lati mọ pato ibi ti Fort Kormantine gangan wa.

Amọ ilẹ tí wọn gbẹ ní ọdún 2019 lẹgbẹ Fort Amsterdam to jẹ kí wọn rí awọn nkan mere-mere kan lati ọdún 17yh Century tubọ jẹ kí wọn ni igbagbọ nípa ìbí to wá gangan.

Àwọn onimọ pada wa sibẹ ní ìbẹrẹ ọdún yi ti wọn sì tẹsiwaju iwadii.

Nigba ti wọn kọkọ bẹrẹ ike ati awọn nkan mii tàwọn eeyan ṣẹṣẹ da sibẹ ni saa táa wa yi ni wọn kọkọ rí.

Amọ akẹkọọ ọmọ orilẹ-ede Naijiria kan Omokolade Omigbule lori okuta kan ti Ọjọgbọn DeCorse sọ pe o jẹ afọku nkan mii tó tobi.

"Iyalẹnu ló jẹ nígbà táa rí asẹku ilé tí o wa n'ibi ibùdó Fort Amsterdam yi "

Ọrọ to jade lẹnu akẹkọọ fasiti Virginia yi ree.

O ní " riri awọn oju ẹsẹ ìbí tàwọn ajoji yi tẹ nígbà tí wọn kọkọ wa sí Afrika mú ọkàn mi padà sí àìmọye ọdún sẹyìn"

Bi wọn ṣe n tẹsiwaju pẹlu ilẹ tí wọn n gbẹ ní wọn ṣe wati ogiri, ojú ìbí to gbé ilẹkùn duro ati ojú omi agbara tí wọn fí bulọọku amọ pupa kọ.

Gbogbo awọn nkan yi ṣafihan pé awọn oyinbo Gẹẹsi tí gbé aaye yi rí ìyẹn Dutch Fort.