Ọmọ ọdún mẹ́rìnlà yìnbọn pa èèyàn mẹ́ta àti ọlọ́pàá nílé ìtajà

Aworan awọn ọkọ agbofinro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Eeyan mẹta ati ọlọpaa kan ti jade laye lorilẹede Thailand lẹyin ti ọmọ ọdun mẹrinla kan ṣina ibọn bolẹ ni ibudo itaja kan ni ilu Bangkok.

Awọn alaṣẹ ni ọwọ agbofinro ti tẹ ọmọdekunrin naa.

Awọn ọlọpaa sọ pe aja kẹta ile itaja naa ni ọmọdekunrin ọmọ ọdun mẹrinla naa ti jọwọ ara rẹ fun awọn ọlọpaa.

Awọn ọlọpaa nibi iṣẹlẹ naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ohun ti a mọ lọwọ yii.

  • Eeyan mẹta lo ti ku.
  • Ọpọ eeyan miran lo fara pa lasiko ti ọmọdekunrin naa fi ṣina ibọn bolẹ
  • Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Reuters ṣe sọ, eeyan kan ti kii ṣe ọmọ orilẹede naa wa lara awọn to fara pa.
  • Ile itaja Siam Paragon Shopping Center to wa lolu ilu orilẹede naa ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Ile itaja igbalode Siam Paragon

Oríṣun àwòrán, EPA

Olotu ijọba orilẹede Thailand, Srettha Thavisin ti sọ pe oun ti paṣẹ fun ọga agba ọlọpaa lorilẹede naa lati tete mojuto ọr naa.

Ninu ọr rẹ, Ọgbẹni Thavisin ba awọn mọlẹbi awọn to ku ninu iṣẹlẹ naa kẹdun atawọn to fara ṣeṣe.

‘Wakati meji la fi sa pamọ si inu ṣọọbu kan’

Ọkan lara awọn to wa raja ni ile itaja igbalode naa

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ọkan lara awọn eeyan ti ọrọ naa ṣe oju wọn ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe o le ni wakati meji ti awọn fi sa pamọ ninu ṣọọbu itaja kan.

O ni iro ibọn mẹfa si meje loun gbọ.

Shir Yahav to jẹ arinrinajo afẹ lati orilẹede Israel ṣalaye pe nigba ti oun ri awọn eeyan to n sare loun naa ba fi ẹsẹ fẹ ẹ lai tilẹ ni oye ohun to n ṣẹlẹ lasiko naa.

O ni oun wa lara awọn eeyan kan to fara pamọ si inu ṣọbu kan fun nnkan bii “wakati meeji, wakati kan abọ, a si di ilẹkun pa.”

Hilahilo lawọn eeyan to wa nile itaja naa n sa nigba ti iro ibọ naa n dun.

Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye ni ṣisẹ n tẹle

Bi wọn ṣe mu ọmọdekunrin naa

Oríṣun àwòrán, Rescue workers association/ reuters

Nigba ti awọn ọlọpaa yoo fi de ibẹ, ti wọn yoo si fi gba agbara lọwọ ọmọdekunrin to n yinbọn naa, ọplọpọ awọn eeyan ni ibọn ti ba.

Awọn ọlọpaa ni ileẹkọ kan ti ko jina si ile itaja nla naa ni ọmọdekunrin ọhun ti n kẹkọọ.

Amọṣa ko tii si ẹni lee sọ ohun gan to ṣokunfa igbesẹ ti ọ̀mọ naa gbe.

Ile itaja igbalode naa wa lara ile itaja ti awọn onibara n na julọ nilẹ Asia

Nnkan bii agogo mẹrin irọlẹ kọja ogun iṣẹju lorilẹede naa, eyi to ja si agogo mẹwaa owurọ kọja ogun iṣẹju.

Nnkan bii agogo marun irọlẹ kọja iṣẹju mẹwaa ni ikọ ọlọpaa kogberegbe yii po ti ko si ri ọna ati lọ ibikibi mọ to fi wa jọwọ ara rẹ ati ibọn ọwọ rẹ silẹ.

Iṣẹlẹ ibọn yinyin kii saba waye ni Thailand

Aworan ọkọ idolla ẹmi kan nibẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iṣẹlẹ ibọn yinyin si ọpọ ero gẹgẹbi eyi to waye yii kii ṣe ohun to saba maa n waye lorilẹede Thailand, bi o tilẹ jẹ wi pe iye awọn to ni ibọn ni ikawọ pọ lẹkun naa.

Ni oṣu kẹwaa ọdun to kọja, ọlọpaa fẹyinti kan yinbọn pa eeyan mẹtadinlogoji, pupọ ninu wọn lo si jẹ ọmọde.

Ibọn ati ọbẹ ni arakunrin naa fi ṣe ọṣẹ ni ile ẹkọ jẹleosinmi naa lẹkun Nong Bua Lamphu ni ẹkun ila oorun ariwa orilẹede Thailand.

Ni ọdun 2020, ṣọja kan pẹlu tun ṣekupa eeyan mọkandinlọgbọn nigba naa ni ilu Nakhon Ratchasima.