Èèyàn mẹ́wàá kú, ọgọ́ta farapa nígbà tí òrùlé ṣọ́ọ̀ṣì já lé àwọn olùjọ́sìn lórí

Aworan orule ṣọọṣi to ja lulẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ko din ni eeyan mẹwaa to dero ọrun nibi ti ọpọ ti farapa nigba ti orule ṣọọṣi kan ja lulẹ le awọn le awọn olujọsin lori lorilẹede Mexico.

Ọsan ọjọ Aiku to kọja yii, iyẹn ọjọ kinni, oṣu kẹwaa, ọdun 2023 ti a wa yii ni iṣẹlẹ ọhun waye ni ṣọọṣi Santa Cruz to wa niluu Ciudad Madero, apa ariwa orilẹede Mexico.

Iroyin to tẹ BBC lọwọ fidi rẹ mulẹ pe ọmọde mẹta lo wa lara wọn to ba iṣẹlẹ naa lọ, nigba ti awọn ti ko din ni ọgọta eeyan to farapa yannayanna nibi iṣẹlẹ naa.

Aworan ṣọọṣi ti orule rẹ ja lulẹ

Oríṣun àwòrán, Reuters

A gbọ pe ọgọrun eeyan lo wa ninu ṣọọṣi ọhun, nibi ti wọn ti lọ kopa ninu eto itẹbọmi to waye nibẹ.

Yatọ si awọn wọnyii, a tun gbọ pe ọpọ ninu wọn lo wa labẹ ile ṣọọṣi naa, to si gba awọn oṣiṣẹ eleto abo ni ọpọ wakati ko to di pe wọn ri wọn yọ jade lati doola ẹmi wọn lasiko iṣẹlẹ naa.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe kayeefi nla lo jẹ fun ọpọ awọn to wa lagbegbe naa nigba ti orule ṣọọṣi ọhun deede wo lulẹ.

B’awọn kan ṣe sare lọ sibẹ pẹlu ọkọ ati àáké, bẹẹ l’awọn miiran sare ranṣẹ si awọn eleto abo, to fi mọ awọn oṣiṣẹ eleto ilera fun iranlọwọ.

Ko pẹ rara ti wọn l’awọn oṣiṣẹ eleto aabo fi sare debẹ pẹlu awọn ọkọ nla ti wọn n pe ni Crane meji ọtọọtọ lati yọ awọn paanu ati orule to wo naa kuro lori awọn eeyan.

Aworan orule ṣọọṣi to ja lulẹ

Oríṣun àwòrán, Reuters

Nigba to n sọrọ, gomina ipinlẹ Tamaulipas ti iṣẹlẹ ọhun ti waye, f’idi rẹ mulẹ pe gbogbo awọn to di awati lasiko iṣẹlẹ ọhun ni wọn ti ni akọsilẹ wọn, ti ikọ eleto aabo si ti bẹrẹ iṣẹ lori wọn.

B’awọn kan ṣe n sọ pe bi wọn ṣe kọ ṣọọṣi naa ni ko ba oju mu to, bẹẹ l’awọn miiran n sọ pe kii ṣe lasan, ti awọn kan si n ni afi ki awọn agbaṣẹṣe to kọ ṣọọṣi ọhun wa a ṣalaye idi ti orule naa fi ja lulẹ lojiji.

Alufa Ángel Vargas to n ṣayẹyẹ itẹbọmi naa lọwọ ṣaaju iṣẹlẹ ajalu naa ṣalaye pe iṣẹlẹ naa ti sọ ayẹyẹ awọn di ibanujẹ, to si lo kọ wọn lominu pupọ.

Lara awọn akọroyin Franc Conteras to wa nibi iṣẹlẹ ọhun sọ fun BBC pe asiko ti isin naa n dun lọwọ ni orule deedee ja le wọn lori eleyii to jẹ ẹdun ọkan lo jẹ fun wọn.

Aworan agbegbe naa

Ninu ọrọ wọn, wọn jẹ ko di mimọ pe awọn eeyan ti to sori ila lati gba ounjẹ alẹ Oluwa – eyi si ni ipe to ṣe koko julọ ninu isin Katoliiki (Catholic Mass) – igba yẹn ni orule yii ja lulẹ le awọn eeyan lori.

Awọn nnkan bii bulọọku, kọnkere ati irin ti wọn fi gbe ṣọọṣi naa duro ja le awọn eeyan lori.

Ọkan lara awọn to wa ninu ṣọọṣi ọhun lasiko iṣẹlẹ naa, Josefina Ramírez sọ pe oun wa si ṣọọṣi naa lati ba ọmọ oun ninu Oluwa ṣajọyọ ibantisi rẹ, ko to di pe nnkan miiran ṣẹlẹ, to si dupẹ lọwọ Ọlọrun fun aabo ẹmi rẹ.

Ramírez ni "mo dupẹ lọwọ Ọlọrun wi pe mo wa laye. Ẹru ba mi wi pe mi o tun ni ri awọn mọlẹbi mi mọ. Mi o mọ pe a ṣi maa jade sita."

Bakan naa ni a tun gbọ pe lara awọn to wa ni abẹ ilẹ lakoko iṣẹlẹ naa lo fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si awọn eeyan fun iranlọwọ lati daabo bo oun.