Ilé ẹjọ́ US fún Chicago University lọ́jọ́ kan láti fún Atiku ní àwọn ìwé ẹ̀rí Tinubu

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/INSTAGRAM
Ilé ẹjọ́ kan ní Northern Illinois ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti pa á láṣẹ fún ilé ẹ̀kọ́ gíga Chicago State University (CSU) láti fún Alhaji Atiku Abubakar ní àwọn ohun ẹ̀kọ́ Ààrẹ Bola Tinubu.
Ìdájọ́ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí Adájọ́ Nancy Maldonado ti ilé ẹjọ́ US fìdí ìdájọ́ tí adájọ́ Jeffrey Gilbert ti ṣáájú gbé kalẹ̀ pé Atiku láṣẹ láti rí àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ pé akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà nígbà kan rí ni Tinubu.
Ṣaájú ni Tinubu ti pe ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tako ìdájọ́ tí Adájọ́ Jeffrey Gilbert dá pé kí ilé ẹ̀kọ́ CSU kó àwọn ẹ̀rí náà lé Atiku lọ́wọ́.
Tinubu ní kíkó àwọn ẹ̀rí yìí fún Atiku yóò ṣe àkóbá fún òun nítorí àwọn ohun ìní òun tó jẹ́ nǹkan tó pamọ́ sí òun ni wọ́n àti pé kò ní nǹkankan ṣe lórí ẹjọ́ tí Atiku ń pè tako ìjáwé olúborí òun níbi ètò ìdìbò ààrẹ Nàìjíríà tó kọjá.
Atiku, tí òun náà dupò ààrẹ Nàìjíríà pẹ̀lú Tinubu níbi ètò ìdìbò ààrẹ tó wáyé lọ́jọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Kejì ọdún 2023 lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, ń bèèrè fún àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ Tinubu láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ayédèrú èsì àbájáde ilé ẹ̀kọ́ ló fi kalẹ̀ lọ́dọ̀ àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò Nàìjíríà, INEC.
Ẹ̀wẹ̀, nígbà tó ń gbé ìdája rẹ̀ kalẹ̀ ní ọja Àbámẹ́ta, Adájọ́ Maldonado ní ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ náà gbé kalẹ̀ tọ̀nà àti pé àwọn náà faramọ.
Ó ní láàárín ọjọ́ Ajé ọjọ́ Kejì, oṣù Kẹwàá sí ọjọ́ Ìṣẹ́gun ọjọ́ Kẹta oṣù Kẹwàá ọdún 2023 ni ilé ẹ̀kọ́ náà gbọ́dọ̀ ti kó gbogbo àwọn nǹkan tí Atiku ń bèèrè fún lórí ìwé ẹ̀rí Tinubu le lọ́wọ́.
Adájọ́ náà ní nítorí ẹja tó wà ní ilé ẹjọ́ tó ga jìlọ ní Nàìjíríà lórí àbájáde èsì ìdìbò Tinubu àti pé ilé ẹ̀kọ́ gíga CSU ní àwọn ti ṣetán láti fi ẹlẹ́rìí kalẹ̀ nítorí náà ni àwọn ṣe ní kí ilé ẹ̀kọ́ tètè pèsè àwọn ohun tí wọ́n ń bèèrè.
Bákan náà ló ní àwọn kò ní fi ààyè gba Tinubu láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní agbègbè náà mọ́ bí ó ṣe jẹ́ pé Atiku kò ní àkókò tó pọ̀ mọ́ láti fi gbé ẹ̀rí rẹ̀ síwájú ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ Nàìjíríà ní ọjọ́ Karùn-ún oṣù Kẹwàá ọdún 2023.
Àmọ́ ó fi kun pé Tinubu le pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn níwájú ilé ẹjọ́ Seven Circuit tó ga ju tí àwọn ilé ẹja tó wà Ní Illinois àtàwọn ìpínlẹ̀ mìíràn náà ni agbègbè náà lọ.














