Ẹ jẹ́ kí oníkálùkù ṣe ẹ̀sìn rẹ̀ kí àlááfíà lè jọba láwùjọ wa - Ooni

Ooni ti Ile-Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi ti pe fun alaafia laarin awọn ẹlẹ́ṣin Mùsùlùmí, Kristẹni ati awọn alabalaye tí ṣe awọn oniṣẹṣe.
Igba ti Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi Ooni Ilé-Ifè to gba kiki awọn Òrìṣà kọ̀ọ̀kan ni akoko ti ọdun Ọlọjọ 2023 n lọ ĺọwọ ni ó pe fún alaafia laarin awọn ẹlẹ́sìn.
Bákan náà ni Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi Ooni Ilé-Ifè tún pe fún alaafia ni orile-ede Naijiria, ipínlẹ̀ ati ilu kọọkan.
Bẹẹ ni o rọ gbogbo awọn adarí orilẹ-ede Naijiria, ipínlẹ̀ ati awọn aṣiwaju ẹṣin kọọkan kí wọn kò pe fun àjọ alaafia kí orile-ede Naijiria ko le yí pada si rere.
Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi ṣe wure fun aarẹ orilẹ-ede Naijiria Bola Ahmed Tinubu fún àṣeyọrí ni gbogbo ọ̀nà.
O tun gba awọn ọdọ lọkunrin ati lobinrin ni ìmọ̀ràn pe ki wọn ko sọra lati fara wọn kalẹ fun wàhálà láwùjọ ki wọn múra gidigidi ṣiṣẹ ki awọn náà le de ibi gíga.
Wale Anta Hamaa ẹni to jẹ apa kan ọmọ orile-ede Naijiria lo tí wi pe o jẹ ìyàlẹ́nu ati ohun to ma dun oun bi ko ṣe si ibaṣepọ gidigidi láàárín awọn ọmọ Yorùbá.




Bákan náà ni Obalufe ti Ilé-Ife Ọba Idowu Adediwura sọ̀rọ̀ nípa ọdún Ọlọjọ pe o jẹ ọdún pàtàkì ni gbogbo agbaye o si jẹ ọdún Ògún.
Ọba Idowu Adediwura pe fun iṣọkan ọmọ Yorùbá ati pe ki a ma gbàgbé asa ati iṣe ilẹ̀ Yorùbá ka si maa wa alaafia gidigidi.
Oladotun Hassan ẹni to jẹ Ọba Aala Ọbatala oun naa tun rọ Aare Tinubu lati gba Àlàáfíà laye ni orilẹ-ede Naijiria.
Gbogbo ẹ̀yà lo peju pesẹ sì bí ayẹyẹ Ọdún Ọlọjọ ti Ọdún 2023.















