Ìgbìyànjú ìjọba láti yẹ ìyanṣẹ́lódì já sí pabo, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fárígá

Oríṣun àwòrán, NLC
Agbarijọpọ awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹ ede Naijiria iyẹn Nigeria Labour Congress ati Trade Unioin Congress ti kọ lati yọju sibi ipade kan ti ijọba apapọ pe.
Ago mẹta ọjọ Ẹti ni o yẹ ki ipade naa waye ni ile ijọba apapọ Aso Rock Villa pẹlu olori oṣiṣẹ ileeṣẹ aarẹ ni Abuja.
Iroyin to tẹwa lọwọ ni pe ijọba apapọ pe ipade pajawiri naa lati jiroro pẹlu awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ lọna ati yi ọkan wọn pada lori iyanṣẹlodi ti wọn fẹ gunle bẹrẹ lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹta oṣu Kẹwaa.
Lọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹsan-an ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ kede erongba lati gunle iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ lati fi ẹhonu han lori ọwọngogo nkan to waye lẹyin ti ijọba Naijiria yọ ẹkunwo lori bẹntiroo.
Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ si sọ fawọn ẹka wọn pata pe ki wọn gbaradi lati yan iṣẹlodi ni gbogbo awọn aaye to ṣe pataki ṣe koko bi awọn papakọ ofurufu,ibudọ ọkọ oju omi, ileeṣẹ mọnamọmọna ati awọn ibudo to n pese epo bẹntiroo.
''Patapata la fẹ doju iṣẹ bole...titi ti ijọba yoo fi wa nkan se si ibeere oṣiṣẹ ati araalu.''
Bẹẹ lawọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ ti ṣe sọ ninu atẹjade ti wọn fi sita lọjọ Iṣẹgun.
Wọn fẹsun kan ijọba apapọ pe wọn kọ lati wa ojutu ki wọn si fẹnuko pẹlu ẹgbẹ oṣiṣẹ lori ọna abayọ si inira ti yiyọ ẹkunwo epo bẹntiroo mu ba araalu.
Tohun ti awọn ijiroro to ti fori sanpọn tẹlẹ, ileeṣẹ iroyin Naijiria Punch jabọ pe ijọba apapọ lẹyin ipade igbimọ ọrọ aje Naijiria parọwa si awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ lati tẹsiwaju ijiroro.
Wọn ni titẹsiwaju pẹlu iyanṣẹlodi yoo ṣe akoba nla fun ọrọ aje Naijiria lasiko yi.
Ijọba pe ipade yi si ago mejila ọsan amọ wọn pada sunsiwaju ki awọn oṣiṣẹ baa le kan si awọn olori wọn mii ti ko si ni Abuja.
Punch tẹsiwaju pe lowurọ ọjọ Ẹti ni ijọba fi iwe ipe ranṣẹ lori ipade yi lati ọwọ minisita fọrọ iṣẹ ati oṣiṣẹ ranṣẹ sawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ.
Titi ti ago m mẹrin fi lu lỌjọ Ẹti awọn aṣoju ẹgbẹ oṣiṣẹ ko yọju sibi ipade toun ti pe awọn eekan lọdọ ijọba bi Minisita Simon Lalong ati olori oṣiṣẹ ileeṣẹ aarẹ Femi Gbajabiamila ti wa nikalẹ ti wọn n duro de awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ.
Se iyanṣẹlodi yi le so eso rere?
Ibeere nla ree ti araalu maa n beere lọpọ igba ti awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ba fi ikede sita pe awọn yoo gunle iyanṣẹlodi.
Lẹnu igba ti ijọba Aarẹ Tinubu de ori aleefa yi, o kere tan awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ti n dunkoko lori ọrọ iyanṣẹlodi yi to fẹẹ to ẹmẹẹta.
Ni igba ti wọn ṣe iyanṣẹlodi ikilọ ọlọjọmeji kọja, pupọ araalu ni ko fitaratara gbagbọ pe nkankan yoo tẹyin rẹ bọ.
Botilẹ jẹ wi pe awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ sọ pe patapata lawọn fẹ taa tan pẹlu ijọba pẹlu iyanṣẹlodi yi, o ku ki araalu ri apẹrẹ pe wọn ko mu ọrọ naa ni kekere.
Nibi ti ọrọ de duro yi, ijọba ipinlẹ ti gbe awọn igbesẹ kan ti wọn lawọn lero pe yoo mu ki aye dẹrun lẹyin ti wọn yọ ẹkunwo epo bẹntiroo.
Ninu rẹ ni pinpin owo palliatifu biliọn marun fawọn ijọba ipinlẹ ati kiko nkan ounjẹ ranṣẹ sawọn araalu.
Pẹlu gbogbo awọn igbiyanju yi, eyi ti o daju taa ri taraalu si n ran lẹnu ni pe ọwọngogo nkan to gbode yi ko jẹ ki eyikeyi iranwọ ti ijọba ṣe mu iyatọ kankan ba isẹmi araalu.
Ati olowo ati talaka lo n ke irora nitori bi owo nkan ṣe n lọ soke ti owo taraalu si n ri ko tolati fi ka bukata.
Titi di ba ṣe n sọrọ yi, ijọba apapọ ko ti mu ileri alekun owo oṣu to kere julọ ti wọn lawọn yoo ṣe di imuṣẹ.
O ku ki a ri iru ipa ti iyanṣẹlodi NLC ati TUC yi yoo mu ni nipa mimu idẹkun ba araalu.












