ILO kọminú lórí ọjọ́ iwájú bí àlékún ṣe bá iye ọmọdé tó ń ṣọfà

Muhammad ń ta tíṣú pepà nínú súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ ní Lebanon
Àkọlé àwòrán, UN ní ọ̀pọ̀ ìdílé ló máa ń fi ọmọ wọn ṣọfà ní Lebanon
    • Author, Alice Cuddy
    • Role, BBC News

Ọjọ́ iwájú àwọn ọmọdé ló wà nínú ewu bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ṣe ń fi ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀ láti lọ máa ṣiṣẹ́.

Èyí ni ìwòye àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ ni àgbáyé lórí bí àwọn ọmọdé tó yẹ kó wà lẹ́nu ẹ̀kọ́ ṣe di ẹni tó ń ṣiṣẹ́ láti wá oúnjẹ oòjọ́.

Gilbert Hungbo, adarí àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ ní àgbáyé ìyẹn International Labour Organization (ILO), ní káàkiri àgbáyé ni ọ̀rọ̀ náà kàn pẹ̀lú bí iná ètò ọrọ̀ ajé ṣe ń jó àjórẹ̀yìn.

Lára àwọn iṣẹ́ tó burú jáì tí àwọn ọmọdé náà ń ṣe ni òwò nòbí.

Ó ní ọ̀rọ̀ náà ń fẹ́ àmójútó ní kíákíá.

"Ìpalára tí Covid 19 mú wá àti ọ̀wọ́ngógó gbogbo nǹkan tó ti ẹ̀yìn rẹ̀ jáde ti mú kí nǹkan dàrú síi àti pé àmójútó gbọ́dọ̀ wáyé ní kíákíá bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nǹkan tún máa bàjẹ́ síi ni."

Àkójọpọ̀ àbọ̀ ìwádìí tí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN ṣe ní ọdún 2020 ṣàfihàn pé kò dín ní ọgọ́jọ mílíọ̀nù àwọn ọmọdé ni wọ́n fi ń ṣọfà.

Hungbo ní gbogbo ìgbìyànjú àwọn orílẹ̀ àgbáyé láti mú àdínkù bá ìṣòro náà ni ìdádúrò ti bá fún ìgbà àkọ́kọ́ láti bí ogún ọdún tí ètò náà tí bẹ̀rẹ̀.

Olóòtú ìjọba tẹ́lẹ̀ rí ní Togo ní ìwádìí fi hàn pé ìṣòro náà ṣì ń tẹ̀síwájú.

Ó fi kún un pé ọ̀wọ́ngógó ṣe ti bá oúnjẹ àti ohun àmúṣagbára nítorí ogun tó ń wáyé ní Ukraine ti mú kí ọ̀pọ̀ ẹbí máa jẹun ní ẹ̀ẹ̀kan lójúmọ́.

Èyí ló mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ẹbí máa ti àwọn ọmọ wọn tí kò ì tíì tó ṣiṣẹ́ láti lọ máa ṣiṣẹ́ ìdọ̀tí bíi ṣíṣe aṣẹ́wó láti fi ran ìdílé wọn lọ́wọ́.

Ọmọdé tó ń ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó ní Kenya
Àkọlé àwòrán, Àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ ní àgbáyé ní àmójútó gbọ́dọ̀ wáyé ní kíákíá láti yọ àwọn ọmọdé lọ́wọ́ iṣẹ́ tí kò tọ́.
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní ìlú Mombasa ni ẹkùn Gúúsù ìlà oòrùn Kenya, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan sọ fún BBC pé ó pọn dandan fún òun láti lọ wá iṣẹ́ ṣe nítorí ìyá òun ń tiraka láti wá oúnjẹ àti owó ilé ẹ̀kọ́ fún òun àti àbúrò òun méjì mìíràn.

Ó ní ó máa ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin, fọ aṣọ tà àti bá àwọn ènìyàn dirun kí òun le rí owó jẹun.

Ó ṣàlàyé pé nígbà tí òun fi ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ebi máa ń pa òun débi wípé òun kò ní lè rí ọwọ́ kọ iṣẹ́.

Nígbà tí ìyá rẹ̀ náà ń sọ̀rọ̀, ó ní kìí ṣe ohun tó rọrùn láti sọ fún ọmọdé láti ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀.

Àmọ́ ó ní kò rọrùn fún òun nìkan láti ran ẹbí òun lọ́wọ́ pẹ̀lú àgbàfọ̀ aṣọ tí òun ń ṣe lẹ́yìn tí òun ti pàdánù iṣẹ́ tí òun ń ṣe lásìkò tí covid 19 ń bá gbogbo ayé fínra.

"Ó jẹ́ ohun tó máa ń bà mí lọ́kàn jẹ́. Ó wù mí kí ọmọ mi náà lọ sí ilé ẹ̀kọ́ bí àwọn ọmọ yòókù, kí ó lè rí iṣẹ́ gidi lọ́jọ́ iwájú ṣùgbọ́n kò sí agbára fún mi nítorí náà ló ṣe ń ṣiṣẹ́ yìí."

Obìnrin kan tó ní ilé ìtura ní ìlú náà ní ọjà òun ń tà dáadáa nítorí àwọn ọmọbìnrin tó ń wá owó ń pọ̀ si ní ojoojúmọ̀.

Houngbo ní fífi àwọn ọmọdé ṣiṣẹ́ ló wọ́pọ̀ ní àwọn orílẹ̀ èdè tí ọrọ̀ ajé wọn kò gbòòrò tó.

"Àsìkò tó lágbára ni a wà yìí àti pé ìṣẹ́ ni okùnfà ọ̀rọ̀ yìí", ó sọ.

Àwọn ọmọdé ni Lebanon
Àkọlé àwòrán, Ní Lebanon, àwọn ọmọdé ń pa ẹ̀kọ́ tì láti lọ máa ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè ran ìdílé wọn lọ́wọ́

Ohun tó ṣokùnfà ìṣòro yìí yàtọ̀ ní orílẹ̀ èdè kan sí òmíràn ṣùgbọ́n ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọdé ní àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé (UNICEF) ní ọ̀wọ́n gógó gbogbo nǹkan jẹ́ ohun tí gbogbo orílẹ̀ èdè ń kojú tó sì ń ní ipa lára àwọn ọmọdé ní ọ̀nà oríṣiríṣi.

Adarí ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwùjọ ní UNICEF, Natalia Winder-Rossi ní ọ̀pọ̀ àwọn ìdílé ló ń ṣe àwọn nnkan tí kò bójúmu nítorí ọ̀nà àtijẹ tó sì ń ṣe àkóbá fún àwọn ọmọdé lásìkò yìí àti lọ́jọ́ iwájú

BBC ṣe àbẹ̀wò sí àwọn orílẹ̀ èdè káàkiri láti mọ bí àìrajaja ètò ọrọ̀ ajé ṣe ń nípa lórí àwọn ọmọdé.

Ní ìlú Sidon ní orílẹ̀ èdè Lebanon, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé ló ní àwọn pa ilé ẹ̀kọ́ tì láti rán ìdílé wọn lọ́wọ́.

"Nígbà tí mo ṣì ń lọ sílé ẹ̀kọ́, iṣẹ́ olùkọ́ ni mo máa ń rò pé máa ṣe tí mo bá dàgbà ṣùgbọ́n mi ò lọ sílé ẹ̀kọ́ mọ́ báyìí," Alaa tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tó ń bá àwọn ènìyàn tún ilé sọ fún BBC.

UNICEF ní ọ̀pọ̀ ìdílé ní Lebanon ló máa ń fi ọmọ wọn ṣọfà bí ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè náà ṣe tí fẹ́ dẹnu kọlẹ̀ pátápátá báyìí.

Muhammad, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún tó ń ta tíṣú pepà nínú súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ ní ó wu òun láti lọ sílé ẹ̀kọ́ àmọ́ kò sí bí òun ṣe fẹ́ ronú nípa rẹ̀ nínú ipò tí àwọn wà.

Houngbo ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro náà lágbára púpọ̀, òun gbà pé ó ṣe é mójútó.

Ó ní òun gbàgbọ́ pé tí àwọn ìjọba gbé ètò dojú kọ ètò ẹ̀kọ́, pípèsè iṣẹ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ kalẹ̀, ìyàtọ̀ máa bá ìṣòro náà jọjọ.

Ó fi kun pé àwọn ìjọba nílò láti dìde láti jí gìrì sí ìṣòro náà.

Additional reporting by Barbara Plett-Usher and Caroline Hawley