Láéláé, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ kò ní yanṣẹ́ lódì, ìkéde ayọ̀ ń bọ̀ lọ́jọ́ òmìnira - Tinubu

Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Ijọba apapọ ti sọ pe ko ni si iyanṣẹlodi kankan ti yoo waye ni Naijiria bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣiṣe ti sọ pe iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ n bọ laipẹ.

Ṣaaju ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ NLC ati TUC ti kọkọ fẹnuko pe awọn yoo yan iṣelodi lẹyin ti ijọba kuna lati ṣe awọn ohun ti wọn n bere fun.

Wayi o, ijọba apapọ ti sọ pe Aarẹ Tinubu yoo ṣe eto amayedẹrun kan fun awọn oṣiṣẹ, eyii ti yoo kede rẹ ninu ọrọ rẹ si awọn araalu ni ayajọ ọjọ ominira Naijiria.

Agbẹnusọ ileeṣe ijọba apapọ to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ, Olajide Oshundun sọ pe ipade awọn ti awọn yoo ṣe lọjọ Iṣẹgun yoo da lori awọn ohun ti Tinubu yoo sọ ni ajọdun ominira, eyii ti yoo waye lọjọ kinni, oṣu Kẹwaa.

O ni “A ko ni jẹ ki iyanṣelodi naa waye.”

“A gbọ nipa erongba wọn lati da iṣẹ silẹ, wọn ni lati fi ọkan bale pe ikede kan n bọ lọjọ ajọdun ominira lati ọdọ Aarẹ si awọn oṣiṣẹ.”

“Ileeṣẹ wa n ṣiṣẹ takuntakun lati ṣe ohun keji ti wọn n bere fun.

“A ti gba itusilẹ alaga igun keji ẹgbẹ awọn awakọ, NURTW.

“Nitori naa a ni ireti pe a o le fi iwe pe wọn lọjọ Abamẹta lẹyin ikede Aarẹ lati ba wọn dunadura lori bi wọn ṣe yoo ṣe wọgile iyanṣẹlodi ti wọn n mura rẹ.”

Ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 1960 ni Naijiria gba ominira lọwọ ijọba amunisin ilẹ Gẹẹsi.

Ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 yii ni yoo pe ọdun mẹtalelọgọta ti Naijiria gba ominira.

Àkọlé fídíò, Aisha Shoneye: Tobi Amusan ni àwòkọ́ṣe mi, mo sì fẹ́ ga jù ú lọ

Egbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC, TUC kéde ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ, wo ọjọ́ tí yóò bẹ̀rẹ̀

Aworan iwọde ẹgbẹ oṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agbarijọpọ ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria Nigeria Labour Congress, NLC ati Trade Union Congress, TUC ti panupọ kede pe awọn yoo gunle iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ ni Naijiria.

Ikede yi waye lẹyin ipade ti wọn ṣe lọjọ Iṣẹgun ti wọn si fẹnuko pe bẹrẹ lati ọjọ Iṣẹgun ọjọ Kẹta oṣu Kẹwaa 2023 awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi naa.

Ṣaaju ni wọn ti fun ijọba ni gbendeke ọjọ mejila ati iyanṣẹlodi ikilọ ọlọjọ meji lati fi jẹ ki ijọba wa nkan ṣe si inira to deba araalu lẹyin ti ijọba yọ ẹkunwo epo bẹntiroo.

Aarẹ NLC ati ti TUC Comrade Joe Ajaero ati Comrade Festus Osifo lo jijọ buwọlu atẹjade to tẹyin ipade yi waye.

Wn ni ni ibamu pẹlu ayajọ ominira Naijiria awọn naa ṣetan lati ri pe ominira to peye fawọn araalu nipa gbigba arawọn silẹ ati mimu ayanmọ arawọn ṣe fun ara wọn.

Ni bayii ẹgbẹ oṣiṣẹ lawọn tikesi gbogbo awọn ẹka ẹgba naa lati bẹrẹ ipalẹmọ lati yan iṣẹlodi ki wọn si gba igboro kan pẹlu iwọde titi ti ijọba yoo fi tẹti si awọn ẹdun ọkan tawọn fi ṣọwọ.

Ijọba ko ṣetan lati mu irọrun ba araalu pẹlu inira to wa nita

Asia ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria NLC

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu ọrọ ti NLC ati TLC sọ ninu atẹjade ti wọn fi sita, wọn ni koko pataki ni pe ati awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ati ijọba ariyanjiyan ko si lori pe yiyọ ẹkunwo epo bẹntiroo mu ki ara maa ni araalu pupọ.

Amọ wọn ni ijọba kọ lati gbe igbesẹ gẹgẹ bi ojuṣe rẹ eyi to le mu inira, ebi ati oṣi to kari yi dinku lawujọ.

''Ijọba apapọ kan da ọgbọn lorisiriṣi lati fọrọ jomi toro ọrọ pẹlu ẹgbẹ oṣiṣẹ ni lati le mu idẹrun ba araalu nitori owo iranwọ ori opo ti wọn yọ.''

Awọn ẹgbẹ naa tẹsiwaju pe, ijọba ko fi ọna kankan to bojumu wa nkan ṣe si awọn ẹdun ọkan ẹgbẹ oṣiṣẹ ati araalu gẹgẹ bi o ṣe wa ninu ilana ajumọfẹnuko si ti yoo mu ki ara dẹ araalu.

Nitori naa, awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ ti wa sọ pe gbogbo ọna ni ijọba n gba lati sọ ẹgbẹ oṣiṣẹ lẹnu paapa loju opo ayelujara ti wọn si n lo agbara wọn lati fun awọn lọrun dipo ki wọn fi agbara ọhun mu aye dẹrun faraalu.

Se iyanṣẹlodi yi le so eso rere?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ibeere nla ree ti araalu maa n beere lọpọ igba ti awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ba fi ikede sita pe awọn yoo gunle iyanṣẹlodi.

Lẹnu igba ti ijọba Aarẹ Tinubu de ori aleefa yi, o kere tan awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ti n dunkoko lori ọrọ iyanṣẹlodi yi to fẹẹ to ẹmẹẹta.

Ni igba ti wọn ṣe iyanṣẹlodi ikilọ ọlọjọmeji kọja, pupọ araalu ni ko fitaratara gbagbọ pe nkankan yoo tẹyin rẹ bọ.

Botilẹ jẹ wi pe awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ sọ pe patapata lawọn fẹ taa tan pẹlu ijọba pẹlu iyanṣẹlodi yi, o ku ki araalu ri apẹrẹ pe wọn ko mu ọrọ naa ni kekere.

Nibi ti ọrọ de duro yi, ijọba ipinlẹ ti gbe awọn igbesẹ kan ti wọn lawọn lero pe yoo mu ki aye dẹrun lẹyin ti wọn yọ ẹkunwo epo bẹntiroo.

Ninu rẹ ni pinpin owo palliatifu biliọn marun fawọn ijọba ipinlẹ ati kiko nkan ounjẹ ranṣẹ sawọn araalu.

Pẹlu gbogbo awọn igbiyanju yi, eyi ti o daju taa ri taraalu si n ran lẹnu ni pe ọwọngogo nkan to gbode yi ko jẹ ki eyikeyi iranwọ ti ijọba ṣe mu iyatọ kankan ba isẹmi araalu.

Ati olowo ati talaka lo n ke irora nitori bi owo nkan ṣe n lọ soke ti owo taraalu si n ri ko tolati fi ka bukata.

Titi di ba ṣe n sọrọ yi, ijọba apapọ ko ti mu ileri alekun owo oṣu to kere julọ ti wọn lawọn yoo ṣe di imuṣẹ.

O ku ki a ri iru ipa ti iyanṣẹlodi NLC ati TUC yi yoo mu ni nipa mimu idẹkun ba araalu.