Dókítà Nàìjíríà yarí pé ohun tó wù UK, kó sọ, àwọn kò ní ṣàì jápa

Oríṣun àwòrán, United states african command
Ẹgbẹ awọn dokita isegun oyinbo lorilẹede Naijiria ti sọ pe ofin ti ijọba ilẹ Gẹẹsi gbe kale lati maṣe gba awọn oṣiṣẹ eto ilera lati Naijiria at’awọn orilẹede kan lagbaye sisẹ mọ ko lee di awọn dokita Naijiria lọna ati wa ẹkọ tutu roke okun o.
Ẹgbẹ awọn dokita iṣegun oyinbo naa sọ pe bi o tilẹ jẹ pe ilẹ Gẹẹsi le sọ le ṣofin lori ohun to fẹ sibẹ, ẹtọ omoniyan ti ko lẹja n bakan ninu ni ẹtọ lati rin si ibi to ba wu ni.
Ni ọjọ diẹ sẹyin lawọn alaṣẹ ilẹ Gẹẹsi gbe ofin kan jade, eyi to sọ pe awon ileesẹ agbanisiṣẹ lorilẹede naa ko gbọdọ gba awọn dokita at’awọn oṣiṣẹ ilera lati orilẹede Naijiria at’awọn orilẹede mẹtalelaadọta miran laaye lati ṣiṣẹ nibẹ.
O ni awọn orilẹede mẹrinlelaadọta naa lawọn orilẹede ti ajọ ilera agbaye WHO tọkasi pe awọn ipenija oṣiṣẹ lẹka eto ilera wọn ti n jẹyọ julọ ninu atẹjade rẹ kan lọjọ kẹjọ oṣu kẹta ọdun 2023.
Ilẹ Gẹẹsi woye pe gbigba awọn oṣiṣẹ eto ilera latawon orilẹede tọrọ kan naa ṣiṣẹ lee tubo pa kun ipenija aito awọn oṣiṣẹ eto ilera lorilẹede Naijiria at’awọn orilẹede yooku ti wọn darukọ ọhun.
Awọn orilẹede wo lọrọ kan?

Oríṣun àwòrán, other
Awọn orilẹede ti aṣẹ tuntun ti ilẹ Gẹẹsi ṣẹṣẹ pa yii yoo bawi ni: Afghanistan, Angola, Bangladesh, Benin, Burkina Faso, Burundi, Cameroon, Central African Republic, Chad, Comoros, Congo, DR Congo, Côte d’Ivoire, Djibouti, Equatorial Guinea, Eritrea, Ethiopia, Gabon, Gambia, Ghana, Guinea, Guinea-Bissau, Haiti, Kiribati, Lao People’s Democratic Republic, Lesotho, Liberia.
Bakan naa ni yoo tun kan awọn orilẹede bii Madagascar, Malawi, Mali, Mauritania, Micronesia, Mozambique, Niger, Nigeria, Pakistan, Papua New Guinea, Rwanda, Samoa, Senegal, Sierra Leone, Solomon Islands, Somalia, South Sudan, Sudan, Tanzania, Timor-Leste, Togo, Tuvalu, Uganda, Vanuatu, Yemen, Zambia, ati Zimbabwe.
Awọn oṣiṣẹ ilera ti ọrọ kan

Oríṣun àwòrán, other
Lara awon oṣiṣẹ ilera ti ọrọ naa kan ni ọn osisẹ itọju alaaisan, awọn dokita eyin, awọn dokita iṣegun oyinbo, awọn nọọsi, awọn oṣiṣẹ ile iwosan gbogbo, awọn agbẹbi, awọn onimọ sayẹnsi nipa eto ilera ati bẹẹbẹ lọ.
Igba akọkọ kọ niyi ti Ilẹ Gẹẹsi yoo gbe iru igbesẹ yii
Ni ọdun 2021, awọn alaṣẹ orilẹede UK ti kọkọ paṣẹ pe awọn agbanisiṣẹ ko gbọdọ gba oṣiṣẹ ilera kankan lati orilẹede Naijiria at’awọn orilẹede mẹrindinlaadọta kan kaakiri agbaye siṣẹ lorilẹede ọhun.
Ohun ti wọn sọnigba naa ni pe bi ọgọrọ awọn oṣiṣẹ eto ilera ṣe n dagiri kuro lawọn orilẹede to ku diẹ kaato fun wa si orilẹede Gẹẹsi n tigi boju afojusun ero ilera awọn.
Ko din ni ẹgbẹrun mọkanla awọn dokita iṣegun oyinbo to kẹkọọ gboye ni Naijiria ṣugbọn to n ṣiṣẹ lorilẹede UK bayii gẹgẹ bí abajade iwadii ti igbimọ alamojuto eto isegun nilẹ Gẹẹsi fi sita.
Awọn dokita iṣegun oyinbo lati Naijiria ni dokita ilẹ ajeji to pọ julọ lorilẹede UK, India ati Pakistan lo si tun tẹ lé wọn.
















