Ọkùnrin tó sùn tí obìrin tó kú sílé ìtùra ní Ibadan, fa ara rẹ̀ lé ọlọ́pàá lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM
Afurasí kan gbòógì tó wà lórí ikú arábìnrin Adeshina Olayinka, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Khadi, tó ń ta aṣọ lórí Instagram ti wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá.
Ní ilé ìtura kan ni Khadi dákẹ́ sí ní ọjọ́bọ̀ tó kọjá ní ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo lẹ́yìn tí ọ̀rẹ́kùnrin tí òun àti ẹ̀ jọ wà nílé ìtura náà ti ṣáájú kúrò.
Ìròyìn ní afurasí náà ti wà ní àhámọ́ ikọ̀ ọlọ́pàá tó ń ṣe ìwádìí ìwà ọ̀daràn ní àgọ́ ọlọ́pàá Iyaganku, Ibadan.
Afurasí náà, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ló lọ fa ara rẹ̀ lé ọlọ́pàá Akobo lọ́wọ́ nígbà tó gbọ́ wí pé wọ́n ń wá òun lórí ikú Olayinka.
Oníbàárà wa ni afurasí, nígbà tí a pè é pé Olayinka kú ló yọjú sí wa tó sì lọ fa ara rẹ̀ lé ọlọ́pàá lọ́wọ́ - òṣìṣẹ́ ilé ìtura
Òṣìṣẹ́ ilé ìtura tí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ti wáyé kan tí kò fẹ́ kí àwọn akọ̀ròyìn dárúkọ òun ní nǹkan bíi aago méjìlá ọ̀sán, tí asiko tó yẹ kí Olayinka jáde kúrò nílé ìtura náà ni àwọn tó mọ nǹkan tó ṣẹlẹ̀.
Ó ní nígbà tí àwọn dé yàrá tí Olayinka wà, ó ṣì ń mí, tí àwọn sì sáré pe àgọ́ ọlọ́pàá Akobo láti fi ọ̀rọ̀ náà tó wọn létí.
"Ó ṣeni láàánú pé Olayinka jẹ́ ìpè Ọlọ́run kó tó dé ilé ìwòsàn."
"Nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, a pe afurasí náà láti ṣàlàyé ohun tó wáyé fún un, ó sì lọ fa ara rẹ̀ lé ọlọ́pàá lọ́wọ́."
"Ọ̀kan nínú àwọn oníbàárà wa níbí ni, wọ́n ti fi sí àhámọ́, ẹjọ́ náà sì ti wà ní ẹ̀ka tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn."
Nígbà tí àwọn akọ̀ròyìn kàn sí agbẹnusọ ọlọ́pàá Oyo, Adewale Osifeso, ó ní ìwádìí tí ń lọ lọ́wọ́ àti pé àwọn máa tó fi ohùn léde láìpẹ́.
Ṣáájú ni àwọn aláṣẹ ilé ìtura tí ọmọbìnrin náà kú sí ní àwọn yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá láti mọ ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀.
Ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí ikú Khadi, gbajúmọ̀ oníṣòwò ayélujára tó kú nílé ìtura n‘Ibadan

Oríṣun àwòrán, Others
Arabinrin Olayinka Adesina, to jẹ ilumọọka alaṣọ lori ayelujarna ti wọn tun mọ si Khadi, ni wọn ba oku rẹ ninu ile itura kan ni agbegbe Akobo, ni ilu Ibadan, nipinlẹ Oyo.
Olayinka, ti o gbajugbaja fun awọn aṣọ alaranbara to ma n ran ati baagi to ma n ta lori ẹrọ ayelujara, ni wọn ni o sọ fun ọrẹ rẹ kan pe oun fẹ lọ pade ẹnikan ni ile itura kan ni alẹ Ọjọru.
Ọkunrin naa lo ji kuro ni ile itura naa ni ọjọ keji amọ ti wọn si pe yara ti Khadi wa, to si sọ fun oṣiṣẹ ile itura naa pe alaafia ni oun wa, ki wọn to gba ki ọkunrin naa maa lọ.
Amọ, oku Khadi ni wọn ba lẹyin ọpọ wakati to ti yẹ ko jade, ti wọn ko si gburo rẹ tabi ko gbe ipe rẹ.

Oríṣun àwòrán, Others
Iwadii n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa – Ileeṣẹ ọlọpaa Ọyọ
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo ti wa sọrọ lori iku gbajumọ onisowo ayelujara naa, to si ti fi ọrọ lede lori iṣẹlẹ iku Khadi, to ku sile itura kan ni ilu Ibadan.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Adewale Osifeso ni lootọ ni iṣẹlẹ naa waye ni Ọjọ Karun si Ọjọ Kẹfa, Oṣu Kẹrin, ọdun 2023.
O ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ iku arabinrin naa.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa naa fi da awọn araalu loju pe awọn yoo jẹ ki awọn eniyan mọ bi iwadii naa ba ṣe n tẹsiwaju.
Ẹbi, ara ati awọn ọrẹ rẹ lo n ṣe idaro rẹ lori ẹrọ ayelujara, ti awọn kan si n ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi ọmọ daradara.
Amọ awọn miran bu ẹnu atẹ lu oloogbe naa pe o lọ si ile itura pẹlu ọkunrin, to si jẹ oninabi.
Koda, ọpọ eeyan lo n woye pe o seese ko jẹ pe ọkunrin ti Khadi lọ pade nile itura fi se etutu ọla ni.
A o ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa lori iwadii iku Khadi – Ile itura Wetland

Oríṣun àwòrán, Others
Alasẹ ile itura ti wọn ti ri oku Khadi ti fi da awọn onibara loju pe awọn yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa lori iwadii iku obinrin naa, ti o waye nile itura wọn.
Ile itura Wetland ni awọn yoo ri daju pe otitọ jọba lori iṣẹlẹ naa.
Bakan naa ni wọn fi ikẹdun ranṣẹ si ẹbi ati ara ẹni to doloogbe naa.
Wọn tun fi da awọn onibara wọn loju pe aabo wọn ati ilera wọn jẹ ile itura naa logun, ti wọn si fi da awọn araalu loju pe ko ni si ewu.
















