Ìjọba gbégi dínà 'Loan App' láti máa le ni ànfàní sórí fóònù oníbàárà wọn

aworan

Oríṣun àwòrán, GETTY IMAGES/ICIR

Ijọba apapọ ti kede pe awọn ti gbegi dina awọn ileeṣẹ ayanilowo lori ayelujara 'PlayStore' lati maa le ni anfani si fọto ati oruko awọn to wa lori foonu awọn onibaara wọn.

Ofin yii yoo bẹrẹ lati ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun, ọdun 2023.

Gẹgẹ bi ajọ FCCP se sọ saaju, Ijọba apapọ ti fi ofin de ileeṣẹ ayanilowo toto aadọjọ niye.

Bakan naa, ajọ naa ni aipẹ ni ijọba buwọlu iforokọsilẹ awọn ileeṣẹ ayanilowo miiran to le ni adọjọ niye ti awọn eeyan le lo lati yawo.

Kilode ti ijọba fi gbe igbesẹ naa

Ijọba apapọ ni awọn gbe igbesẹ yii nitori ilana tuntun ti ileeṣẹ Google gbe kalẹ lori awọn appu ayanilowo lori ayelujara.

Wọn ni o se koko lati tẹle ilana naa ti gbe kalẹ, eyi ti yoo dina bi awọn ileeṣẹ wọnyi se ma ni anfani si foonu onibara wọn.

Ijọba ni idi kan pataki ti fọwọ sofin ni pe ko ba ofin bi awọn ileeṣẹ se tọjubọ foonu awọn onibara

Oga agba fun ajọ FCCPC, Babatunde Irukera igbesẹ jẹ ohun to dara pupọ

Ajọ ni awọn yoo maa se amojuto awọn ileeṣẹ ayanilowo ii ijọba sẹsẹ buwọlu lorekore.