Rukayat Shittu: Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ló jẹ́ kí ń borí, mo ti ṣe omi, àtúnṣe ọ̀nà sẹ́kún ìdìbò mi

Àkọlé fídíò, Rukayat Shittu: Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ló jẹ́ kí ń borí, mo ti ṣe omi, àtúnṣe ọ̀nà sẹ́kún ìdìbò mi

Saaju eto idibo sile asofin ipinlẹ to kọja, ni BBC Yoruba ti seto ifọrọwanilẹnuwo fun omidan kan, Rukayat Motunrayo Shittu.

Rukayat lo n dije sipo asofin ipinlẹ Kwara lati soju ẹkun idibo Owode Onire nijọba ibilẹ Asa nipinlẹ naa llabẹ ẹgbẹ oselu APC.

Rukayat di dibo, o si ti jawe olubori lati lọ soju ẹkun idibo naa sile asofin ipinlẹ Kwara, eyi si lo mu ki BBC Yoruba tun fọrọ werọ pẹlu rẹ lẹyin idibo lati mọ ohun to n la kọja.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Rukayat ni ọmọja oun ti kuro niye ti ana nitori pe oun ti kuro ni Rukayat ti wọn mọ ni ẹsẹkuku mọ.

O salaye pe oun kii se Rukayat ti wọn mọ tẹlẹ mọ, bẹẹ ni oun ko si mọ fun ẹkun idibo Owode Onire nikan, oun ti di ti gbogbo agbaye.

O ni ati awọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC ti oun ti jade ni, atawọn alatako, gbogbo wọn ni oun wa fun.

Bakan naa lo sisọ loju rẹ pe ẹni to jẹ bi baba fun oun, to wa latinu ẹgbẹ oselu miran, ti awọn dijọ dije ibo lẹkun idibo naa, ti gbe oun lọ sile ẹjọ.

"Hon Usman Alajere ro pe awọn ni awọn wọle ibo naa, wọn si gbe mi lọ sile ẹjọ.

Amọ eyi ko ko irẹwẹsi ọkan ba mi nitori pe baba ni wọn jẹ si mi, ilu ni mo si fẹ sin.

Sugbọn ibi to ba ja si, ajẹ pe bi Ọlọrun se fẹ niyẹn."

Bakan naa ni Rukayat Shittu sisọ loju rẹ pe oun ti lọ ki ọba ilu Ilorin, ti inu rẹ si dun si oun.

Nigba to n woye idi to se bori ibo sile asofin naa, obinrin naa ni iwa irẹlẹ lo mu ki oun bori ọhun, bẹẹ ni oun ko ni yipada kuro ni oniwa irẹlẹ ti wọn mọ tẹlẹ.

O wa salaye pe saaju idibo ni oun ti pese omi fawọn eeyan lẹkun idibo oun, ti oun si tun se atunse oju ọna fun wọn.

O wa fọwọ sọya pe oun ko ni dawọ duro nidi sise eleyii, ti oun yoo si kan sawọ ẹlẹgbẹjẹgbẹ lawujọ agbaye lati wa se ohun rere si ẹkun idibo oun.