Goroso Ekiti: N kò kábàámọ̀ pé mo gbọ́ Ekiti, òhun ló gbé mi dé ọ̀dọ̀ gómìnà

Àkọlé fídíò, Goroso Ekiti: N kò kábàámọ̀ pé mo gbọ́ Ekiti, òhun ló gbé mi dé ọ̀dọ̀ gómìnà

Yoruba ni ọmọ ale lo maa n fi ọwọ osi juwe ile baba rẹ, bẹẹ si ni ọmọ to ba sọ ile nu, o so apo iya kọ.

Idi si ree to fi yẹ ki obi kọọkan ri gẹgẹ bi ojuse oun lati maa kọ awọn ọmọ rẹ ni asa ati ede abinibi wa nitori ọpọ anfaani to wa ninu iru igbesẹ yii.

Lara awọn anfaani to wa ninu sisọ ede abinibi yii si lo sọ ọdọmọkunrin kan, Owolabi Olamilekan, ti ọpọ eeyan mọ si Goroso Ekiti di ilumọọka adẹrinposonu lori ayelujara.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Goroso Ekiti gbe osuba fun awọn obi rẹ to kọ ni ede Ekiti, tii se ede abinibi rẹ.

"Bi awọn obi mi ko ba jẹ ki n gbọ ede naa, mo le ma di ilumọọka, ti mo da lonii"

O ni to ba jẹ pe oun ko mọ ede Ekiti sọ ni, o seese ki oun ma di gbajumọ alawada ti oun da lonii.

"Ọmọ bibi ilu Ikere-Ekiti ni mi, Ekiti ni mo ti lọ si ileẹkọ alakọbẹrẹ, girama ati ile ẹkọ giga fasiti.

Koda, Ekiti gan ni mo ti sinru ilu NYSC, ti mo si gbọ ede naa bo se yẹ.

Amọ bi awọn obi mi ko ba jẹ ki n gbọ ede naa, mo le ma di ilumọọka, ti mo da lonii.

Mo wa n rọ gbogbo obi nile tabi ni ilẹ okeere, boya USA ni abi UK, ẹ maa sọ ede abinibi si awọn ọmọ yin."

"Alaye ree lori bi mo se bẹrẹ isẹ alawada lori ayelujara"

Bakan naa ni Goroso Ekiti tun yan pelati ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni oun ti di alawada amọ ti oun ko ja kunra.

O ni lọjọ kan, oun kan n fi ede Ekiti se awada eyi ti oun ka silẹ lori foonu oun, ti oun si gbe soju opo Whatsapp oun.

Goroso Ekiti ni "Ọpọ eeyan to ri fidio kekere naa lo fẹran rẹ, ti wọn si ni ki ẹni to n se awada ni ede Ekiti naa bọ sita lati maa se e fun araye.

Idi ree ti mo fi bẹrẹ loju opo Facebook ati Instagram, ti awọn aye si fẹran rẹ.

Alabagbele wa kan ni Iya Glory, ọrẹbinrin mi si lo n jẹ Damilola.

Orukọ mejeeji yii ni mo saba maa n lo ninu awada mi, tori mo fẹran awọn orukọ naa."

"Ede Ekiti ti mo fi n se awada lo gbe mi de ọdọ gomina ati igbakeji aarẹ"

Nigba to n salaye ọpọ anfaani ati ipenija to ti ri ninu sise awada pẹlu ede Ekiti, Goroso ni awada kan ti oun se mu ki oun gba oriyin pupọ.

"Nigba isejọba gomina Kayode Fayemi ni Ekiti, bo se gbọ̀ọ ọkan lara awọn awada mi lede Ekiti, lo ni ki wọn lọ wa mi jade.

Kilaasi ni mo wa nile ẹkọ fasiti nigba naa, ti wọn si de pe gomina n pe mi.

Mo de ọdọ rẹ, o si bọ mi lọwọ, bakan naa ni awada yii ti gbe mi de ọdọ igbakeji aarẹ."

Nigba to n salaye awọn ipenija to n ri nidi awada sise ni ede Ekiti, Goroso ni ọpọ ololufẹ oun lo maa n fẹ ki oun se awada ni ọfẹ eyi ti ko dara to.

"Ti awọn ololufẹ mi ba ri mi, wọn yoo fẹ ki n fun awọn ni owo lai mọ boya emi gan lowo lọwọ.

Awọn eeyan to n fẹ ki n fun awọn lowo yii naa si lo tun n fẹ ki n maa se awada ni ọfẹ fun awọn lode ayẹyẹ.

Se ẹ ri pe eyi ko jọra wọn."

Goroso Ekiti wa gba awọn ọdọ akẹẹgbẹ rẹ nimọran lati maa gbe ede abinibi wọn larugẹ, ki wọn si mase maa tabuku rẹ.