Entertainers who died within five months: BBC Yorùbá ṣe àkójọpọ̀ àwọn amúlùúdùn mẹ́fà tó kú láàrin oṣù márùn-ún

Diẹ lara awọn gbajumọ to jade laye

Ojoojumọ ni ẹda n ku bi ilẹ se n su, to si n mọ, bẹẹ ni ọrun n gbalejo tuntun.

Bo si se n waye laarin awọn araalu, naa lo n waye lagbo awọn osere amuludun, boya akọrin ni tabi onitiata.

Bi iku awọn amuludun yii ba si se n waye, ni ọpọ eeyan yoo fi ika hanu pe ogo miran lo tun wọọkun yii.

Laarin osu marun nikan, akaimọye awọn amuludun yii lo ti ki aye pe o digbose, ti araalu si n kẹdun wọn.

Idi si ree ti BBC Yoruba fi se akojọpọ awọn amuludun marun ni iran Yoruba, to ti dagbere faye laarin osu marun.

Àkọlé fídíò, Baba Suwe: Bi eto isinku Babatunde Omidina se lọ ree

Awọn amuludun mẹfa to ku laarin osu marun:

Baba Suwe:

Baba Suwe

Oríṣun àwòrán, Olusola Omidina/ Instagram

Se ni ilẹ mi titi ni ọjọ Aje, ọjọ Kejilelogun osu Kọkanla ọdun 2021 ti gbajumọ adẹrinposonu ninu sinima, Babatunde Omidina, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Suwe jade laye.

Aisan rọlapa rọlẹsẹ lo seku pa alawada yii, to si ti wa lori aarẹ naa fun ọdun diẹ, ki ẹmi rẹ to bọ.

Ọdun mẹtalelọgọta ni alawada naa lo loke eepẹ, ki ọlọjọ to de.

Ọdun 1971 ni Baba Suwe bẹrẹ awada sise ninu sinima, to si ti dẹrin pẹẹkẹ ọpọ eeyan ti ko le gbagbe rẹ.

Amọ sinima Omolasan to se lo mu ki aye tete riran ri i, to si tun gbe ọpọ sinima miran jade saaju ati lẹyin rẹ.

Koda, ko si mi, ajọ ko kun ni ọrọ Baba Suwe lagbo tiata nigba to wa loju ọpọn nitori oju rẹ lasan pawo ninu fiimu.

Idi si ree tawọn osere tiata akẹgbẹ rẹ atawọn oludari ere fi maa n du lọtun losi lati jẹ ko kopa ninu ere kan.

Sugbọn akude wọ isẹ to yan laayo naa nigba ti ajọ to n gbogun ti lilo ati gbigbe oogun oloro, NDLEA mu ni papakọ ofufuru Eko, nigba to n rinrin ajo lọ soke okun.

Ẹsun ti ajọ NDLEA fi kan ni pe o gbe oogun oloro sinu rẹ amọ gbogbo aayan wọn lati jẹ ko ya igbẹ lati ko awọn oogun oloro naa jade lo ja si pabo.

Ọrọ naa di tile ẹjọ, ti adajọ si ni NDLEA jẹbi lati fi ẹsun kan osere tiata naa nitori pe wn ko ni ẹri to daju lati gbe kalẹ pe o gbe oogun oloro.

Ile ẹjọ wa ni ki NDLEA san miliọnu mẹẹdọgbọn naira fun osere tiata naa bii owo gba ma binu amọ ko si owo naa gba titi to fi jade laye.

Ọpọ eeyan si lo n sọ pe wahala ti ajọ NDLEA gbe ti Baba Suwe lo fa aisan si lara eyi to mu ko ku laipe ọjọ.

Tafa Oloyede:

Tafa Oloyede

Oríṣun àwòrán, Tafa Oloyede

Amuludun miran to tun jade laye laarin osu marun sẹyin ni gbajugbaja osere tiata kan, John Adewuni ti ọpọ eeyan mọ si Tafa Oloyede Actor.

Ọjọ Isẹgun, ọjọ Kinni osu Keji osu 2022 ni Tafa Oloyede jade laye lẹni ọdun mọkandinlaadọrin.

Aisan ranpẹ si ni mọlẹbi rẹ kede pe o mu ẹmi gbajumọ osere tiata naa lọ.

Nigba aye rẹ, Tafa Oloyede lo jẹ ogunna gbongbo ninu ẹgbẹ osere tiata oloogbe Oyin Adejobi nilu Osogbo.

O si ti kopa ninu awọn oniruuru ere tiata bii Kootu Aṣipa, Ile ta fitọ mọ, Kuye Ọgba Iwosan, Orogun Adedigba ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bakan naa lo ti bawọn agbaagba osere tiata bii Herbert Ogunde, Adeyemi Afolayan (Ade Love) ati Baba Sala kopa ninu sinima bii Jaiyesimi, Ayanmo, Akanji Oniposi ati bẹẹ lọ.

Shade Taylor

Gbajumọ osere tiata ni Shade Taylor, ti ọpọ eeyan mọ Oluweri Magbojo.

Ilu London ni oloogbe naa fidi kalẹ si, to si n dabi ẹdun, rọ bi owe, ki iku to pa oju rẹ de.

Lara awọn ere tiata alarinrin to sọ Shade Taylor di ilumọọka lagbo tiata ni Omo Alhaja ati Oluweri Magbojo.

Ọjọ Aje, ọjọ Kinni osu Kẹta ọdun 2022 si Shade Taylor mi kalẹ, to ki aye pe o digbose lasiko aisan ranpẹ.

Ẹni ọdun mọkandinlọgọta ni Oluweri Magbojo amọ awọn ẹbi rẹ ko kede irufẹ aisan to mu ẹmi gbajumọ osere tiata naa lọ.

Dejo Tunfulu:

Dejo Tunfulu

Oríṣun àwòrán, Dejomania/Instagram

Alawada ati adẹrinposonu ni Kunle Adetokunbo, ti ọpọ eeyan mọ si Dejo Tunfulu.

Oju to n pawo ni oju Dejo Tunfulu lagbo tiata, to si ti kopa ninu ere sinima kaakiri lede Yoruba.

Ọjọ Ẹti, ọjọ Kinni osu Kẹrin ọdun 2022 ni adẹrinposonu naa jade laye nigba to ku osu diẹ ko pe ẹni aadọta ọdun.

Lara awọn ti Dejo Tunfulu fara kinra pẹlu nidi awada sise ninu tiata ni Baba Suwe.

Awọn mejeeji si ti di oloogbe bayii, ki Ọlọrun tẹ wọn si afẹfẹ rere.

Iyanda Sawaba:

Iyanda Sawaba

Oríṣun àwòrán, Iyanda Sawaba/Facebook

Gbajugbaja akọrin Fuji ni Iyanda Sawaba ti ọpọ eeyan mọ si Easy Sawaba.

Ọjọ Kẹfa osu Kẹrin ọdun 2022 ni Sawaba ki aye pe o digbose lasiko aisan ojiji to mu.

Ile iwosan ẹkọsẹ isegun UCH ni Easy Sawaba ku si lẹni ọdun mọkanlelaadọrin.

UCH yii si lo ti n gba itọju nigba ti aisan naa sadede kii, to si ku laarin ọsẹ meji ti aisan naa bẹrẹ.

Iroyin iku Sawaba ni akọrin Fuji naa de lati ode ariya kan ni aisan ọhun de si lojiji, ti wọn si gbe digba digba rele iwosan.

Ni bii ọdun 1970 si 1980 ti Sawaba n lo saa lọwọ, ọpọ ode ariya ni wọn ti maa n lo awo orin rẹ, paapaa Pata Olokun to sọ di ilumọọka.

Ki Easy sawaba to jade laye, o le ni awo orin Fuji mejilelogun to gbe jade.

Lara awọn awo orin naa ni Suru, Igbo Odaju, Pata Olokun, Ayetoto ati Oroseniwo.

Ọdun 2018 lo gbe awo orin Fuji jade kẹyin eyi to pe akọle rẹ ni 'Correction'.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Orlando Julius:

Orlando Julius Ekemode

Oríṣun àwòrán, Orlando Julius Ekemode/Facebook

Gbajumọ akọrin Highlife ni Orlando Julius Ekemode, to si wa loju ọpọn lẹyin ti orilẹede Naijiria gba ominira tan.

Ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹẹdogun osu Kẹrin ọdun 2022 lo dagbere faye bi o tilẹ jẹ pe mọlẹbi ko tii kede iru iku to gbẹmi rẹ.

Ọdun 1943 ni wọn bi Julius nilu Ikole, ti baba rẹ si jẹ onisowo plu awọn oyinbo.

Iya Julius si lo kọ ni orin kikọ eyi to mu ko nifẹ lati maa kọrin, to si wa ninu ẹgbẹ akọrin fun ileẹkọ rẹ lọdun 1957.

Iku baba oloogbe naa lo mu ko kuro nileẹkọ lairotẹlẹ, to si gba ilu Ibadan wa lati yan isẹ orin kikọ laayo.

Ilu Ibadan si lo ti dara pọ awọn ẹgbẹ akọrin juju lorisirisi bii Rex Williams, Jazz Romero ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Orlando maa n gba Fela laaye lati goke wa kọrin pẹlu rẹ, to si ni nitori toun ni Fela fi kọ baa ti n fọn Saxophone.

Lara awo orin to gbe Orlando Julius Ekemode sita ni Jaguar Nana.

BBC Yoruba wa n gbadura pe ki Ọba Oke fi ọ̀run kẹ awọn gbajumọ amuludun to ti rewalẹ aṣa, ko si maa sọ awa ta ku lẹyin wọn.