Jerusalem: Ènìyàn 150 farapa bí ìkọlù tuntun ṣe bẹ̀rẹ̀ ní mọ́ṣáláṣí al-Aqsa

Àwọn tó ń ṣe ìkọlù síra wọn
Àkọlé àwòrán, Àwọn tó ń ṣe ìkọlù síra wọn

Kò dín ní àádóje ènìyàn Palestin tó ti farapa níbi ìkọlù tó wáyé láàárín àwọn ọlọ́pàá Israeli àti àwọn Palestin ní mọ́ṣáláṣí al-Aqsa tó wà ní Jerusalem.

Àwọn ọlọ́pàá Israeli ní ìkọlù tí àwọn ènìyàn Palestin kọ́kọ́ ṣe sí àwọn nípa jíju òkò, òkúta àti àwọn nǹkan olóró mìíràn sí àwọn ló jẹ́ kí àwọn náà yawọ mọ́ṣáláṣí náà.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí àwọn ọlọ́pàá Israeli fi léde, ọlọ́pàá mẹ́ta ló farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Mọ́ṣáláṣí yìí ṣe pàtàkì sí àwọn Mùsùlùmí àti àwọn Júù, tí wọ́n kàá sí àyè mímọ́.

Ìkọlù láàárín àwọn ènìyàn Israeli àti Palestin ló ti ń gbópọn ní ọjọ́ mẹ́ta yìí lẹ́yìn tí àwọn ènìyàn kan pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìkọlù kan tó wáyé láàárín wọn ní Israel.

Ile iṣẹ́ ètò ìlera Palestin nínú àtẹ̀jáde kan ní ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kan tó farapa níbi ìkọlù tí àwọn ènìyàn Israel ṣe sí agbègbè Jenin ní ẹkùn àríwá West Bank ní ọjọ́rú ti jáde láyé ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù kẹrin, ọdún 2022.

Àkọlé fídíò, Easter Celebration: Olórí Celestial ní Krìstíẹ́nì kò yẹ kó fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú àjíǹde

Báwo ni ọ̀rọ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀?

Kò dín ní ènìyàn ogun tó jẹ́ ọmọ Palestin, èyí tí wọ́n pè ní agbébọn tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìkọlù tí Israel ṣe sí West Bank pàápàá ẹkùn Jenin lẹ́yìn tí àwọn ènìyàn ṣekúpa àwọn ọmọ Israel mẹ́ta ní Tel Aviv lọ́jọ́bọ̀ ọ̀sẹ̀ tó kọjá.

Ìkọlù yìí ni ìkẹrin tí yóò wáyé ní Israel láàárín àwọn ọmọ Israel tó jẹ́ Lárúbáwá àti àwọn Palestin láàárín ọ̀sẹ̀ méjì.

Ìkọlù yìí ti ṣokùnfà ikú ọmọ Isreal méjìlá àti ọmọ orílẹ̀ èdè Ukraine méjì, èyí tó jẹ́ àkọ́ọ́lẹ̀ ikù ènìyàn tó pọ̀ jùlọ láti ìgbà tí ìkọlù ti ń wáyé ní Israel láti bí ọdún mẹ́ẹ̀dógún sẹ́yìn.

Iléeṣẹ́ ọlọ̀pàá Israel ní lógún lọ́gbọ̀n àwọn ọmọ Palestin, tí àwọn kan gbé àsíá ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Hamas dání ya wọ inú ọgbà mọ́ṣáláṣí náà ní òru tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ síní ju òkò àti àwọn nǹkan mìíràn mọ́ àwọn.

Iléeṣẹ́ ọlọ̀pàá ní àwọn ní sùúrù láti ri wí pé àwọn mùsùlùmí parí ìrun wọn kí àwọn tó tú àwọn olùfẹ̀hónúhàn tó ń ju òkò lu ibi tí àwọn Júù wà.

Àwòrán inú ọgbà mọ́ṣáláṣí al-Aqsa
Àkọlé àwòrán, Àwòrán inú ọgbà mọ́ṣáláṣí al-Aqsa

Iléeṣẹ́ ilẹ̀ òkèrè Palestin bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù náà

Iléeṣẹ́ ilẹ̀ òkèrè Palestin ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù tí Israel ṣe sí ọgbà mọ́ṣáláṣí náà bí wọ́n ṣe ní àwọn ló wà nídìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Iléeṣẹ́ ilẹ̀ òkèrè Palestin ní ìkọlù náà wáyé nítorí ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Gaza ti sọ wí pé kí àwọn ọmọ Palestin péjọ sínú ọgbà mọ́ṣáláṣí náà láti dá ààbò bo orílẹ̀ èdè àti mọ́ṣáláṣí wọn.

Àkọlé fídíò, Female Carpenter: Fatia Garu ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí gbàgbọ́ pé obìnrin ló ń ṣiṣẹ́ Káfíńtà