Ooni Ife's New Princess: Ooni Ogunwusi ní òun nífẹ̀ẹ́ ìyá tó bí ọmọbìnrin náà púpọ̀

Oríṣun àwòrán, Screenshot/ instagram
"Ọmọọbabinrin Adebunkunmi Adeifẹ pe ọdun kan loni.
Ọlọrun ọba yoo fun ọ ni ẹmi gigun lati ṣe rere laye. O n mu mi ranti iya mi to ti jade laye, nitori aworan rẹ lo jẹ. Mo nifẹ rẹ pupọ Mama Adebuks."
Ọrọ ikini ku ọjọ ibi yii ti Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹyẹ Ẹniitan Ogunwusi, Ọjaja keji fi ki ọmọdebinrin jojolo kan lori oju opo ayelujara Instagram rẹ.
- Kà nípa ìbẹ̀rẹ̀ ìyàwó Ooni Ife, Olórí Silekunola Moronke Náómì, Wòlíì tó di Ayaba Ile Ife
- Ta ni Ashley Folasade Adegoke ti ayé ń pariwo pé òun ni Olorì tó máa rọ́pò Naomi Silekunola?
- Irọ́ ni o! Ìyàwó Ọ̀ọ̀ni Ogunwusi kò bímọ tuntun
- Báyìí ni mo ṣe san nínú oore Ọlọ́run tó fi Kábíyèsì Ooni ti Ile Ife ta èmi Silekunola lọ́rẹ - Olorì Wòlíì Naomi
- Mọ̀ síi nípa àwọn Obìnrin tó wà láyé Ooni Ogunwusi ṣáájú Olòrì Naomi SilekunOla
- Kà nípa ibi tí wọ́n bí Àrẹ̀mọ tuntun Ọọ̀ni Ife sí, àti orúkọ tó ń jẹ́
- Ki ní yóò sẹlẹ̀ sí Àrẹ́mọ Ooni Ile-Ife tí wọ́n bá gbé e kúrò l'Áàfin?
- Ooni ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ẹ̀bùn tuntun ta Olorì Naomi lọ́rẹ tán ní, ìfẹ́ wọn dúró, kò sí ìpínyà- Aàfin Oòdúà
Ilana ti ikinni yii gba, lo ti n mu ki ọpọ ẹnu maa kun Kabiyesi Ọọni Adimula, olori ade gbogbo bayii pe, lẹyin o rẹyin, baba ti fi oju ọkan lara awọn eso rẹ han lati ọdọ obinrin miran.
Bi ẹ ko ba ni gbagbe, ni ipari ọdun to kọja ni Yeyelua ilẹ Yoruba to jẹ olori laafin Oodua, Olori Naomi Silẹkunọla Ogunwusi gba oju opo Instagram lọ, lati ke gbajare sita pe oun n fi Kabiyesi Ọọniriṣa silẹ nitori awọn idi kan tabi omiran.
Lara awọn idi ti Olori Naomi ka silẹ nigba naa ni pe Kabiyesi n huwa ṣekuṣẹyẹ nitori pe iyatọ wa ninu iwa to n hu ninu ile ati eyi to n hu ti gbogbo agbaye mọ pẹlu rẹ.

Oríṣun àwòrán, Screenshot/instagram
Ẹ ma gbagbe pe ṣaaju didori itẹ Ọọni Adimula, ni o ti kọkọ bi ọmọbinrin kan nigba ewe rẹ, ki olori Silẹkunọla to wa bi ọmọkunrin fun un.
Nigba ti BBC yoo tun fimu finlẹ kaakiri ayelujara, a kan lu oju opo @abikejagaban nibi ti ikini ku ọjọ ibi ti jade fun ọmọọbabinrin to pe ọdun kan yii.
Abike Jagaban wa kọ ẹkunrẹrẹ orukọ ọmọbabinrin naa, ti wọn pe ni Ọmọọbabinrin Adebunkunmi Adeifẹ Ogunwusi...Ọmọọba Ogunwusi Ọjaja II"

Oríṣun àwòrán, Screenshot/ instagram
Bi o tilẹ jẹ wi pe ko tii si atẹjade kan pato lati ile Oodua, tii ṣe aafin Ile Ifẹ pe Ooni ti fẹ iyawo miran, ọpọ ti woye rẹ pe o ṣeeṣe ki eyi kun ara idi ti Olori Naomi Silẹkunọla Ogunwusi fi digba di agbọn rẹ fi aafin silẹ lẹyin to kede rẹ lori ayelujara.















