Ooni Ile Ife marriage: Mọ̀ síi nípa àwọn Obìnrin tó wà láyé Ooni Ogunwusi Adeyeye ṣáájú Olòrì Naomi SilekunOla

Ooni

Oríṣun àwòrán, Others

Lati ọjọ kẹtalelogun, oṣu kejila ọdun yii ti Olori Naomi Silekunola aya Oba Adeyeye Ogunwusi to jẹ Ooni ti IleIfe ti kede lori ayelujara pe o toge ni oriṣiriṣi iroyin ti n jade.Olòrì Silekunola Naomi Ogunwusi: Mo ti sún síwájú, mo gbìyànjú pé kí ìgbèyàwó yìí ṣiṣẹ́ ṣùgbọ́n....

Eyi lo jẹ ki BBC Yoruba lọ ṣe iwadii awọn irpyin to n kede ọpọlọpọ obinrin fun Ooni naa pe wọn jẹ aya rẹ yatọ si Olori Naomi.

Opọ ninu awọn iroyin naa jẹ ofege nitori ko si akọsilẹ to ṣe e fihan pe nitootọ ni kabiesi Ogunwusi fẹ awọn obinrin mẹwaa naa ti ọpọ n sọ nipa wọn lori ayelujara.

Obinrin mẹrin wọnyii nikan ni akosile ojutaye wa nipa wọn ati akoko ti wọn fi wa pẹlu Ojaja keji.

Obinrin akọkọ ti igba oju mọ pẹlu Oba Adeyeye Ogunwusi ni arabinrin Omolara Olatubosun.

Odọmọde ti ko tii pe ẹni ogun ọdun ni awọn mejeeji lasiko ti wọn jọ n rin papọ ki o to di oyun ti wọn fi bi Ọmọbabinrin Adeola Ogunwusi ni o din diẹ ni ọgbọn ọdun sẹyin.

Àkọlé fídíò, Àwọn aláànú ṣe ọdún fáwọn tí kò rí ọwọ́ họrí

Adebukola Bombata ni obinrin imii to jade ninu aye Oba Ogunwusi ṣaaju ki o to jẹ Oba Ile Ife.

Lọdun 2008 ni wọn ṣe igbeyawo ni won jọ gbe papọ ki onikaluku to pin gaari.

Ooni ati Adebukola

Oríṣun àwòrán, @Others

Bi awọn kan ṣe sọ pe Adebukola fi Ooni Ogunwusi silẹ lọdun 2015 nitori pe ipo Oba naa ko wu u ni àwọn mii ni pe nkan miran lo jẹ ki wọn fi ara wọn silẹ.

Lọdun 2015 lẹyin ti Ooni gori aleefa itẹ awọn baba nla rẹ ni o gbiyanju iyawo miran.

Ooni ko duro nile Yoruba rara lati lọ mu arẹwa to wu Kabiesi.

Àkọlé fídíò, 'Èmi ò kí ń lu ìyàwó mi'

Benin ni ipinlẹ Edo to jẹ ọmọ iya Oodua ni Oba Ogunwusi ti lọ gbe Olori Zainab Otiti Obanor Wuraola.

Igbeyawo naa si wa sopin lọdun 2017.

Àkọlé fídíò, Ooni Ile Ife ti sọrọ lori Olori Naomi

Lọdun 2018 ni Oba Adeyeye Ogunwusi gbe Ajihinrere obinrin Naomi Silekunola lati ipinlẹ Ondo ni iyawo.

Oba Oke fi omokunrin lantilanti, Tadenikawo Ogunwusi ta wọn lọrẹ lọdun to kọja.

Àkọlé fídíò, Ohun mẹ́jọ tóo ní láti mọ̀ bí o bá fẹ́ lọ ilé ọdun

Igbeyawo yii ni Olori Naomi si wa kede lori ayelujara bayii pe oun ti sun siwaju nitori pe oun fẹ gbajumọ ṣiṣe iya ọmọ rẹ Tadenikawo.

Àkọlé fídíò, 8kyti,j

Ikede yii ni Moses Olafare agbenuso fun Ile Oodua ni Ile Ife sọ fun BBC Yoruba pe wọn ko mọ nkankan nipa rẹ nitori pe Ooni ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ẹ̀bùn tuntun ta Olorì Naomi lọ́rẹ tán ní, ìfẹ́ wọn dúró, kò sí ìpínyà- Aàfin Oòdúà

Àkọlé fídíò, Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀