Christmas: Ìdí tí Bàbá Kérésì fi máà n wọ aṣọ pupa àti funfun nígbà gbogbo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọlọpọ gbagbọ pe Baba Keresi maa n wọṣọ ni ibamu pẹlu aàwọ̀ pupa ati funfun to wa lara agolo nkan mimu ẹlẹrindodo Coke.
Won ro eyi nitori pe ipolowo ọja Coca Cola ni nkan bii ọdun 1030 lo sọ Baba Keresi di gbaju-gbaja.
- Wo ọ̀nà mẹ́wàá tí o fi lè dábò bo ara ré lásòkò ọyẹ́ yìí
- Ọ̀fẹ́ ni ọkọ̀ ojú irin akérò yóò máa kó àwọn arìnrìnàjò lásìkò pọ̀pọ̀ṣìnṣin ọdún yìí - Ìjọba àpapọ̀
- Mọ̀ síi nípa Olorì Abibat Nihinlola Adeyemi tó ti lo ọdún 60 gẹ́gẹ́ bíi olorì láàfin Alaafin Oyo
- Ẹ̀yin olùgbé ìlú Eko, ẹ má bẹ̀rù, bílíọ̀nù mẹ́ta ni a ná lórí ọlọ́pàá lọ́dún 2021- Sanwo-Olu
O dara bẹẹ, ṣugbọn wọn ko da Baba Keresi alaṣọ pupa ati funfun kalẹ lati polowo Coca Cola, ṣugbọn nitori pe o n du ọja pẹlu White Rock l'ọdun 1923 ni.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orisun miran ni aṣọ Baba Keresi ode oni ti wa.
Ọkan lara wọn ni Saint Nicholas. Biṣọọpu Greek ni aye atijọ, to maa n wọ aṣọ pupa ni gbogbo igba to ba ti fẹ ẹ fun awọn alaini ni ẹbun. paapa awọn ọmọde.
Ìtàn miran lati ọwọ oṣere Netherlands, Sinterklas, to tun dale Saint Nicholas, to gbajumọ laarin awọn olowo ni New York, bi i Washington Irving ati Clement Clark Moore ni nkan bi ọdun 1800.
Awọn mejeeji gbiyanju lati sọ Aisun alẹ Keresimesi di nkan ti gbogbo eniyan yoo wa lori ibusun wọn lati sun, dipo ayẹyẹ ati ariya ita gbangba.
Ọgbẹni Moore jẹ ọ̀kan lara awọn to da Baba Keresimesi ti Amẹrika silẹ - ẹni mimọ to maa n wọ aṣọ pupa, ti yoo si maa fun gbogbo eniyan ni ẹbun, boya wọn fẹ tabi wọn ko fẹ ẹ.
Ta a ni Baba Keresi gan an gan?
A le tọ ipasẹ Baba Keresi lọ si ọdọ Biṣọọpu Greek, Nicholas.
Ninu ẹ̀sìn Kristiẹni, ọpọ maa n pọn ọn le gẹgẹ bi alaabo awọn ti ko ni iya ati baba, awakọ oju omi ati awọn ẹlẹwọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Olukọtan kan ni Fasiti Manitoba, Gerry Bowler, ṣalaye pe nitori pe Ẹni Ọwọ Nicholas maa n pin ẹbun fun awọn eniyan, ni wọn ba bẹrẹ sii ri gẹgẹ bi baba-isalẹ awọn ọmọde ati onidan to maa n fun nii ni nkan.
Ṣugbọn, ipolowo ọja lo mu ki Baba Keresimesi ode-oni o gbajumọ.
Ni nkan bi ọdun 1820, ipolowo fun ẹbun ọdun Keresimesi bẹrẹ si ni tan kiri orilẹ-ede Amẹrika, nigba ti yoo si fi di ọdun 1940, Baba Keresi naa ti bẹrẹ si ni farahan daada ninu ipolowo ọja.
Bi ififunni lasiko Keresi ṣe bẹrẹ niyi.


















