Ooni of Ife's surprise birthday: Olorì Wòlíì Silekunola Naomi wú olólùfẹ́ rẹ̀, Ooni ti Ile Ife lórí

Ooni ati Olori

Oríṣun àwòrán, Goldmytv

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

"Baba wa, ọkọ mi olowo ori Silekunola, Akanbi emi ataata

Ooni, adade owo r'ẹmu, mo ni kaa kan san ninu ore kekere

ti Baba ṣe fun gbogbo wa naa ni.

Ọkọ mi olowo ori mi, ṣe bi iwọ ni ọkọ lati ipilọṣẹ wa

Olori Ooni ti Ile Ife, Alayeluwa, Ooni Adeyeye Babatunde Enitan Ogunwusi Ojaja keji ti ni oun ni lati ṣa ọkọ oun fun anfani ti oun ni lati fẹ Kabiyesi.

Gẹgẹ bi Ooniriṣa ṣe n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ lonii ọjọ Kẹtadinlogun oṣu Kẹwaa ni iyawo, Olori Naomi rẹ ati aburo rẹ, Ọmọọbabinrin Adesola ṣe eto ayẹyẹ iyalẹnu fun un lai mọ nipa rẹ tẹlẹ.

Ṣe ni ori Kabiyesi gan n wu nita gbangba ti ko ṣee pa mọra gẹ́gẹ́ bi Olori rẹ ṣe n kii ni mẹ́san mẹ́wàá to tun ni oun fẹ sọ nipa ore ti Baba ti ṣe.

Kabiyesi: O tun ti fẹ maa sa mi niyẹn o...

Olori: Mo ni kaa kan san ninu ore kekere ti baba ṣe fun gbogbo wa naa ni...

Ooni ati Olori

Oríṣun àwòrán, Olori Silekunola

Àkọlé fídíò, Bí àlááfíà yóò ṣe wà láàrin Fulani àti Yorùbá ni Ooni bá lọ sọ́dọ̀ Buhari- Ààfin Ile Ife

Pẹlu ẹrin musẹ lẹnu awọn mejeeji, bi o ṣe mu ikunlẹ haa to n ki ọkọ rẹ ni Olori Silekunola kẹnu bọ orin "gbese ọpẹ mi pọ" to ni oun ma fin yin Ọlọrun to da oun saye to tun wa fi Ooni ta oun lọrẹ.

O ni oun n dupẹ ti Tadenikawo, ọmọkunrin ti Ọlọrun fi ta wọn lọrẹ tao si n ki ọkọ rẹ ni mẹsan mẹwaa gẹgẹ bi ẹni to ni ẹbun oriki.

Kabiyesi naa wa fesi nibẹ nigba to n dupẹ lọwọ awọn to peju sibẹ pe ki nkan ire maa de ba wọn gaan ni idunu oun.

"Too ba ba mi rin fun bii ọdun meji, mẹta ti nkan o ṣe pẹli, nkan n ṣe ẹ gidi gan o". O ni lootọ oun o ki n ṣe Ọlọhun amọ o ran oun wa ṣe rere ni.

Kabiyesi ki adura bọ ẹnu fun gbogbo awọn to wa nibẹ pe wn yoo ṣe oriire ti wọn si ṣe aṣẹ sii.

Ṣe lo tun jẹjẹ pe lootọ, oun le ma tii kan awọn ti wọn wa nibẹ lara amọ ki wọn fọkan balẹ tori ko rẹ oun.

"A mọ awọn to jẹ pe nkan mii ni wọn ba wa sibi, kii ṣe fun rere, mo si mọ wọn, ṣiṣe ṣiṣe ni yoo maa ba wọn tori ko sẹni to kọja aṣiṣe".

Ni dede agogo mejila ọjọ ti wọn bii saye ni ayẹyẹ ọjọibi yii waye, Ooni ni o da bii pe wọn ti fẹ sọọ di aṣa mọ oun lọwọ ni gbogbo ọjọ ibi oun ti oun si kọkọ fẹ sa mọ gbogbo eeyan lọwọ amọ "mo wo waju mo ri eeyan, mo wo ẹhin mo ri eeyan".