Ooni Ogunwusi: Ẹ sinmi àdíjàlẹ̀ ìròyìn, Adeleke kò ní òun yóò ra bàálù fún mi

Oríṣun àwòrán, Ooni Of Ife
Ooni tilu Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi ti pariwo fun araye pe irọ to jinna sootọ ni ahesọ ọrọ kan to n ja rain pe Sẹnetọ Ademola Adeleke seleri lati ra baalu fun oun.
Atẹjade kan ti akọwe feto iroyin si Ooni, Moses Olafare fisita lo sisọ loju ọrọ yii fawọn akọroyin.
Atẹjade naa salaye pe ofuutu fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kaun lasan ni iroyin naa to jade sita lasiko ti oludije fun ipo gomina laẹ ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke wa se aago laafin si Ooni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wàládè dé! Àwọn obìnrin aṣaralóge wọ gàù ikọ̀ Taliban ní Afghanistan
- Òrùka ìgbéyàwó,ìlẹ̀kẹ̀ ìdí àti àwọn nkán míràn tàwọn eléwé ọmọ fí n ṣètò ìfètòsọ́mọbíbí
- Nkan mẹ́sàn-án tí o le ṣe láti dènà ìkú ọmọ tuntun
- Okùnrin yìí ra àpò ìrẹsì mẹjì, ó fi ọmọ méjì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi owó
- Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ń se ọbẹ̀ tó máa ń fún wọn ní ìbejì ní Igbo-Ora
- Owó yíyá kò kọjá àfaradà tí a bá ti lò ó dáadáa- Aarẹ Buhari
Iroyin eke naa ni lasiko yii ni Adeleke seleri pe oun yoo ra baalu fun Ooni Ogunwusi lati maa fi se ẹsẹ rin.
Amọ atẹjade naa ti wa sẹ lori ọrọ ọhun, to si salaye pe aafin Ooni kọ lo fi atẹjade sita nipa ọrọ naa, gẹgẹ bi awọn ileesẹ iroyin kan ti polongo rẹ.

Oríṣun àwòrán, Ooni Of Ife
"Se ni awọn akọroyin kan to fẹ ta ẹrẹ si asọ aala oloselu naa, to si tun fẹ wọ Ooni nilẹ, se magomago iroyin naa, ti wọn si kọ ohun ti ko ri bẹẹ.
Yoo si dara ti ẹni ti ọrọ yii ba ru loju wa wo fidio abẹwo Adeleke si aafin Ooni fun aridaju ọrọ to sọ ati esi ti Ooni fọ pada fun."
Atẹjade naa ni pato ohun ti Ooni sọ fun agba oselu naa ni pe ki wọn ri daju pe eto idibo gomina to n bọ ko lọwọ laasigbo ninu, eyi ti oloselu naa fara mọ.
Gẹgẹ bi Olafare ti salaye, Adeleke seleri lati se atunse oju ọna Ile Ife ati akọpari papakọ ofurufu to wa nilu Ido-Osun sugbọn awọn akọroyin alaparutu kẹyin sawọn iroyin gidi yii.
"Gẹgẹ ba se mọ pe awọn idile Adeleke ni ọpọ Baalu ni ikawọ wọn, eyi lo mu ki Ademola Adeleke se awada pe "Baba, baalu aladani tẹ maa gun gan wa nilẹ.
Abẹwo Adeleke kọ ni igba akọkọ tabi ikẹyin ti awọn oloselu yoo wa se abẹwo si Ooni ninu aafin rẹ nibayii ti idibo gomina mii n kanlẹkun, tawọn naa si tun n bọ laipẹ, to fi mọ gomina to wa nipo."
Atẹjade naa wa n fi ewe ọmọ mọ awọn adijaalẹ akọroyin leti pe ki wọn sọra fun iroyin eke, to si tun n rọ awọn araalu lati mase gba iroyin eke naa gbọ nitori ọrun apoaadi lo ti wa.



















