World Twins Festival, Igbo-Ora: Ayẹyẹ ọdún ìbejì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú síse ọbẹ̀ Ilasa

Wọn ti bẹrẹ si n pese eto ọbe Ilasa bayii niluu Igbo-Ora.
Ọbẹ yii ni igbagbọ wa pe o maa n jẹ ki awọn obinrin wọn bi ibeji, eyi to mu ki ilu naa jẹ ilu ti wọn ti n bi ibeji julọ lagbaye.

Lara awọn ohun elo ti akọroyin BBC ti foju ganni nibẹ ti wọn fi se ọbẹ naa ni ẹfọ ti wọn n pe ni ewe ila, ẹgusi, iru, epo, atawọn nnkan mi ti wọn fin se ọbẹ nilẹ Yoruba.

BBC Yoruba ti wa nikalẹ niluu Igbo-Ora lati maa mu gbogbo ba ba ṣe n lọ wa si eto igbọ ati oju iworan yin.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣeyin?
Òní lòní ń jẹ́, pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ayẹyẹ ọdún ìbéjì yóò wáyé nílùú Igbo-Ora

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nje ẹ mọ pe ilu kan wa ni orilẹ-ede wa nibiti bibi ibeji ti pọ ju?
Ṣe ko jẹ kayeefi pe ọpọlọpọ ile ni o jẹ ile ibeji ninu ilu naa?
Igbo-Ora jọ ilu to kun fun ọpọlọpọ ohun meriri ni orilẹ-ede Naijiria, nibi ti awọn oyinbo ti ṣe awari ibeji nigba mẹrindinlogun, nibi ikunlẹ ẹgbẹrun.
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba orílẹ̀-èdè Benin ti gba àbọ̀dè lórí ẹjọ́ sunday Igboho?
- Ṣé o mọ̀ pé o leè kó Covid pẹ̀lú ọmọ ìka ẹ̀sẹ̀ rẹ̀ láì mọ̀?
- Bí a kò bá yá owó, Nàìjíríà ò bá má bọ́ nínú ìfàsẹ́yìn ọ̀rọ̀ ajé - Mínísítà ètò ìsúná
- Mo dúpẹ́ pé Ọlọrun kò jẹ́ kí àwọn ọmọge tí mo kọ́kọ́ dẹnu ìfẹ́ kọ gbà láti fẹ́ mi - Mike Bamiloye
- Kókó mẹ́rin tó jẹyọ lẹ́yìn ìpàdé àwọn adarí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP
- Ojú wa rí tó lásìkò tì a wà ní àhámọ́ ajínigbé, koríko la jẹ fún ọjọ́ 52
- Ààrẹ Buhari, wá ọ̀nà míràn látí wá owó fún ètò ìṣúná 2022, ẹ̀yáwó ojojúmọ́ tí pọ̀jù- Ilé Ìgbimọ̀ Aṣòfin
- Wàhálà bẹ́ sílẹ̀ nílé aṣòfin, káńsẹ́lọ̀ obìnrin ní alága ìjọba ìbílẹ̀ ló pàṣẹ pé káwọn jàndùkú fa aṣọ òun ya.
- Ẹ wo Ajá tó ń gbọ́ òórùn àìsàn ibà, ẹja tí a kò gbọdọ̀ pa àti ọọ̀nì tó ń gbọ́ àdúrà ní Ìbàdàn
Ilu yii kan naa ni awọn ara Amẹrika ti ṣe awari ibeji ni ikunlẹ mẹtalelọgbọn ni ikunlẹ ẹgbẹrun.
Ilu Igbo-Ora to wa ni orilẹ-ede Naijiria tun ṣe awari ibeji nigba aadọta ni ikunlẹ egberun.
Oniwadii Patrick Nylander lo fidi awari rẹ mulẹ nigba to rinrinajo lọ si ilu Igbo-Ora.
Ilu Igbo-Ora ni jẹ ogoje kilomita lati Ilu Eko, o si jẹ olu ilu fun awọn ibeji ni agbaye.
Ibeji wọn pọ ni ilu Igbo-Ora ju ilu miran lo lagbaye, iwadii fi mulẹ pe, arinrinjo ninu ilu naa le fẹ dojuru fun alejo nigba to ba pade oniruru awọn ti wọn jọ ara wọn nitori ile kọọkan lo ni ibeji larin wọn.
E bawa kalọ nigba ti a ba darapọ fun pọpọṣinṣin ọdun ibeji ti ọdun 2021, nibi ti a oo ti mu ara ọtun ninu aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba wa fun yin, ati pataki ọdun ibeji ni ilẹ kaarọ oojiire.
- Agbébọn yìnbọn pa akẹ́gbẹ́ rẹ́ lásìkò ìjínígbé tí wọ́n kójú Àmọ̀tẹ́kùn
- Kí ló lè mú kí ará ìlú fárígá pátápátá nítorí pé kò sí iná mọ̀nàmọ̀nà?
- Àwọn olọ́kadà ti gba àwọn ìyàwó wa tán nítorí a kò lówó lọ́wọ́- Àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì ni Benue
- Àwọn Òṣèré fíìmù Yorùbá tẹ́ ò ro tó tí jápaa lọ ìlú Òyìnbó rèé
- Chiwetalu Agu ti gba òmìnira lọ́wọ́ àwọn sọ́jà tó mú u














