Veteran Yoruba actors who relocated: Àwọn Òṣèré fíìmù Yorùbá tẹ́ ò ro tó tí jápaa lọ ìlú Òyìnbó rèé

Awọn oṣere

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Agbo Òṣeré fiimu Yoruba figba kan kun fun awọn eekan osere to si mọ isẹ wọn daadaa koda orúkọ wọn ti di manigbagbe.

Láti bíi 1990s titi di akoko yii awọn isipo padà kan tí ṣẹlẹ̀ lagbo osere bo tilẹ̀ jẹ pe isẹ wọn ò parẹ paapaa pẹlu awọn sinima agbelewo ti wọn ṣe jáde tabi kopa ninu wọn.

Nigba ti ọ̀pọ̀ wọn sì wa ti wọn n ṣe daadaa lorile-ede Naijiria, awọn míì ti wa papa oko tútù lọ si orileede miran.

A o ṣe alakalẹ díẹ̀ lára àwọn osere tó gbajumọ ni nkan bíi 1990s sugbọn ti wọn ti ń gbe ni Amẹrika tàbí ìlú òkè òkun miran báyìí tí ẹ lè má lérò.

Baba Kekere

Oríṣun àwòrán, Yetunde Olugbenga

Solomon Majekodunmi

Baba Kekere ni ọpọlọpọ mọ ọ si. Solomon Majekodunmi kii ṣe ẹni aimọ rara lagbo osere Yoruba torí ó kopa lára awọn sinima to ṣe koko ni 1990s.

Toyin Majekodunmi, àgbà osere míì to dagbere faye nínú oṣù Kínní, ọdun 2017 ni iyawo àgbà osere yii.

Boy Alinco

Oríṣun àwòrán, Gboah TV

Bayo Bankole

Orúkọ ori itage rẹ ni Boy Alinco tí ọ̀pọ̀ eniyan si mọ ọ bí ẹni n mọ owó nigba to máa n kopa ninu fiimu agbelewo. Alinco ti ko lọ si orileede Amẹrika bayii to si ti gbe nibẹ fun ọpọlọpọ ọdun.

Àkọlé fídíò, Gbajugbaja oṣere tiata, Bolaji Amusan fi hann wa bo se láyà to lori ètò ṣé o láyà.

Lara awọn fiimu to ti kopa ni Owo Blow, Eda àti sinima agbelewo to fi gbajumọ ju, Papa Ajasco.

Bayo Bankole wa ni Amẹrika pẹlu idile rẹ.

Bukky Wright

Oríṣun àwòrán, Bukky Wright

Bukky Wright

Gbajugbaja Òṣerébìnrin ni Bukky Wright ti ọpọ si maa n fi orúkọ rẹ gangan pee bo ti wu ko ni oríṣiríṣi orúkọ orí itage to.

Àkọlé fídíò, Ebun Oloyede Olaiya Igwe sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí lásìkò àìsàn kídìnrín tó yọ ọ́ lẹ́nu

Osere to tun ń mú owó pọ mọ ère orí itage ni Bukky to si gbajumọ fún kikopa nínú àwọn fiimu ti yoo ti sọkun gidi ti awọn eeyan maa n ní pe o mọ bi wọn ṣe n ba ẹnu ẹkùn gidi gan.

Oserebìnrin yii náà ko si lorileede Naijiria mọ, atohun àti idile rẹ lo ti n gbe ni òkè okun báyìí.

Osere Sango

Oríṣun àwòrán, Gboah TV

Wale Adebayo

Wale Adebayo ni osere ti ẹ mọ si Sango nitori ipa to pataki julọ, Sango to ko ninu fíìmù Sango.

O jẹ ọkan lara awọn eekan osere to di gbajumọ to si mú ki awọn olólùfẹ́ fiimu Yoruba gbadun pọpọṣinṣin awọn sinima to jade ni 1990s fiimu Sango to si kopa ninu rẹ lo polongo rẹ faye.

Àkọlé fídíò, Adepoju Abdulsalamm ẹni ọdun 18 tó n fi kẹ̀kẹ́ dára fi kiri ẹja tó fi n tà wàràwàrà

Pẹlu bo ṣe wá lokiki to nigba naa, Wale Adebayo fi orileede Naijiria silẹ lọ si United States.

Nínú iforowanilenuwo kan pẹlu iwe iroyin Punch, Wale jẹ ko di mimọ pe kii ṣe pe o wu òun lati jápaa kuro ni Naijiria, àmọ́ ìṣòro to n ba orileede Naijiria finra lo mu ki oun kuro lọ wa ọna ati tọju ẹbi oun.

Opeyemi Aiyeola

Oríṣun àwòrán, Opeyemi Aiyeola

Opeyemi Aiyeola

Òṣerébinrin yìí naa ko farasin rara lagbo osere fiimu Yoruba títí di bí a ṣe ń kọ ìròyìn yìí.

Àkọlé fídíò, Africa Eye wádii àwọn tó wà nídìí ìgbésùmọ̀mí ni Mozambique

Opeyemi Aiyeola jẹ osere to di gbajumọ laarin awọn akẹgbẹ́ rẹ gẹgẹ bi ọdọ nígbà to n gbe ni Naijiria.

Ẹwẹ, pẹlu awọn ọrọ, àwòrán, àtàwọn fídíò to máa ń gbé jáde, àfihàn gedegbe wa pé ìlú Òyìnbó ni òun àti ebi rẹ ń gbé báyìí bo tilẹ̀ jẹ pe bo ba ni ère láti kopa ninu rẹ yoo darapo mọ wọn.

Pefuele

Oríṣun àwòrán, Gboah TV

Razaq Ajao

Lasiko ti oju osere yii maa n jade nínú sinima, orúkọ ti wọn mọ ọ si gan ni Pefuele.

Odu ni Pefuele kii ṣe aimọ fun oloko ni nkan bíi 1990s yẹn ko to di pe oun naa ko kuro ni Naijiria lọ si U.S.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Adarí FIN

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ti a gbọ́, láti ọdun 2003 ni Pefuele ti kuro lorileede Naijiria to si lọ síbi tàbí sọ́hùn-ún nígbà miran laarin Naijiria ati Amẹrika.

Iroyin kan tilẹ ni ni orilẹ̀ede to wa, o ti n ṣiṣẹ nọọsi bayii eyi ti ọpọ gbagbọ pe o n mu owo wọle gidi gan.

Àkọlé fídíò, Ẹni tó bá ni kí n fi iṣẹ́ kòkò mímọ sílẹ̀, mi ò lè fẹ́ẹ láéláé - Adekemi Àgùnbánirọ̀