Mouth odour: Ọ̀nà márùn-ún tí o lè gbà láti ṣẹ́gun ẹnu rírùn àti ìṣòrò eyín

Oríṣun àwòrán, JOEL SAGET
Láti igba ti olukuluku ti wa ni ọmọde lo ti n gbọ pe ẹẹmeeji lojumọ lo yẹ ki eniyan maa fọ eyin.
Ṣugbọn awọn onimọ iṣegun ti ṣalaye ọna ti o le gba gbogun ti isoro eyin didun ati ẹnu rirun, erigi to n ṣẹjẹ ati awọn inira eyin miiran.
Gẹgẹ bi wọn se sọ awọn koko yii ni lati sọna bi eyin awọn eniyan ko se ni maa ra ti yoo si fa iṣoro eyin didun.
- Àwọn Òṣèré fíìmù Yorùbá tẹ́ ò ro tó tí jápaa lọ ìlú Òyìnbó rèé
- Kéére o! Ojú òpó WhatsApp kò ní ṣiṣẹ́ mọ́ lórí àwọn ẹ̀rọ ìléwọ́ yìí láti Nov 1
- Agbẹnusọ àjọ EFCC Wilson Uwujaren ti ṣàlàyé nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀gá àjọ náà lósàn ọjọ́bọ
- Ìjọba Burundi yóò kọ̀wé lọ rọ́kún nílé fún àwọn tó dípò ìjọba mú tí wọ́n sì tún ń yàn àlè
- Ilé alájà méjì dàwó nílùú Abuja, èèyàn kan kú, orí kó àwọn míì yọ
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn ajínigbé níbi tí wọ́n ti ń gba owó ìtúsílẹ̀ ẹni tí wọ́n jígbé
Máa ṣan ẹnu rẹ nu ni kete ti o ba fi ọṣẹ fọyin tan
Ajọ eto ilera lorilede UK (NHS) gba awọn eniyan niyanju pe ti o ba ti fọ ẹnu tan, o le tu ọṣẹ ifọyin rẹ danu ṣugbọn ma ṣan ẹnu rẹ ni kiakia.
Idi eyi ni pe ti o ba ṣan yoo ṣan eroja Floride ti o yé ki o pa kokoro to wa ninu eyin rẹ danu.
Ma fi igi itayin yọ ounjẹ to ba ha sinu eyin rẹ kuro
NHS fi kun imọran rẹ pe, ki enikẹni ma ṣe maa lo igi itayin yọ ounjẹ to ba ha sinu eyin kuro.
Idi eyi ni pe, o le gun erigi ti yoo di egbo ti yoo si fa aisan sinu eyin naa.
Imọran ti wọn fi kun un ni pe ki eniyan lo okun tinrin ti o ba ni eji laarin awọn eyin rẹ lati yọohunkohun to ba ha sibẹ kuro.

Oríṣun àwòrán, AFP
Fi okun tinrin yọ idọti lati mu adinku ba ẹnu rirun
Eyi ni ti o ba fi okun tabi owu tinrin si aarin eyin rẹ lati yọ idọti to ba wa nibẹ kuro.
O dara ki eniyan maa lo okun lati yọ idọti kuro ninu eyin rẹ,n itori ajọ NHS sọ pe ti eniyan ba n se eyi deede yoo mu adinku ba awọn aisan to maa n ṣe eyin.
Wọn ni eyi ni yoo yọ gbogbo idọti to wa ninu eyin.
Ma lo omi ifọyin lẹyin ti o ba ti fi ọṣẹ fọyin tan
NHS fi imọran sita pe omi ifọyin lẹyin ti o ba ti fọnu tan, o le ṣe isẹ ti omi naa yoo se lati san gbogbo ọṣẹ ti o fi fọnu kuro lẹnu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O yẹ ki obi maa ba ọmọ fọ ẹnu rẹ titi di ọdun meje
Lakotan NHS sọ pe o ṣe pataki lati maa ba ọmọ fọnu titi yoo fi pe ọmọ ọdun meje.
Imọran naa ni pe, ti o ko ba le ran lọwọ o yẹ ki o moju too bi o se n fọọ titi ti yoo fi pe ọdun meje
- Èkó àti Rivers nìkan kọ, wo àwọn ìpínlẹ̀ Gúúsù-Gúúsù mi tó ṣetán láti lọ sílé ẹjọ́ gíga jùlọ lórí VAT
- À ò ni gbárùkù tì gbogbo ẹ̀yin gómìnà ìhà Gúúsù tó bá tako kíkẹ́ràn jẹ̀ - Miyetti Allah
- Nkechi Blessing sọ̀rọ̀ nípa ikú ìyá rẹ̀, ó tún tú àṣírí kàbìtì nípa ìhùwàsí ara rẹ̀ táyé kò mọ̀
- Kìí ṣe pé ìjọba ń fi ọwọ́ jẹ́jẹ́ mú àwọn jàndùkú o - Lai Mohammed
- Irọ́ ni, kò sóhun tó jọ pé a fẹ́ gbẹ́sẹ̀ lé owó 'domiciliary account' àwọn ènìyàn Nàìjíríà- CBN



















