Èèyan kan dágbére fáyé lẹ́yìn tí ilé alájà méjì dàwó nílùú Abuja

Ile to wo

Oríṣun àwòrán, The Nation

Abala kan lara ile alaja meji kan ti dawo niluu Abuja nibi ti eeyan kan lara awọn to wa ninu ile naa ti dagbare faye.

Ile to dawo ọhun wa lẹyin awọn ilegbe igbalode CITEC Estate to wa ni opopona papakọ ofurufu ni opopona Jabi.

Adari agba ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri niluu Abuja, FEMA, Alhaji Abbas Idris sọ pe ile naa dawo ni nnkan bii aago mọkanla aarọ Ọjọru.

Idris sọ fun awọn akọroyin pe wọn ti gbe oku ẹni to ba iṣẹlẹ naa lọ lọ si ile igbokusi to wa nile iwosan ijọba apapọ, FMC, ni Jabi.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, apakan ile alaja meji naa lo dawo laarọ Ọjọru.

O ni "Ẹnikan ku nibi iṣẹlẹ naa, a si ti gbe oku rẹ lọ sile igbokupamọsi to wa ni FMC, Jabi."

"Nnkan bii aago mọkanla aarọ oni ni ile ọhun dawo ṣugbọn wọn ti doola awọn eeyan to wa ninu rẹ lati dena ijamba mii."

O pari ọrọ rẹ pe iwadii ti bẹrẹ lori ohun to jẹ ki ile naa dawo awọn yoo si fi atẹjade ṣọwọ si awọn akọroyin lori abajade iwadii awọn laipẹ.