Kaduna kidnap: Akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà mórí bọ́ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army
Ọpẹ o! Awọn akẹkọọ mẹfa ti wọn jigbe ni ileewe girama ni Gwagwada, nipinlẹ Kaduna ti gba ominira bayii.
Ileeṣẹ ologun orilẹ-ede Naijiria lo fọrọ naa lede ninu atẹjade kan ti wọn fi sita.
Ileesẹ ologun ṣalaye pe ọwọ ti tẹ awọn ajinigbe ọhun, ati pe awọn tun ti gba oriṣiiriṣii ohun ija lọwọ wọn.
- Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn òfegè ni pé Buhari fẹ fẹ́ Sadiya, síbẹ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ń ṣètò ìyàwò náà lórí ayélujára
- Olùkọ́ àgbà tó fipá bá ọmọ ọdún 13 lò yóò fojú ba ilé ẹjọ́ ni Benue
- Ẹṣẹ wo ni Ambode ṣẹ̀ tí ilé aṣòfin Eko fẹ́ fí ọlọ́pàá mú u?
- Dino Melaye fìdí rẹmi, Smart borí nílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn
- Ìjọba, ẹ yé fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn dun ọmọ Nàìjíríà mọ́- SERAP
Ileeṣẹ ologun ni awọn akẹkọọ naa n lọ si ileewe nigba ti awọn ajinigbe ọun gbe wọn lọ.
Lẹyin ija ajaku akata laarin awọn ologun atawọn ajinigbe ọun nibi ti ọkan ninu awọn ajinigbe naa ti farapa.

Eleyi ni igba kẹta ti iṣẹlẹ ijinigbe yoo waye nile iwe laarin ọsẹ meji ni Kaduna.
Koda iṣẹlẹ ijinigbe kan tun ṣẹlẹ l'Ọjọbọ nibi ti wọn ti ji ọga ileewe kan lọ.
- 'Títẹ àwọn afipábánilopọ̀ lọ́dàá kọ́ ni ọ̀nà àbáyọ sí ìwà ìfipábánilopọ̀'
- Jessica Nabongo ni obìnrin àkọkọ nílẹ Adúláwọ tó rin gbogbo àgbáyé.
- Ilé aṣọ̀fin Nàìjíríà ń gbèrò ẹ̀wọ̀n f'áwọn olùkọ̀ tó bá dẹnu ìfẹ́ kọ akẹ́kọ̀bìnrin
- Ìṣòro Nàíjíríà kọjá kí Bobrisky àtàwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dá ní ilé ìgbọ̀nsẹ̀ lọ́tọ̀"
Ileeṣẹ ologun sọ pe awọn akẹkọọ fẹsẹ fẹ ni kete tawọn ajinigbe de ileewe wọn ti wọn si ji ọga ileewe naa lọ.
Opọ eyan Naijiria lo ti gboriyin fawọn ọmọ ogun to doola awọn akẹkọọ naa pe iṣẹ takuntakun ni wọn ṣe.
A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin laipẹ.
















