Yoruba Culture: Ìran Yorùbá: Àṣà ju àṣà lọ!

Wo díẹ̀ lára àwọn àṣà àti ìṣe tó ya Yorùbá sọ́tọ̀ nínú gbogbo àgbáyé!

ọkolaya

Oríṣun àwòrán, @Kla

Àkọlé àwòrán, Ìdána ló ń ṣaaju igbeyawo nilẹ Yoruba. Aṣa igbeyawo nilẹ Oodua kii ṣe laarin ọkọ ataya nikan bikoṣe laarin gbogbo ẹbi mejeeji. Ifojusode, iwadii, alarina, iya gbọ, baba gbọ, àti mọmi-ki-n-mọ-ẹ wa lara igbesẹ inu igbeyawo Yoruba
lokolaya

Oríṣun àwòrán, @ore

Àkọlé àwòrán, Imura lọkọlaya maa n gbe aṣa Yoruba ga lọjọ ti ẹbi ọkọ ba ko awọn ẹru idana wa bii iṣu, eso, ẹja, epo, iyọ, owo orí, ireke, aadun, oyin, ṣuga ati bẹẹ bẹẹ lọ. Gbogbo eewọ idile ati ounjẹ wọn ni ẹbi ọkọ a ṣalaye fun iyawo tuntun ki wọn to wa bu omi tutu sii lẹsẹ wọle ki ẹsẹ ọsingin le dara lọọdẹ ọkọ rẹ.
oba ti wọn n ki

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Aṣa ìkíni ṣe pataki pupọ nilẹ Yoruba. Omọkunrin a dọbalẹ; ọmọbinrin a kunlẹ ki awọn to juu lọ. Gbogbo igba ati asiko ni iran Yoruba ni ikini fun ati pe gbogbo iṣẹlẹ naa ni wọn ni ikini fun ẹni ti ọrọ kan.
ilu

Oríṣun àwòrán, @drummer

Àkọlé àwòrán, Ilu ṣe pataki nilẹ Yoruba, a fi n ṣe ikede, a fi n yin awọn oriṣa ati Adẹdaa, oriṣa kọọkan lo ni ilu tirẹ bii Ṣango to ni bata. Oriṣirisi ilu ti Yoruba ni pọ bii: omele, iya ilu, gangan, bata ati bẹẹ bẹẹ lọ.
eegun

Oríṣun àwòrán, @danaf

Àkọlé àwòrán, Ajurawalọ... Yoruba ni agbara, oogun ati iṣẹṣe lati ọwọ awọn baba nla wa. Eeegun Danafunjo ree lati Oyo to jẹ pe ina lo fi n ṣagbara ni eyi ti ko si paa lara si iyalẹnu gbogbo ero.
ẹgbẹ

Oríṣun àwòrán, @ojude oba

Àkọlé àwòrán, Lara awọn ọdun ilẹ Yoruba ni ọdun ojude Oba to maa n waye ni ọjọ keji Ileya nilu Ijẹbu Ode nipinlẹ Ogun. Ninu ọdun yii ni aṣọ ti maa n pe aṣọ ran niṣẹ ti awọn eeyan maa n foju lounjẹ lori awọn nkan to n lo igba lọwọ
isinku

Oríṣun àwòrán, @abe

Àkọlé àwòrán, Àṣà isinku agba naa jẹ ọkan lara ayẹyẹ ti Yoruba ka si pupọ pe ọmọ rere a gbẹyin gbogbo wa ati pe ẹni ti ọmọ ba sin lo bimọ nilẹ Yoruba. Gbogbo ebi ara ati ọrẹ oloogbe lo maa fọwọsowọpọ wa ṣe ẹyẹ ikẹyin fun arugbo to re ibi agba n re
isinku

Oríṣun àwòrán, @abe

Àkọlé àwòrán, Ko si ẹni to maa n fẹ ki arugbo to ba wulo ninu ile rẹ o ku, ọpọ igba ni awọn eniyan maa n sunkun lori iru iku to ba pa ẹni kan. Opo lo maa n gbadura ki onikaluku fọwọ rọri ku lai kuku inira tabi ti ijamba.
ẹyọ

Oríṣun àwòrán, @Lagos

Àkọlé àwòrán, Ẹyọ jẹ ọdun kan pataki ni ipinlẹ Eko nibi ti awọn ọmọ isalẹ Eko ti maa n fidunnu wọn si alaṣọ aala funfun gbooo kanlẹ. Igbagbọ wọn nipe Adimu oriṣa maa ko iku, arun, aṣeeri ati idaamu lọ kuro nilu Eko.
afingba

Oríṣun àwòrán, @kwas

Àkọlé àwòrán, Igba finfin wa lara iṣẹ ajogunba awọn ọmọ Oodua. Iran Yoruba kii ṣe ọlẹ rara, bẹẹ bi Onirese ko ba fingba mọ ni..ìṣẹ ọwọ awọn baba nla wa bii ẹmu dida, irun didi, apẹja, ọdẹ ṣiṣe, irin rirọ ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn fi n ri owo
iyan

Oríṣun àwòrán, @Jeromi

Àkọlé àwòrán, Iyan lounjẹ, ọka loogun, airi rara la n jẹkọ, ki ẹnu ma dilẹ ni ti guguru ni igbagbọ awọn Yoruba. Aṣa irufẹ ounjẹ wa jẹ Yoruba logun pupọ. Ounjẹ wa maa n ṣaraloore ti o si maa n fun ni lokun ati agbara. Obẹ oṣiki, ẹfọ riro, ẹgusi, ila asepọ ati bẹẹ bẹẹ lọ lo maa n kọwọ rin pẹlu iyan Oba ounjẹ.
joloofu

Oríṣun àwòrán, @Ajoku

Àkọlé àwòrán, Irẹsi alasepọ Jọlọọfu lounjẹ to tun n gbayi ni gbogbo inawo awọn Yoruba lasiko yii. ẹran, ẹja, móinmọin, dodo, igbin, adiyẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ lo maa n tẹlẹ jọọọfu rin lode ariya. Tọmọde tagba lo n jẹẹ ninu ile, nibi ase ati nibi gbogbo. ọfada ayamase ati oriṣi irẹsi miran ni Yoruba n se lode.
awọn onijo

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Iran Yoruba maa n ba ara wọn ṣajọyọ papọ, wọn gbagbọ pe igi kan ko le da igbo ṣe. Ikomọjade, iṣile, ifinjoye, isinku agba abbl ni awọn inawo ti gbogbo ẹbi, ara, ọrẹ jọ maa n dawọ idunnu si. Koda wọn a tun jọ mu aṣọ ankoo, ẹgbẹjọda papọ bii tolobinrin ile.
Lalude

Oríṣun àwòrán, @odunlade

Àkọlé àwòrán, Ere itage, fiimu agbelewo, sinima ati awọn ọna idanilaraya miran ni Yoruba ma n ṣe ki wọn fi pa ironu mọ. Awọn agba oṣere apanilẹrin atawọn to n ṣafihan aṣa, oogun, agbara ati iṣe awọn akọni Yoruba naa tun maa n kọni lẹkọ lori amohunmaworan.
olorin

Oríṣun àwòrán, @bola are

Àkọlé àwòrán, Oriṣirisi orin ni Yoruba maa n gbadun bii juju, apala, orin ẹmi, fuji, ṣakara abbl. Awọn olorin bii Bola Arẹ, King Sunny Ade, Obey Commander, Oloogbe Wasiu Ayinde, Baba lẹgba atawọn miran lo maa n mu inu awọn eeyan dun ti onikaluku a si fijo rasẹ paapaa nibi inawo
ọde
Àkọlé àwòrán, Oriṣiriṣi owe, aṣamọ, akanlo ede ati akoonu to kun fun ero ọgbọn ati girama to pe ni Yoruba fi maa n ba ara wọn sọrọ. Yoruba a maa fi ẹnu, oju, imu ati ọwọ tabi ẹya ara mii bi ẹsẹ ba ara wọn sọrọ to jẹ pe ajoji ko ni mọ ohun ti wọn n sọ. Koda owe to jẹ ẹṣin ọrọ naa wa nibẹ
ọọni
Àkọlé àwòrán, Awọn ori ade ile Oodua ko ṣee fọwọ rọ sẹyin rara ninu gbigbe asa ati iṣe Yoruba ga. Ooni ti Ile Ifẹ nibi ojumọ gbe mọ wa sile aye ree to gunwa lori itẹ awọn baba nla rẹ. Oba Yoruba jẹ igbakeji oriṣa to jẹ aṣegbe ni ohun ti wọn ba ṣe pẹlu ibẹru Olorun.
Dolapo n kunle ki Buhari

Oríṣun àwòrán, @FemiAdesina

Àkọlé àwòrán, ọmọbinrin Yoruba to gbẹkọ ilé maa n kunle ki agbalagba ni. Dolapo aya Igbakeji aarẹ Naijiria, Osinbajo rre, to n kunle ki aarẹ Buhari nibi eto ijọba kan. Aṣa ikini nilẹ Yoruba ṣafihan ibọwọfagba to ṣe koko ninu aṣa Yoruba lainii fi ṣe ipo, tabi ipele igbega ti eniyan wa.
obinrin to n jo

Oríṣun àwòrán, @asoo

Àkọlé àwòrán, Ṣẹkẹrẹ ati aago wa ninu ohun eelo orin ti Yoruba fi maa n fimoore han si Olorun, Oriṣa, olowo ori wọn ati ẹnikẹni tinu wọn ba dun si. Awọn obinrin Yoruba maa n jo tarugbo tomidan.
ọkunrin

Oríṣun àwòrán, @ife

Àkọlé àwòrán, Awọn Olobatala naa n ṣọdun wọn lasiko wọn. Asiko ọdun wa fun Oṣun Oṣogbo, ọdun Sango ni Oyo, ọdun Obalufọn, Olọjọ, Olóro ati bẹẹ bẹẹ lọ kaakiri ilẹ Oodua lo tun n ṣafihan asa ẹsin abalaye wa.