Ebeano Supermarket Abuja Fire: Ohun tí a mọ̀ nípa Ọjà Ebeano tó jóná

Oríṣun àwòrán, Ebeano Supermarket /Others
Fidio bi ina ṣe jọ ile itaja Ebeano Supermarket ni ilu Abuja ni o ti kaakiri oju opo ayelujara, lẹyin ọsẹ kan ti iṣẹlẹ naa waye.
Fidio naa ni ẹrọ CCTV ti awọn to ni ile itaja naa fi si inu ṣọọbu wọn ko to di wi pe o jona raurau gbe jade lẹyin ti iṣẹlẹ naa ṣẹ.
Fidio naa safihan bi ọmọdebinrin kekere kan ṣe lọ si ẹka ibi ti wọn gbe (cylinder) afẹfẹ gaasi si ninu ile itaja naa.
- Ṣé lóòtọ́ ni ọlọ́pàá MOPOL yìnbọn fún ọlọ́kadà l'Osogbo?
- Olùwọ́de 47 nínú àwọn tí ọlọ́pàá kó ní ìwọ́de Yoruba Nation ti gba ìtúsílẹ̀ láhámọ́ ọlọ́pàá
- Gbogbo ẹ̀yin Mùsùlùmí Yorùbá tí ẹ ń pè fún Yorùbá Nation ẹ lọ tún èrò yín pa - Ishaq Akintola
- Wọ́n ti fi ẹ̀sùn míì kan Sunday Igboho ní ìlú Benin! - Agbẹ́jọ́rò Igboho
- Gbogbo ẹ̀yin Mùsùlùmí Yorùbá tí ẹ ń pè fún Yorùbá Nation ẹ lọ tún èrò yín pa - Ishaq Akintola
Ọmọ kekere naa lo ẹrọ ti wọn fi n ta ina ti o si gbe pamọ si , o duro diẹ ni ibi cylinder naa lati jẹ ki ina ran ko to di wi pe o kuro nibẹ ki ina to sọ.
Iroyin gbe e pe ileeṣẹ ọlọpaa ti fi panpẹ mu ọmọ kekere ti wọn ni fidio CCTV safihan pe o ṣeeṣe ko jo ile itaja naa.
Amọ, awọn alakoso ile itaja Ebeano Supermarket ko i tii fi atẹjade kankan sita lati bi ọsẹ kan ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Iroyin ina to jo ile itaja naa bẹrẹ lati alẹ Ọjọ Abamẹta to si jo di Ọjọ Aiku, lẹyin ti igbiyanju awọn panapana jasi pabo.
Gbogbo ọja to wa ninu ile itaja naa to le ni ẹgbẹgbẹrun miliọnu naira lo ba iṣẹlẹ ina to jo naa lọ.
Amọ,kii ṣe igba akọkọ ti ile itaja naa yoo jona ni yii, lẹyin ti ẹka ile itaja naa to wa ni agbegbe Lekki, nipinlẹ Eko jona, ti ko si si ẹni to mọ ohun to fa ina naa.


















