LASTMA: Ìwà tí LASTMA àtàwọn ọlọ́pàá hù tí ìyáwó mi fi pàdánú oyún inú rẹ̀ - Onyemaechi

Ìyáwó mí ń kígbé ìrora, ó sì pàdánú oyún inú rẹ̀ nítorí aṣemáṣe òsìsẹ́ LASTMA àti ọlọ́pàá-Onyemaechi

Ọkunrin kan tí ó n jẹ Eze Onyemaechi ati iyawo rẹ, ti fi ẹsun kan pe oṣiṣẹ LASTMA meji ati ọlọpaa meji ni agbegbe Egbeda nilu Eko lo se okunfa pipadanu oyun inu iyawo oun.

Ọkunrin yii ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu ile iṣẹ Punch lo ti ṣalaye pe, ní kete ti oun ati iyawo oun kuro nile ni agbegbe ikọtun ní ọjọ naa ni iyawo oun bẹrẹ si ni ṣe akiyesi inu rirun.

Onyemaechi ṣalaye pe iyawo oun rọ oun latu dujro naa ki on mọ nnkan ti o ṣẹlẹ, asiko yii lo sare wọ ile ounjẹ igbalode kan to wa ni agbegbe ibi ti wọn duro si.

Àkọlé fídíò, Japan: Ẹ wo arákúnrín tó ń ta ilé àwọn òkú fún àwọn tó ní ìfẹ́ sí

Lẹyin to lọ ṣe ayẹwo ara rẹ nile igbọnsẹ ile ounjẹ naa lo pada de lati sọ fun un pe ẹjẹ ni oun n ri, ati pe ile iwosan ni o ku.

Ọkunrin naa ni bi awọn ṣe kuro ti awọn bọ si titi pada ni ina da awọn duro, lasiko ti awọn si n duro ki ina yii gba wọn laaye lati lọ ni oun ṣaadede ri awọn oṣiṣẹ LASTMA meji ati ọlọpaa meji, ti ọkan ninu awọn LASTMA naa si n fi foonu rẹ ya aworan.

"Nigba ti wọn sun mọ mi ni mo bere pe se ko si, ni wọ́n wa sọ fun mi pe iyawo mi ko lo ọja inu ọkọ (Seatbelt) ".

Ìyáwó mí ń ké ìrora, ó sì pàdánú oyún inú rẹ̀ nítorí aṣemáṣe òsìsẹ́ LASTMA àti ọlọ́pàá-Onyemaechi

Oríṣun àwòrán, Punch

Àkọlé àwòrán, Oṣiṣẹ LASTMA to ṣiṣẹ lọ́jọ́ naa

"Mo ṣalaye fun wọn pe, ara n nii lọwọ koda ẹjẹ n da lara rẹ a si nilo lati lọ si ile iwosan bayii, sugbọn ki n to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ osiṣẹ LASTMA kan ti ko sinu ọkọ mi o si ti gbe iyawo mi lọ

Arakunrin naa ni gbogbo ẹbẹ ti oun bẹ lati jẹ ki oun kọkọ gbe iyawọ oun lọ si ile iwosan naa, pabo lo ja si nitori pe ọkan ninu wọn sọ fun oun pe nigba ti awọ ba ṣetan pẹlu rẹ lo e maa lọ si ibi to ba fẹ.

Bawo ni owo, iwe Irina ilẹ okere ati iwe irina ọkọ ṣe poora?

Onyemaechi tẹsiwaju pe lẹyin bii wakati meji, ti awọn ti wa lori ọrọ yii, ti iyawo oun si n ku lọ pẹlu irora ni wọn sọ pe, ki oun san ẹgbẹ̀run marundinlogoji Naira.

O ní oun rọ wọn lati gba ẹgbẹrun marun ṣugbọn wọn ni ẹgbẹrun mẹwaa ni jalẹ, ati pe ni asiko yii wọn ti pin ara wọn, wọn si ni ki oun lọ san owo lọdọ ẹnikan loju irin.

Lasiko yii gẹgẹ bi o ṣe sọ ni oun wọ inu mọto ti oun si gba kọkọrọ lọwọ iyawo oun lati gbe lọ si ile iwosan, ṣugbọn ni asiko yii, iwe irina ọkọ àti ti ilẹ okere ni oun ni wọn ti ko.

Ọgbẹni Onyemaechi ni oun bere lọwọ wọn pe wọn si sọ fun oun pe, ki oun wa si ile iṣẹ wọn lati wa gba, asiko yii gan si ni awọn yoo sọ iye ti yoo san lati gba.

Bakan naa lo ni ẹgbẹrun lọna ààdọ́jọ ti oun ko sinu apo iwe ninu moto naa ti poora lẹyin ti LASTMA to wa ọkọ gbe ọkọ kalẹ tan

O ní titi di asiko yii, oun ko ti ri "Passport" oun ati iwe irina ọkọ oun gba lọwọ ọlọpaa.

Kilo pada ṣẹlẹ si iyawo?

Ọkunrin òun ni aṣẹyinwa, aṣẹyinbọ, oun sare gbe iyawo oun lọ si ile iwosan sugbọn ẹpa ko boro mọ.

O fi kun pe ko si iru ọrọ ti dokita ko sọ fun oun tan lori iru ẹjẹ to ti sofo lara iyawo oun ti oun ko si gbe wa si ile iwosan

Lẹyin gbogbo ayẹwo, dokita sọ pe wọn ti pada nu ọmọ naa, ati pe to ba jẹ pe awọn tete gbe wa ni, boya wọn o ba le doola rẹ.

Onyemaechi wa ke si ara ilu ati ijọba lati se idajọ ododo ki wọn si ba oun gba gbogbo iwe ọkọ, ati iwe irin ilẹ okere to wa lọwọ wọn nítori fisa wa lori rẹ.

Ìyáwó mí ń ké ìrora, ó sì pàdánú oyún inú rẹ̀ nítorí aṣemáṣe òsìsẹ́ LASTMA àti ọlọ́pàá-Onyemaechi

Oríṣun àwòrán, Punch

Àkọlé àwòrán, Oludari ajọ LASTMA

Kini ajọ LASTMA sọ?

Ninu ọrọ ọga ajọ LASTMA Jide Oduyoye lori ọrọ naa lo ti ṣalaye pe lootọ ni arakunrin oun san ẹgbẹrun mẹwaa Nairia ti wọ ni ki o san, sugbọn ko si asiko kankan ti iyawo rẹ kuro ninu ọkọ lasiko ti LASTMA n wa ọkọ naa

Ọgbẹni Oduyoye fi kun pe gbogbo bi wọn se n fa ọrọ naa ni ọkunrin naa n pe iyawo rẹ pe ki o moju to owo ti oun ko si abẹ moto, nitori naa iyawo rẹ mọ.

Bakan naa lo sọ pe inu apo iwe naa lo ti mu ẹgbẹrun mẹwaa to fun awọn osiksẹ LASTMA, asiko yii lo yẹ ki o ti yẹwo boya owo rẹ pe.

O tun sal,aye pe ko si nnkan ti ẹsẹ oju popo niise pẹlu gbigba iwe irina ile okere lọwọ ẹnikẹni, ati pe se iwe irina ọkọ ti oun lo ṣe ayederu ni tabi gidi.

Àwọn ibeere miiran ti ọga LASTMA n bere ni pe: kini idi ti iyawo rẹ ko fi ni mọ pe ẹniyan kan n mu owo ọkọ rẹ lasiko ti o wa ninu mọtọ?

Bawo ni ẹniyan yoo se ko ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira sinu apo iwe ni asiko ti a wa yii?

Bawo ni awọn osisẹ LASTMA ati ọlọpaa ko se ri ẹjẹ to n jade lara iyawo rẹ ti wọn yoo fi mọ pe lootọ ni o nla iru ipo yẹ kọja?

Bawo ni ọkọ rẹ se san owo ile iwosan niwọn igba to jẹ pe wọn ti ji owo lọ ninu mọto rẹ, ti o si jẹ pe kii ṣe ile iwosan to n lo tẹlẹ ni wọn ti lọ gba itọju?

Ọga oun wa fi kun pe lootọ awọn ni ofin ti awọn n tẹle lẹnu iṣẹ ijọba, àwọn yoo si ba oṣiṣẹ ti ẹbi ọrọ naa ja le lori wi nitori oṣiṣẹ kan pere lo yẹ ki o wa ni ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ.

O ni igbese meji ni wọn gbe ti ko si tọna lati gbe, nitori naa fun idi eyi, ijiya wa fun wọn.

Oduyoye ṣalaye pe, niwọn igba ti ọrọ ole jija ti wọ, ọrọ naa yoo di ti ọlọpaa, ko si ni ọwọ ajọ LASTMA mọ, Onyemaechi yoo nilo lati mu ẹjo naa lọ si ile ọlọpaa.