Clarion Chukwura goes topless: Ẹ̀mí mímọ́ ló ní kí n múra lài wọ bùbá láti ṣe ọjọ́ ìbí mi torí pé ...

Clarion Chukwura

Oríṣun àwòrán, Clarion Chukwura/Instagram

Gbajumọ agba oṣerebinrin to n ṣe fiimu Yoruba to tun n ṣe ti Igbo ati ede Gẹẹsi, Clarion Chukwura ti ni ẹmi mimọ lo dari oun gẹgẹ bo ṣe yan aya ati ẹyin rẹ si ihoho ninu fọto ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.

Loju opo ara rẹ, Clarion to pe ẹni ọdun mẹtadinlọgọta lọjọ kẹrinlelogun oṣu keje ṣafihan awọn fọto naa to si kọ ewi iyalẹnu lee lori.

O fi akoko naa bi owe bi owe ṣalaye bi nkan ṣe ti ri fun un tẹlẹ latẹyin wa amọ o kọkọ sọ nipa Naijiria ati awọn orilẹede Afirika kan.

"Ọmọ Naijiria ni mi, pẹlu oniruuru aṣa ati ẹya to ṣara jọ sibi. Nigba mii, mo maa n da bi ẹni to daru lọkan si gbogbo awọn to ku lagbaaye.

Amọ pẹlu ọpọlọpọ ohun ti mo ni bo tilẹ ti di apati tabi ti ko ba igba mu mọ sibẹ, ọpọ ibukun ti mo ni n fa oju wọn mọ mi lara".

Clarion Chukwura

Oríṣun àwòrán, Clarion Chukwura

O tun ṣafiwe bi wọn ṣe maa n pe orilẹede ni akọni ilẹ Afirika, ilẹ wura to si n jagun ṣẹgun.

Amọ nibayii, to wa lori ẹsẹ to ti yẹ, o ni Naijiria ko lee kan. Gbogbo ohun ti awọn orilẹede bii Cameroon, Ghana, Togo, Lebanon, Niger ati South Africa ti gbe ṣe ninu Naijiria.

Yala gbigbe nibẹ tabi ṣiṣe iṣẹ ati owo atawọn to jere ominira latara Naijiria ti awọn mii si n ja a lole to bẹẹ ti ko fi niyi mọ nile ati loju araye, "sibẹ awọn ọmọ mi lọkunrin ati lobinrin ti kọ agbaye!".

Gbogbo irora ati ilakọja yii naa ni Clarion Chukwura ni o sọ Naijiria di ọkunrin takuntakun.

Àkọlé fídíò, Japan: Ẹ wo arákúnrín tó ń ta ilé àwọn òkú fún àwọn tó ní ìfẹ́ sí

Idi ti Clarion Chukwura fi wa nihoho ninu fọto rẹ

Clarion Chukwura

Oríṣun àwòrán, Clarion Chukwura

Nitori ipo ti Naijira wa, Clarion ni Naijiria n bere fun aanu, ọ̀wọ̀ ati ireti lati da aṣọ bo o ati lati da ogo rẹ pada ki o lee pada sọ pe oun ni okun ati agbara. Eyi lo mu ko bọ aṣọ silẹ lati ṣafihan ipo ti Naijiria wa daadaa.

"Pẹlu ibinujẹ o ti wa han gbangba si mi pe mo ti n wo lulẹ, mo ti ja si ihoho mo si n bẹbẹ fun ọ̀wọ̀, ... ki wọn lee pada pe mi ni akọni ilẹ Afirika ti mo jẹ toripe Ọlọrun wa ninu mi".

"Orukọ mi ni Clarion Chukwura, oni ni ọjọ ibi mi, ọmọ Naijiria ni mi, mo si sọ pe mi o ṣee kan. Nipa oreọfẹ, maa dide. Ogo ni fun Ọlọrun. O ṣeun Oluwa.

Ìmísí mi wá látọwọ́: Ẹmi Mimọ