Niger school kidnap: Àwọn jàndùkù ajínigbé mú bábá tó gbé owó ìtúsílẹ̀ lọ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jígbé mọ́lẹ̀

Oríṣun àwòrán, Reuters
Eemọ lukutu pẹbẹ, awọn janduku ajinigbe ti mu ẹni to gbowo itusilẹ fawọn ọgọrun akẹkọọ ileewe Salihu Tanko Islamic Secondary School niluu Tegina nipinlẹ Niger mọlẹ.
Iroyin sọ pe awọn janduku ọhun ni owo itusilẹ ti ko wa ko pe lo jẹ ki awọn mu un mọlẹ.
Akọroyin BBC, Ishaq Khalid ṣalaye pe awọn obi awọn akẹkọọ naa ti da ẹgbẹẹgbẹrun owo dọla fun itusilẹ awọn akẹkọọ ọhun.
- Ẹ̀mí mímọ́ ló ní kí n múra lài wọ bùbá láti ṣe ọjọ́ ìbí mi torí pé ... - Òṣèré Clarion Chukwura
- Sanwo-Olu ṣàlàyé ohun táwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
- Sunday Igboho, ìsáǹsá rẹ̀ kò lé sá mọ́ wa lọ́wọ́, mímú lá mú ọ - DSS fọwọ́ gbáyà
- Wo àwọn ẹ̀sùn tí ìjọba Nàìjíríà fi kan Olóyè Sunday Igboho
- Kí ló ṣẹlẹ̀ tí Tinubu kò fi kópa nínú ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko?
- Isó fààá leè jẹ́ kí ẹ kò Covid-19 níbi tí o ba fún pọ̀! Ẹ fura o!
O ti to bi oṣu meji bayii tawọn ajinigbe ti gbe awọn akẹkọọbinrin ati akẹkọọbinrin sa lọ nipinlẹ Niger.
Ọga ile ẹkọ naa sọ pe o yẹ kawọn ajinigbe le tu awọn akẹkọọ naa silẹ lẹyin ti wọn ti gba ẹgbẹrun marunlelaadọrin owo dọla tii ṣe ọgbọn miliọnu naira.
Ṣugbọn o ni ọrọ ti polukuru musu bayii lẹyin ti wọn mu baba to gbowo lọ fun wọn mọlẹ.
Iru nkan bayii ko wọ pọ pẹlu awọn ajinigbe lorilẹede Naijiria.
O ti le ni ẹgbẹrun kan akẹkọọ tawọn ajinigbe ti ji lọ lawọn ile ẹkọ girama ni Naijiria lati oṣu kejila ọdun 2020 di akoko yii.
Ọpọlọpọ wọn lo si wa ni akata awọn ajinigbe pawo yii titi di asiko yii.















