Buhari sons wedding: Ìgbìmọ̀ ẹlẹni 145 ni yóò ṣe ètò ìgbáyàwó ọmọ ààrẹ Buhari pẹlu ọmọ Emir Bichi

Ìgbìmọ̀ ẹlẹni 145 ni yóò ṣe ètò ìgbáyàwó ọmọ ààrẹ Buhari pẹlu ọmọ Emir Bichi

Gbogbo ètò lo ti tò báyìí fún ìgbéyàwó ọmọ ààrẹ Muhammadu Buhari àti ọmọ Emir ilú Bichi Nasir Ado Bayero.

Igbéyàwó náà tí yóò wáyé ni ogúnjọ́ oṣù kẹjọ ọdún 2021 láàrín Yusuf Buhari àti Zahra Ado-Bayero ni wọ́n ti yà àwọn ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe ti yóò mójú tó ètò náà.

Àkọlé fídíò, Japan: Ẹ wo arákúnrín tó ń ta ilé àwọn òkú fún àwọn tó ní ìfẹ́ sí

Agbẹnusọ Emir Bichi, Lurwanu Malikawa nínú àtẹ̀jádé lọ́jọ́ Sátíde, ṣàlàyé pé Emir Bichi, Nasir Ado-Bayero ti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni márùnlélógóje lati mu kí ètò ìgbéyàwó náà lọ ni ìrọwọ́rọsẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bi àtẹ̀jáde náà ṣe sọ, àwọn ìgbìmọ yìí bákan náà ni yóò ṣe ètò ìwúyè àti gbigba ọ̀pá oye ti Gómínà ìpínlẹ̀ Kano Abdullahi Ganduje yóò fún un.

Bákan náà ni àtẹjáde ọhun fi kun pé, Baálẹ̀ Bagwai, Nura Ahmed( Madakin Bichi) ni alága ìgbìmọ̀ náà nígbà tí Abba Waziri(Falakin Bichi) yóò jẹ́ akọ̀wé ìgbìmọ̀.

Lásìkò tí wọ́n ń ṣe àfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ náà ní èyí tí Madakin Bichi ti sojú Emir, lo ti rọ wọn láti lo àwọn ìmọ̀ àti ìrírí wọn fún àṣeyọrí ètò ìgbéyàwó náà.

Ìgbéyàwó yìí yóò wáyé ni ogúnjọ oṣùkẹjọ ọdún 2021, nígbà tí ètò ìwúye ọba yóò wáyé ni ọjọ́ kejì lélógúnni ààfin Emir.

Ìròyìn sọpé ilẹ̀ UK ni àwọn méjèèjì ti kẹkọ̀ọ́ gboye.