Sunday Igboho: Reno Omokri ní kí Falana, Afe, Jegede, Olanipekun lo ọpọlọ òfin ní Cotonou láti tú Igboho sílẹ̀

Sunday Igboho

Amugbalẹgbẹ tẹlẹ fun aarẹ Naijiria, Reno Omokri ti ke si awọn agba amofin to jẹ ọmọbibi ilẹ Yoruba lati tete di ẹru wọn lọ gbeja Sunday Igboho nileẹjọ nilẹ Benin

Reno Omokri ni awọn agba amofin bii Femi Falana, Afe Babalola, Eyitayo Jegede, Wole Olanipekun, atawọn miran lati ilẹ Yoruba lo yẹ ko ti lẹ joko silu Cotonou bii ikọ amofin fun Sunday Igboho, ki wọn ma baa gbe pada wa si Naijiria.

Ikede kan ti Omokri fi si oju opo Facebook rẹ lo sisọ loju ọrọ yii pẹlu afikun pe aarẹ Muhammadu Buhari gan jẹbi sise ojusaaju fun iran rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Japan: Ẹ wo arákúnrín tó ń ta ilé àwọn òkú fún àwọn tó ní ìfẹ́ sí

Omokri ni "lọdun meji sẹyin ni aarẹ Muhammadu Buhari fi baalu kekere ransẹ si orilẹede Niger lati ko awọn ọmọ ikọ mujẹmujẹ Boko Haram to ronu piwada wa sile.

Se ijọba to wa se eleyi fun awọn adunkookomọni lo yẹ ko ni ki wọn fi tipa tipa mu ẹni to n ja fun ominira iran rẹ wa sile lati orilẹede Benin.

Ọrọ ti Reno Omokri sọ loju opo Facebook rẹ

Oríṣun àwòrán, Reno Omokri/Facebook

Akoko yii kii se akoko to yẹ ka joko maa sọrọ lasan tabi kọ iwe ti ko nitumọ kankan.

O yẹ ki gbogbo iran Yoruba lo owo, dukia ọpọlọ ati imọniyan wọn lati dide gbe Sunday Igboho nija ni, ẹni to koju awọn afurasi apaayan darandaran to n da orilẹede Naijiria laamu."

Bẹẹ ba gbagbe, Sunday Igboho lo n jẹjọ lọwọ nile ẹjọ kan lorilẹede Benin lati mọ boya wọn yoo da pada wa si Naijiria ko wa jẹjọ iwa ọdaran ti ijọba fi kan.

Amin iyasọtọ kan

Wo bí ìgbẹ́jọ́ Sunday Igboho yóò ṣe lọ ní ìlú Cotonou, Benin Republic lónìí

Agọ ọlọpaa ti Sunday Igboho wa

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe igbẹjọ waye lọjọru lorilẹ-ede Benin, lati mọ boya ijọba orilẹ-ede naa yoo fa Sunday Adeyemo Igboho le ijọba Naijiria lọwọ.

Ọjọ Aje ni awọn oṣiṣẹ alaabo mu oun ati iyawo rẹ, Ropo, lasiko ti wọn fẹ wọ baalu lọ si orilẹ-ede Germany.

Iroyin sọ pe aago mẹwa owurọ oni, ni igbẹjọ naa yoo bẹrẹ.

Ọjọru lo yẹ ki igbẹjọ naa kọkọ waye, ṣugbọn wọn ko gbe Sunday Igboho wa sile ẹjọ ni ilu Cotonou ni orilẹede Benin Republic.

Akọroyin BBC Yoruba to wa ni Cotonou ni ko si igbẹjọ kankan nitori wọn ko gbe Sunday Igboho wa si ileẹjọ.

Gẹgẹ bi akọroyin wa se wi, awọn eeyan duro lati foju ganni Igboho amọ nigba ti wn ko ri, ni awọn eniyan bẹrẹ si ni kuro ni ileẹjọ.

Ile ẹjọ to yẹ ki igbẹjọ naa ti waye ni wọn n pe ni Paequet, ti iroyin naa si ni ahamọ kan ti wọn n pe ni Brigade De Criminel to wa lagbegbe Berlier, ni wọn fi Sunday Igboho pamọ si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iwadii akọroyin naa fihan pe, Sunday Igboho ṣi wa ni agọ ọlọpaa ti wọn n pe ni BRIGADE DE CRIMINEL, nibi ti wọn fi pamọ si.

Lọwọlọwọ awọn eniyan pejọ si agọ ọlọpaa naa lati mọ ipo ti Sunday Igboho wa, amọ ọlọpaa kankan ko i tii bawọn sọrọ.

Agọ ọlọpaa ti Sunday Igboho wa

Amọ wọn ko tii le sọ boya wọn yoo si gbe lọ si ileẹjọ ki ilẹ oni to ṣu.

Bi iroyin naa ba ṣe n lọ ni a o ma a fi to yin leti.

Ti ẹ ko ba gbagbe, Ọgunjọ, Oṣu Keje, ọdun 2021 ni ẹṣọ agbofinro lati orilẹede Naijiria mu Sunday Igboho ni papakọ ofurufu ni Benin Republic, lẹyin ti ajọ DSS lorilẹede Naijiria kede pe wọn n wa Sunday Igboho fun ẹsun pe o ko ohun ija oloro pamọ si ile rẹ.

Awọn eekan ni ilẹ Yoruba to fi mọ awọn lọbalọba ni wọn ti n ṣepade lori ọrọ naa, ti awọn alakoso Yoruba Nation si n sọ pe awọn yoo sa gbogbo ipa wọn lati ri pe wọn ko gbe Sunday Igboho pade si Naijiria nitori wọn yoo tẹ ẹtọ rẹ mọlẹ.