Lagos LG Election: Ìbò ìjọba ìbílẹ̀ yóò wáyé l‘Eko lónìí lòdì sí ẹ̀bẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú mọ́kànlá láti fagi lé e

Awọn eeyan to n dibo

Loni ọjọ Satide ni eto idibo yoo maa waye lati yan awọn alaga ati Kanselọ sawọn ijọba ibilẹ ati agbegbe idagbasoke to wa jakejado ipinlẹ Eko.

Saaju ni ijọba ti kede pe ko ni si lilọ bibọ awọn ero ati ọkọ lati aago mẹfa aarọ si mẹta ọsan, ti eto idibo naa yoo fi maa waye.

Eto idibo naa yoo seese tori bi ile ẹjọ giga ijọba apapọ to wa ni Ikoyi se kọ lati wọgile eto idibo naa, ti yoo waye lawọn ijọba ibilẹ ati agbegbe onidagbasoke mẹtadinlọgọta to wa nipinlẹ Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi atẹjade kan tijọba ipinlẹ Eko fisita lọjọ Ẹti, awọn ẹgbẹ oselu mọkanla lo n rọ ile ẹjọ giga naa lati wọgile sise eto idibo ọhun.

Adajọ Akintayo Aluko si lo gbọ ẹjọ naa, eyi ti ẹgbẹ oselu Alliance of Social Democrats atawọn mẹwa miran pe ajọ eleto idibo niìnlẹ Eko ati ijọba ipinlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Timi Orokoya ní orin Iléyá tí òun kọ lọ́dún 28 sẹ́yìn, ló padà wá ṣẹ báyìí

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Aluko gba ẹbẹ Agbẹjọro agba ati Kọmisana eto idajọ nipinlẹ Eko, Moyosore Onigbanjo, eyi to gbe kalẹ lorukọ ijọba ipinlẹ Eko.

Adajọ naa ni "Ile ẹjọ mi ko ni asẹ lati gbọ ẹjọ naa tabi wọgile eto idibo ijọba ibilẹ ti yoo waye lọjọ Satide."

Wayi o, Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Eko, Akeem Odumosu ti wa kede pe ileesẹ ọlọpaa ti seto gbogbo to yẹ lati ri daju pe ko si lilọ bibọ ọkọ ati ero jakejado ipinlẹ Eko lọjọ Satide ayafi awọn onisẹ kosemase nikan.