Sunday Igboho: Wọ́n sì de Igboho lọ́wọ́ ní àtìmọ́lé ọlọ́pàá ní orílẹ́èdè Benin

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho
Oju ajijagbara ati ajafẹtọ ọmọniyan nilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyemo(Sunday Igboho) n ri to lọwọ awọn ọlọpaa orilẹede Benin, agbẹjọrọ rẹ, Ibrahim Salami lo sọrọ yii fun BBC Yoruba.
Salami sọ pe bo tilẹ jẹ wi pe ninu atimọle ni wọn ju Igboho si, niṣe lawọn ọlọpaa tun fi ṣẹkẹ ṣẹkẹ si i lọwọ.
O ṣalaye pe pe ọkan lara agbẹjọro marun un to n ṣoju Igboho lorilẹede Benin ni oun jẹ.
- "Ẹ̀yin àgbà amòfin nílẹ̀ Yoruba, ẹ kó lọ sí Cotonou láti gbèjà Sunday Igboho"
- Sunday Igboho ń bẹ iléẹjọ́ láti ṣe àtìpò òṣèlú nílẹ̀ Benin
- Igun kan PDP ìpínlẹ̀ Ogun kọ̀ lati kopa nínú ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ lónìí
- Gbaga ọlọ́pàá ni Igboho ti ń lo òpin ọ̀sẹ̀, ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Benin kò jókòó lọ́jọ́ Ẹtì
- Ẹgbẹ́ òṣèlú mọ́kànlá forí ṣánpọ̀n nílé ẹjọ́ láti wọ́gilé ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ l‘Eko
- Adájọ́ pàṣẹ pé kí DSS kó èèyàn méjìlá tó kó nílé Igboho wá sílé ẹjọ́
''Nigba ti a lọ ṣabẹwo si Igboho ni atimọle ọlọpaa, a ri pe wọn fi ṣẹkẹ ṣẹkẹ si lọwọ, amọ wọn ko lu u, wọn ko si jẹ ẹ niya.
A ṣọ fun awọn agbonfinro wi pe eleyii ko ba ofin orilẹede Benin mu, ṣugbọn wọn ko tii ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe.
Eleyii jẹ ki o nira fun Oloye Igboho lati jẹun ati lati ṣe nkan mii ni atimọle.
Ijọba Naijiria ko tii sọ fun ijọba Benin pe ki wọn ki wọn da Igboho pada si oriẹede Naijiria.
Ohun ti ijọba orilẹede Naijiria sọ fun Benin ni pe Igboho ti lu ofin ni Naijiria wi pe ki wọn mu un nibẹ.
Awọn aṣoju ijọba Naijiria tun sọ fun ile ẹjọ ni Benin pe Igboho ko ibọn pamọ sile eleyii ti o fẹ lo lati pin orilẹede Naijiria.
Wọn tun sọ pe Igboho n lo awọn eeyan lati da ilu ru.
Ijọba Naijiria tun sọ pe Igboho n ṣe fayawọ ibọn.
Mo fẹ sọ fun yin pe Igboho ko tapa si ofin orilẹede Benin, bakan naa wọn ko ka iwe igbelu Benin mọ Igboho lọwọ.
Mo tun fẹ ki ẹ mọ pe papakọ ofurufu ni awọn ọlọpaa ti mu Igboho ati iyawo rẹ lẹyin ti wọn ti ra tikẹẹti tan lati rinrin ajo lọ si orilẹede Germany.
Iyawo Igboho ti gba ominira lọwọ awọn agbofinro ko si si ni atimọle mọ bayii.
Sunday Igboho ń bẹ iléẹjọ́ láti ṣe àtìpò òṣèlú nílẹ̀ Benin
Gbajugbaja ajafẹtọ ọmọniyan, Oloye Sunday Igboho ti n beere pe ki ijọba ilẹ Benin fun oun ni aaye lati fi ori pamọ silu wọn.
Igboho, ẹni ti awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ DSS n wa lorilẹede Naijiria lo tun n koju igbẹjọ lori boya yoo pada sorilẹede Naijiria abi bẹẹkọ.

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho/Instagram
Gẹgẹ bi iwe iroyin Punch ti salaye, Igboho pada gba lati beere fun aabo igbelu lọwọ ijọba ilẹ Benin nigba ti awọn ọlọpaa orilẹede Benin mu si ahamọ ni papakọ ofurufu to wa nilu Cotonou lasiko ti oun ati iyawo rẹ n rinrin ajo lọ sorilẹede Germany lọjọ Aje to kọja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Adájọ́ pàṣẹ pé kí DSS kó èèyàn méjìlá tó kó nílé Igboho wá sílé ẹjọ́
- N kò ṣe ẹlẹ́yà Sunday Igboho, irọ́ ni wọ́n pa mọ́ mi - Olayomi Koiki
- ‘Passport’ Nàíjíríà àti Germany ni wọ́n ká mọ́ Sunday Igboho lọ́wọ́ - Agbẹjọ́rò
- "Ẹni tó bá gba 'Passport Benin Republic' láì ṣe ọmọ onílùú, yóò fi ẹ̀wọ̀n jura"
- Mo kìlọ̀ fún Igboho kó má wá sí ilé mi ní Benin Republic, lẹ́yìn táwọn ọlọ́pàá ń ṣọ́ mi - Alábàṣiṣẹ́pọ̀
- Benin Republic ló bẹ́gi dínà aáyan ìjọba àpapọ̀ láti kù gììrì gbé Igboho wá Naijiria - Amòfin
Bi o tilẹ jẹ pe ile ẹjọ ti Igboho ati aya rẹ, Ropo, yọju si nilu Cotonou pasẹ pe ki wọn fi iyawo Igboho silẹ, ko maa lọ sile lai ni gbedeke kankan nidi nitori ko ni ẹjọ lati jẹ, sibẹ wọn ko fi ọkọ silẹ, to si n lo opin ọsẹ ninu ahamọ ọlọpaa kan ni Cotonou.
Koko ohun ti wọn si n ba Igboho se ẹjọ le lori ni pe boya wọn yoo fa le ijọba Naijiria lọwọ abi bẹẹkọ, ko le wa koju awọn ẹsun kiko ibọn pamọ tileesẹ DSS fi kan ni Naijiria.
Gẹgẹ ba se gbọ, awọn agbẹjọro Sunday Igboho ti gbe ẹbẹ kan siwaju ile ẹjọ naa, ti wọn si n rọ ọ pe ko fun Igboho laaye lti fori pamọ sorilẹede olominira Benin.
Gbogbo igbesẹ si lo ti n lọ lọwọ bayii lati maa fi ọwọ si awọn iwe to yẹ fun ibeere lọwọ ijọba Benin pe ko gba Igboho laaye lati se atipo oselu lorilẹede naa, dipo ki wọn gbe pada wa si Naijiria.














