Sunday Igboho: Mo gbìyànjú láti kìlọ̀ fún Igboho pé Interpol ń wa ṣùgbọ́n ó ti bọ́ sórí

Oríṣun àwòrán, Nigerian Watch
Enikan to sun mọ Igboho, ṣugbọn ti ko fẹ ki wọn fi orukọ oun lede ti ṣalaye bi oun ṣe sọ fun ajijagbara naa pe ko dẹkun a ti maa bẹ ile oun wo lorilẹ-ede Benin.
O ṣalaye pe oun sọ ọrọ naa lẹyin ti awọn ọlọpaa bẹrẹ si n ṣo ile loju-lẹsẹ.
Gẹgẹ bii ohun to sọ fawọn akọroyin, ilẹ rẹ ni Igboho maa n de si ni gbogbo igba to ba ti gunlẹ si Benin Republic, ati pe oṣu Kinni, ọdun yii ni wahala Igboho pẹlu ijọba Naijiria ti bẹrẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn agbẹjọ́rò tó dáńtọ́ ti wà ní Cotonou láti gba ìdáǹdé Sunday Igboho - Akitoye
- Wo ìgbà márùn-ún tí wọn saáyan láti mú Sunday Igboho
- Wo àwọn ìgbésẹ̀ tí Sunday Igboho gbé, tó fi di ọ̀tá ìjọba
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba Naijiria ti fi pampẹ̀ òfin mú Sunday Igboho?
- "Á dá ohun àlùmọ́ọ́nì wa jọ láti gbèjà Sunday Igboho nílé ẹjọ́"
- "Buhari, kí ló dé tó ń mu Sunday Igboho àti Kanu, amọ́ tó mu àwọn agbébọn?"
- Èémọ̀! Pásítọ̀ dèrò ọ̀run níbi tó tí ń l'àjà láàrin ọkọ àti ìyàwó- Iléeṣẹ ọlọ́pàá
Ọkunrin naa fikun pe oun sọ fun ajijagbara naa ko dẹkun lati maa bẹ ile oun wo lasiko yii nitori pe awọn ọlọpaa ti n ṣọ ile naa.
Ti ẹ ko ba gbagbe, agbẹnusọ fun Aarẹ Buhari, Garba Shehu ti kọkọ sọ loṣu kini ọdun yii pe, ọga agba ana fun ileeṣẹ ọlọpaa, Mohammed Adamu ti paṣẹ ki wọn mu Igboho.
Igbesẹ naa waye lẹyin ti Igboho le awọn afurasi ọdaran Fulani kuro lagbegbe Ibarapa, nipinlẹ Oyo.

Ẹni naa ṣalaye siwaju si pe wọn ko fi ọrọ naa falẹ rara, eyii to n tumọ si pe o ti ṣe diẹ ti ijọba Naijiria ti n wa Igboho.
O tun sọ siwaju si pe ijọba Naijiria ti kọwe si ijọba Benin lati tọpinpin Igboho.
O ṣalaye pe "Mo maa n mọ ni gbogbo igba ti ti Igboho ba fẹ wa si Benin Republic nitori yoo pe mi lori aago pe oun bọ, ṣugbọn ko pe mi ni eyii to wa kẹyin yii boya nitori mo ti sọ fun pe mi o gba alejo rẹ mọ."
"Nigba ti mo gbọ lọjọ Aje pe o wa ni papakọ ofurufu, mo gbiyanju lati ke si pe ko fi ibẹ silẹ nitori ijọba Naijiria ti kọ lẹta si Interpol lori ọrọ rẹ."
"Lẹsẹ kan naa ni mo gbiyanju lati pe ẹnikan ni papakọ ofurufu ọhun, ki wọn sọ fun pe ko fi ibẹ silẹ ni kia-kia, iṣẹju marun un lẹyin naa ni mo gbọ pe wọn ti mu Igboho pẹlu aṣẹ lati oke wa."

Wọn yóò tẹ ẹ̀tọ́ Sunday Igboho mọ́lẹ̀ tó bá padà sí Nàìjíríà - Afenifere Renewal Group

Oríṣun àwòrán, others
Ẹgbẹ Afenifere Renewal, ARG Group ti sọ fawọn orilẹ-ede agbaaye pe ijọba yoo tẹ ẹtọ Oloye Sunday Adeyemo Igboho mọlẹ ti o ba le pada si Naijiria.
Ninu atẹjade kan ti alaga ẹgbẹ ARG, Olawale Oshun ati akọwe ẹgbẹ naa, Ayo Afolabi fi sita, ẹgbẹ naa sọ pe o ṣeni laanu pe wọn ti mu Igboho to n sọrọ tako iwa ipa awọn darandaran ti ijọba ko ri nkan ṣe si.
"O buru jai pe ijọba n lo gbogbo agbara to ni lati dena igbiyanju Igboho lori idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ooni Ife àtàwọn èèkàn Yorùbá ṣèpàdé ìdákọ́nkọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
- Ìwọ́de ńlá yóò wáyé lónìí ní London lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
- Àwọn ajìjàgbara Yoruba Nation yóò ṣe iwọ́de tako bí wọ́n ṣe mú Sunday Igboho
- "Ẹ̀yìn ọba Yorùbá, ẹ dìde láti gbe Sunday Igboho níjà kó le jàré nílẹ̀ Benin"
- "Ìdí tí ìjọba Benin Republic kò ṣe ní le è fa Igboho lé Nàíjíríà lọ́wọ́ ree"
- Inú ìrora ni Sunday Igboho wà pẹ̀lú ṣẹ́kẹ́-ṣẹkẹ̀ ní àhámọ́ - Agbẹjọ́rò
- Sé lóòtọ́ ni wọ́n ti fi Sunday Igboho sílẹ̀ ní Cotonou?
- Sunday Igboho àti aya rẹ́, Ropo ni ọlọ́pàá Interpol mu ní Cotonou - Agbẹjọ́rò
- Kìí ṣe tuntun pẹ ìjọba Buhari tí mú Sunday Igboho, àmọ́ ọ̀nà àbáyọ sí ìtúsílẹ̀ rẹ̀ rèé - Agbẹnusọ Sunday Igboho
- Buhari, tú Sunday Igboho sílẹ̀ bo ṣe tú Boko Haram tó ronúpíwàda sílẹ̀ - Ladoja
"Ṣugbọn ijọba yii kan naa ko ka ọrọ awọn darandaran ti wọn fẹ gba ilẹ Yoruba, ti wọn fẹ sọ ọ di ibi igbesunmọmi amọ awọn gomina ko gba fun wọn."
Ẹgbẹ ARG sọ pe oun ko tii ri ki ijọba gbe igbesẹ to ni itumọ lati ri pe awọn janduku agbebọn to n da orilẹ-ede Naijiria laamu foju wina ofin.
O si ṣapejuwe ihuwasi ijọba gẹgẹ bi iwa ẹlẹyamẹya ninu ijọba awaarawa.
Wọn ni wọn yabo ile Igboho niluu Ibadan lọna aitọ, lai mu iwe ofin to fun wọn laṣẹ lati mu un dani.
Ti ko si si ẹri to daju to le fihan pe awọn to wa nile Igboho kọju ija si awọn DSS to yabo ile rẹ nibi ti wọn ti pa eeyan meji laiṣẹ.
"A fẹ sọ fun gbogbo agbaye pe kò sí idaniloju pe Igboho yoo ri idajọ ododo to ba fi le pada si Naijiria.
Labẹ ofin agbaye ni orilẹ-ede Benin Republic wa, o ṣi lẹtọọ lati daabo bo Igboho ati lati ri i pe o gba idajọ ododo níbẹ," ẹgbẹ ARG lo ṣalaye bẹẹ.
Ẹgbẹ naa wa rọ ijọba apapọ lati wa ojutu sí ohun to ṣokunfa awọn iṣoro to n koju Naijiria lọwọ yii.
Ẹgbẹ ARG ni ki ijọba yee dọdẹ awọn ọmọ Naijiria kan nitori ẹya wọn.



















